Báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń tún ojú wọn dá pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ, ire àbí ibi wo ló wà níbẹ̀?

Awọn obinrin mẹta to se isẹ abẹ, egbo wa ni imu akọkọ́, ori obinrin keji ni wọn we bandeji mọ nigba ti ẹrẹkẹ mejeeji obinrin kẹta jẹ egbo ti wọn we bandeji mọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ayé ń lọ à ń tọ̀ ọ́.

Ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láti fi tún ojú ṣe tún ti ń gba ọ̀nà míì yọ.

Ṣíṣe ìwádìí lórí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ abẹ tó wà láti fi tún ojú ẹni ṣe.

Láyé ìgbà kan ló jẹ́ pé àwọn olówó tí wọ́n ti dàgbà ni wọ́n sábà máa ń ṣe àtúnṣe ara wọn pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ ṣùgbọ́n ó ti di tọ́rọ́ fọ́nká sílé láàárín àwọn ọ̀dọ́ báyìí.

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lóde òní ni wọ́n ń fi ìdùnnú ṣe àfihàn bí ojú wọn ṣe rí ṣáájú kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ abẹ àti bó ṣe rí lásìkò tó ń jiná lọ́wọ́ àti lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ.

Kìí ṣe ohun tí wọ́n ń gbé pamọ́ mọ́, àwọn ìlúmọ̀ọ́ká bíi Kris Jenner, Catt Sadler àti Marc Jacobs ti sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ wọn ní gbangba. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlúmọ̀ọ́kà náà ló ti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣé àwọn èèyàn kò ní ìgboyà nínú ara wọn mọ́ débi wí pé wọ́n le san ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ pọ́ùn láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ láti ṣe àtúnṣe ojú wọn?

Àbí ṣe àwọn àtúnṣe ojú tí kò nílò iṣẹ́ abẹ bíi Botox àti fillers, níbi tí wọ́n ti máa ń ya àwọ̀ ojú dé ẹ̀ẹ̀kẹ́ àti ṣíṣe àtúntò àwọn ọ̀rá ojú bí kò kájú òṣùwọ̀n tó mọ́?

Àkójọpọ̀ àwọn àwòrán tó ń Emily ṣáájú àti lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ

Oríṣun àwòrán, @hotgirlenhancements

Àkọlé àwòrán, Emily ní òun kò kábàámọ̀ síṣe iṣẹ́ abẹ ojú
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fún Emily, ẹni tó ṣiṣẹ́ abẹ láti fi tún ojú rẹ̀ ṣe nígbà tó wà ní ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, ó ní òun ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú kí ojú òun dùn-ún wò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣe àtúnṣe ẹ̀kẹ́, ìjàgbọ̀n àti ojú rẹ̀. Ó sọ pé ṣíṣe iṣẹ́ abẹ náà ní orílẹ̀ èdè Turkey jẹ́ àyípadà ńlá ní ìgbé ayé òun.

"Ní àpapọ̀, mo ṣe iṣẹ́ abẹ mẹ́fà papọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà," ó ṣàlàyé. "Lára rẹ̀ ni àtúnṣe ojú, ètè àti imú."

Nígbà tó ń júwe ìgbésì náà, oníṣòwò náà láti Toronto, Canada sọ pé dókítà tó ṣe iṣẹ́ abẹ náà bá òun fi àwọn orin tí òun fẹ́ràn sí lásìkò tí iṣẹ́ abẹ náà ń lọ lọ́wọ́.

"Mo sùn lọ síbẹ̀, nígbà tí mo jí, mo bì, mo sì ri pé ojú àti imú mi ti yàtọ̀."

Kí iṣẹ́ abẹ náà tó jiná pẹ́ díẹ̀, ó ní àwọn ìnira tó rì bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ díẹ̀díẹ̀, tó sì gbà á tó oṣù mẹ́fà kí Emily tó bẹ̀rẹ̀ sí ri mọ ìnira lára ẹ̀kẹ́ rẹ̀.

