Wo kókó àtúnṣe mẹ́rin tí ìjọba ṣe lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ àti ipa tí yíyọ ẹ̀kọ́ ìṣirò fún ìgbaniwọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ‘Arts’ yóò ní lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́

Aworan awọn akẹkọọ ninu yara ikẹkọ pẹlu olukọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti gbe igbesẹ tuntun lori atunṣe eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, paapa fun awọn akẹkọọ to n gbero lati wọ fasiti.

Eyi lo yọ imọ ẹkọ iṣiro kuro ninu awọn imọ ẹkọ to yẹ ki akẹkọọ ẹka Art ni ko to le wọ ile ẹkọ giga fasiti tabi ile ẹkọ giga miiran.

Igbesẹ yii ni ẹka ijọba apapọ lori eto ẹkọ labẹ idari Maruf Tunji Alausa, minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria gbe sita lọjọ Kẹrinla Oṣu kẹwaa ọdun 2025.

Alausa ṣalaye pe, ṣaaju ọpọ awọn akẹkọọ lo n koju ọpọ inira lati wọ fasiti nitori wọn ko yege ninu imọ iṣiro.

"Lọdọdun, akẹkọọ milọnu meji to n jokoo fun idanwo igbaniwọle si fasiti UTME ṣugbọn 700,000 nikan lo ni anfani lati wọ ile sinu fasiti.

"Eyi ko tọna, ti ko si ba igba mu mọ, ti a ni lati mu kuro lati fun awọn ọdọ ati akẹkọọ ni anfani si ile ẹkọ."

Wo ilana tuntun fun igbaniwọle awọn akẹkọọ si ile ẹkọ giga

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹka ijọba to n risi eto ẹkọ, Boriowo Folasade, fi sita fun awọn akọroyin, Alausa ni igbesẹ gbogbo awọn ile ẹkọ pata lo gbọdọ tẹle eyi, bẹrẹ pẹlu awọn fasiti, ile ẹkọ poly ati awọn ile ẹkọ giga kaakiri orilẹede Naijiria.

  • Fun ile ẹkọ fasiko, akẹkọọ ti ko ba si ni ẹka ṣayensi ko nilo imọ iṣiro mọ, o gbọdọ yege ninu imọ-ẹkọ marun un pẹlu ede gẹẹsi, ṣugbọn Iṣiro pon dandan fun awọn akẹkọ ni ẹka sayẹnsi, imọ ẹrọ ati agbegbe sayẹnsi.
  • Ile ẹkọ Poly ti awọn ND (ND Level): Akẹkọọ gbọdọ yege ninu imọ-ẹkọ mẹrin ninu awọn ẹkọ to ṣe pataki, ti ẹdẹ gẹẹsi si se koko fun ẹka ti ki i ṣe ti sayẹnsi, ti Isiro naa si ṣe koko fun awọn ẹka sayẹnsi.
  • Ile ẹkọ Poly (HND Level): Akẹkọọ gbọdọ yege ninu imọ-ẹkọ marun un to fi mọ ede gẹẹsi ati iṣiro.
  • Ile ẹkọ Colleges of Education (NCE Level): Akẹkọọ gbọdọ yege ninu idanwo mẹrin fun eyi eto ẹkọ to fẹ ka, ti Ede gẹẹsi si ṣe koko fun ẹka ti ki n ṣe Sayẹnsi ṣugbọn Isiro ṣe koko fun awọn ẹka sayẹnsi ati imọ ẹrọ.
Aworan Minisita fun eto ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Others

Iwe ẹri ND yoo rọpo fun NID fun awọn ile ẹkọ giga Innovation Enterprise Academies

Bakan naa ninu atẹjade ti Boriowo Folasade fi sita, iwe ẹri National Industrial Enterprise fun awọn ile ẹkọ giga Innovation Enterprise Academies ti wọn ti yọ kuro bayii, ti wọn si ti fi National Diploma rọpo rẹ lati ti pe awọn akẹkọọ ni anfani lati tẹsiwaju ninu eto ẹkọ naa.

Alausa ni awọn ile ẹkọ ti ko ba tẹle aṣẹ yii ni ijọba yoo gba iwe aṣẹ lati sisẹ wọn.