Nígbà tí a bèèrè pé ṣé yóò tún iṣẹ́ abẹ́ náà ṣe Emily kò tètè fèsì.

"Láti ìgbà tí mo ti ṣiṣẹ́ abẹ mi, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti yípadà ní ìgbésì ayé mi. Ara mi le si, mi ò mu ọtí mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, mò ń ṣe àkíyèsí àwọ̀ síi, mo máa ń sùn. Tó bá jẹ́ pé mo mọ àwọn nǹkan tí mo mọ̀ nísìn-ín tẹ́lẹ̀, mol è má ṣe iṣẹ́ abẹ náà.

"Ìyá mi kò mọ̀ pé mo ṣe iṣẹ́ abẹ títí di ìgbà tí mo sọ fun lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí mo ṣiṣẹ́ abẹ náà."

Wọ́n fi àwọn nǹkan lẹ ojú Emily lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ tán. Ó wà lórí ibùsùn, tó sì na ìka méjì sókè

Oríṣun àwòrán, @hotgirlenhancements

Àjọ British Association of Aesthetic Plastic Surgeons (BAAPS) sọ pé àwọn èèyàn tó ń ṣe iṣẹ́ abẹ láti mú àtúnṣe bá ojú wọn ti lékún pẹ̀lú ìdá mẹ́jọ láàárín oṣù mẹ́fà ní orílẹ̀ èdè UK. Wọn kò ṣe àtúpalẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọjọ́ orí àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ń ní àyípadà ti ń bá àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà.

Èyí náà ń wáyé ní àwọn apá ibòmíràn káàkiri pẹ̀lú bí American Society of Plastic Surgeon ṣe sọ pé àlékún ti bá iye àwọn èèyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùndínláàádọ́ta sí ọgọ́ta ọdún tó ń ṣiṣẹ́ abẹ àtúnṣe ojú.

Nora Nugent, ààrẹ BAAPS gbàgbọ́ pé ọ̀pọ̀ ìdí ló ń ṣokùnfà àlékún yìí tó fi mọ́ bí àwọn èèyàn tó ń lo oògùn láti mú ara sísan dínkù ṣe ń pọ̀ si.

"Lílo oògùn láti fi mú ara sísan dínkù le mú kí ẹran pọ̀ lára èyí tí ṣíṣe iṣẹ́ abẹ le dínkù. Tí ìgbèrú sì tib á ìmọ̀ ẹ̀rọ, èyí tó túmọ̀ sí pé àwọn iṣẹ́ abẹ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ mú ewu dání mọ́ bíi ti àwọn ayé ìgbanì."

Àwòrán obìnrin tí wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ sí lójú tó ń wòkè, tí wọ́n sì ya àwọn àwòrán kan sójú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Síbẹ̀, ṣíṣe iṣẹ́ abẹ ojú jẹ́ èyí tó jẹ́ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nìkan ló lè ṣe é, dókítà oníṣẹ́ abẹ tó ní iléeṣẹ́ tó forúkọsílẹ̀ àti àwọn ohun èèlò tó péye

Ní ilé ìwòsàn rẹ̀ tó wà ní Bristol, oníṣẹ́ abẹ Simon Lee ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ àtúnṣe ojú – tó sì fi fídíò kan hàn mí lára wọn.

Fún gbogbo àsìkò tó lò láti fi ṣiṣẹ́ abẹ náà, ẹni náà kò sùn. Wọ́n gun ní abẹ́rẹ́ tí iṣẹ́ abẹ náà kò fi ní dùn-ún.

Ó ṣe bí ẹni pé ó sín gbẹ́rẹ́ díẹ̀díẹ̀ si lójú ṣáájú kó tó bọ́ sí abẹ́ ara rẹ̀, inú ọ̀rá débi inú àwọn inú ẹ̀yà arak ó tó di pé ó mú àtúnṣe bá ojú náà.

Nígbà tó máa fi parí, ẹni tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà lójú rẹ̀ rẹ́rìn-ín músẹ́.

Lee wòye pé ọ̀kan lára ìdí tí iṣẹ́ abẹ náà fi ń wọ́pọ̀ báyìí ni pé ó ti rọrùn láti ṣe. Ó ní àwọn kìí kun àwọn tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ náà lórun ní ilé ìwòsàn wọn.

"Àyípadà ọ̀tun ní ẹ̀ka yìí bí ìdàgbàsókè ṣe ń wáyé lemọ́lemọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ abẹ tó wà fún ọrùn àti ìjàgbọ̀n ṣì gbajúmọ̀, àwọn apá ojú míì náà ti ń wọ́pọ̀ pàápàá àwọn tó máa ń ṣàfihàn pé èèyàn ti ń dàgbà," ó sọ.

Oníṣẹ́ abẹ náà sọ pé àwọn iṣẹ́ abẹ àtúnṣe ojú dára fún àwọn tí ọjọ́ orí wọn bá ti lé ogójì ọdún ṣùgbọ́n ó jẹ́ iṣẹ́ abẹ tó lágbára fún àwọn tí ọjọ́ orí wọn ṣì wà láàárín ogún sí ogójì ọdún.

Ó ní ọ̀pọ̀ ewu ló máa ń wáyé látara àwọn iṣẹ́ abẹ yìí bíi hematoma, necrosis, alopecia àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣíṣe iṣẹ́ abẹ ojú le ná èèyàn tó £15,000 sí £45,000 ní UK ṣùgbọ́n àwọn ilé ìwòsàn kan ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà fún £5,000.

Àwọn onímọ̀ sọ pé ó ṣe pàtàkì fún àwọn èèyàn láti máa ṣe ìwádìí kí wọ́n tó yan ẹni tó máa báwọn ṣe iṣẹ́ abẹ ojú wọn.

Àkójọpọ̀ àwòrán Julia Gilando ṣáájú àti lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ ojú

Oríṣun àwòrán, Julia Gilando

Àkọlé àwòrán, Julia Gilando went to Turkey for her surgery

Julia Gilando, ẹni ọdún 34, pinnu láti ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi ṣe àtúnṣe ojú rẹ̀ lẹ́yìn tó ti ní ìṣòro pẹ̀lú ìjàgbọ̀n rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ sọ pé àwọn kò rí nǹkan tó ṣe ojú rẹ̀ ṣùgbọ́n tó tẹ̀lé ọkàn rẹ̀ tó sì lọ sí Turkey láti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ èyí tó ná $8,000 (£6,000) lé lórí.

Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìkìlọ̀ tó wà nídìí ṣíṣe iṣẹ́ abẹ ní Turkey, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ látàrí bí owó rẹ̀ kò ṣe wọ́n tó àwọn ti orílẹ̀ èdè míì.

"Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, mo rò pé èrò náà kò dára tó ṣùgbọ́n mo ṣe ìwádìí mi, mo sì pinnu láti lọ ṣé, Ms Gilando sọ, onímọ̀ ètò ìlera sọ. " Ẹ̀rù ń bà mí, mo wà ní orílẹ̀ èdè míì, èmi nìkan, tí mi ò sì gbọ́ èdè wọn."

"Ọjọ́ méjì ni mo lò nílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ mi, tí mò ń ṣe gbogbo nǹkan fúnra mi. Gbogbo ojú mi wú mi ò ríràn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.

Àwọn olùwádìí ń kọminú pé ṣe ṣé ṣiṣe iṣẹ́ abẹ máa ń fún àwọn èèyàn ní ìgboyà gẹ́gẹ́ bí àwọn tó máa ń ṣe ìpolongo ṣíṣe rẹ̀ ṣe máa ń sọ.