O tẹsiwaju pe igbesẹ yii yoo se alekun akẹkọọ to to 250,000 si 300,000 ti wọn yoo ma wọ ile ẹkọ giga bayii ni ọdọdun.

O ni eyi jẹ igbiyanju ijọba lati ri pe eto ẹkọ jẹ anfani fun gbogbo ọpọ ọdọ lorilẹede Naijiria.

"Igbesẹ yii yoo jẹ ki igbaniwọle si fasiti pọ si ati pe yoo mu adikun ba awọn ọdọ ti wọn w ani titi nigba to yẹ ki wọn wa ni ile ẹkọ.

"Awọn ọdọ ni ọjọ ọla orilẹede Naijiria, ti ijọba si n sa akitiyan lati eto ẹkọ wa fun wọn lati yi ọjọ ọla wọn pada pẹlu imọ ti wọn nilo."

Ìgbésẹ̀ yíyọ ẹ̀kọ́ ìṣirò kúrò kò lè ní ìpalára kankan fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ - Onímọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC News Yoruba wa kan si olukọ kan ni fasiti Ilorin, Ọjọgbọn Olugbade Ojo lati se agbeyẹwo awọn ayipada ati atunse to waye ni ẹka eto ẹkọ naa.

Ọjọgbọn Ojo, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ wa kan sara si ijọba apapọ lori igbesẹ wọn lati yọ imọ iṣiro kuro ninu awọn imọ to ṣe koko fun awọn akẹkọọ lati ẹka Art gbọdọ ni ṣaaju ki wọn to wọle si ile ẹkọ giga lorilẹede Naijiria.

Olugbade Ojo si jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa dara nitori ko pọn dandan fun awọn akẹkọọ lati ẹka Arts ni ile ẹkọ girama.

"Igbesẹ yii dara ṣugbọn wahala ti a ni ninu eto ẹkọ ni pe bi ijọba kan ṣe n lọ ti wọn n de ti wọn gbe aṣẹ tuntun sita.

"Ko ki n ṣe gbogbo ẹkọ lo pin dandan fun pe ki wọn nilo lati mọ imọ ẹkọ iṣiro ki wọn to wọ fasiti."

Ojo ni oun ko gbagbọ pe igbesẹ yii ko le fa ipalara kankan fun awọn akẹkọọ nitori ọpọ wọn ni ohun ti wọn fẹ ka ni ile ẹkọ giga.

"Ko ni ipalara kankan ti igbese yii fẹ se fun akẹkọọ nitori akẹkọọ mọ oun ti o fẹ ṣe ṣugbọn fun awọn akẹkọọ ni ẹka Ṣayẹnsi, awọn akẹkọọ wọn mọ pe o pin dandan pe ki wọn yege ninu imọ-ẹkọ iṣiro.

"Iwọ to fẹ ka nipa imọ nipa bi a ṣe n ṣe ilu, ofin ati awọn ẹkọ mii, o ko nilo imọ ẹkọ iṣirọ rara."

"Yatọ si yiyọ imọ-ẹkọ iṣiro kuro, ọpọ nnkan si wa fun ijọba lati ṣe lẹka eto ẹkọ"

Olugbade Ojo ni bo tilẹ jẹ pe ijọba ni awọn gbe igbesẹ yii nitori wọn fẹ mu adikun ba awọn ọdọ ti ko si ni ile ẹkọ, o ni ọpọ awọn nnkan miiran wa ti ijọba ko bi ara si to n se ọpọ ijamba fun eto ẹkọ.

"Awọn ọmọ ti ko si ile ẹkọ, to si jẹ nnkan to n fa ju ni osi to wọpọ ni awujọ wa, ọpọ obi ni ko ni owo lati ran awọn ọmọ lọ si ile ẹkọ.

"Ọpọ obi lo fẹ ki ọmọ rẹ naa mọ ka ṣugbọn owo ko tọ yapa ni awọn ile ẹkọ, ti ọpọ awọn ọdọ si ni lati lọ iṣẹ.

"Ti ijọba ba fẹ ki yi dinku, wọn lati mojuto eto ẹkọ daradara."