Onímọ̀ nípa ara kan ní Centre of Appearance Research ti ilé ẹ̀kọ́ gíga University of West England, Kristy Garbett, ṣàlàyé pé àwọn èèyàn ń kàn máa ti ara wọn ni.

"A máa fi ara wa wé àwọn míì púpọ̀ pàápàá nígbà tí a bá ń ṣe fídíò, wo àwọn ayélujára."

"AI, àwọn ohun amójúyàtọ̀ wà lára ohun tó ń mú kí àwọn èèyàn máa ara wọn ní ohun tí wọn kò jẹ́. Bákan náà ni à ń rí tí àwọn èèyàn kò rí ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láti fi ṣe àtúnṣe ara bí ohun tó burú mọ́."

Ó ní àwọn ìlúmọ̀ọ́ká tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ abẹ yìí lọ́nà kan jẹ́ ohun tó dára, tó sì jẹ́ ohun tó ń kọnilóminú ní ìdàkejì bí wọ́n ṣe ti mú un bí ẹni pé ohun tó bójúmu fún ìgbé ayé ni.

Àkójọ àwọn àwòrán ojú Caroline Stanbury kó tó ṣe iṣẹ́ abẹ àti lẹ́yìn tó ṣe é tán. Nínú àwòrán àkọ́kọ́, ó ń wo ẹ̀rọ ayàwòrán pẹ̀lú aṣọ pupa tó wọ̀. Àwòrán tó wà láàárín ṣàfihàn bí wọ́n ṣe fi aṣọ we lójú pẹ̀lú aṣọ ilé ìwòsàn lọ́rùn. Inú àwòrán tó gbẹ̀yìn ló wọ aṣọ aláwọ̀ èsúrú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Caroline Stanbury

Àkọlé àwòrán, Caroline Stanbury júwe iṣẹ́ tó ṣe bí nǹkan tó dára jùlọ tó ṣe

Caroline Stanbury, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ nílé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán, tó sì wà lára àwọn tó kópa níbi ètò Real Housewives of Dubai ṣe iṣẹ́ abẹ àtúnṣe ojú ní ọdún méjì sẹ́yìn nígbà tó wà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta lòdì sí bí gbogbo èèyàn ṣe kìí nílọ̀ láti má ṣe é, pé ó ṣì kéré.

"Ó jẹ́ ohun tó dára jùlọ tí mo ṣe," Caroline sọ. "Kí nídìí tí mo ṣe nílò láti dúró di ìgbà tí mà á pé ọgọ́ta ọdún kí n tó ṣe é. Mo fẹ́ kí n dàbí èwe láti àsìkò yìí."

Ẹní tó ti ń lo Botox àti fillers fún ogún, ó ní ojú òun ti ń rí bákan. $45,000 (£34,000) ló ná láti fi ṣe àtúnṣe ojú ní Amẹ́ríkà.

"Mo ṣì dàbí èmi náà ni, iṣẹ́ abẹ yìí ti fún mi ní ogún ọdún láti dàbí èwe," ó sọ.

Alexis Verpaele, oníṣẹ́ abẹ ní Belgium, tó sì ní àwọn oníbàárà káàkiri àgbáyé tó fi mọ́ UK sọ pé iye àwọn ọ̀dọ́ tó ń wá fún iṣẹ́ abẹ náà jẹ́ ohun tó máa ń kọ òun lóminú.

Ó máa ń bá àwọn oníbàárà rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe rí láì ṣe ohun tó lágbára bí àwọn iṣẹ́ abẹ náà.

"Tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ nígbà tí wọ́n wà ní ogún ọdún, iṣẹ́ abẹ́ náà máa lò tó ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún.

"Èyí túmọ̀ sí pé nígbà tí wọ́n bá máa fi pé ọgọ́ta ọdún, wọ́n ti máa ṣe iṣẹ́ abẹ mẹ́ta," De Verpaele sọ.

"Ohun tó lágbára fún ojú kan láti kojú nìyẹn ìyẹn tí kò bá sí ìdíwọ́ kankan.