Nigeria Yahoo Boys: Ìjọba Amẹrika fi ojú àwọn ọmọ Yahoo mẹ́fà léde, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá wọn

Oríṣun àwòrán, Other
Ijọba ilẹ Amẹrika ti gbe igbesẹ lati fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria mẹfa ti wọn fẹsun kan pe wọn lu awọn ọmọ ilẹ naa ni jibiti owo to le ni miliọnu mẹfa dọla.
Ninu atẹjade kan to fi soju opo ileeṣẹ to n mojuto ẹka eto iṣuna rẹ, ijọba Amẹrika sọ pe oun ti gbẹsẹ le ile ati gbogbo ohun ini to jẹ ti awọn afurasi naa to wa nilẹ Amẹrika.
Ìjọba Amẹrika fi ojú àwọn ọmọ Yahoo mẹ́fà léde, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá wọn
Wọn fi ẹsun kan awọn ọmọ Naijiria ọhun pe wọn maa n dibọn bi oniṣowo ti wọn si maa n parọ gba owo gọbọi lọwọ awọn to ba ko si panpẹ wọn.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn afurasi naa ma n dibọn bi ololufẹ awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lati lu wọn ni jibiti.
Bẹẹ naa ni wọn ni wọn ti fofin de awọn eeyan lati ba wọn dowo pọ.
Lara awọn afurasi ti wọn fi orukọ wọn lede ni Richard Uzuh, ti wọn fẹsun kan pe o ma n kọwe ranṣẹ si awọn eeyan bi pe ọga ileeṣẹ nla kan lo n kọwe si wọn lọna ati gba owo lọwọ wọn.
Ilẹ Amẹrika tun fi oju Micheal Olorunyomi lede gẹgẹ bi oni jibiti to maa n lo ori ayelujara awọn to ba n wa ololufẹ lati fi ṣe gbajuẹ.Koda, wọn ni owo to ti fi magoago gba lọwọ awọn eeyan n lọ si nnkan bi miliọnu kan dọla.
Awọn to ku ti wọn fi oju wọn lede ni Alex Ogunshakin, Felix Okpoh, Nnamdi Benson, ati Abiola Kayode ti wọn ni wọn ma n fi ọrọ ifẹ lu jibiti.
Ijọba ilẹ naa ti wa ni oun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri pe gbogbo awọn to ba lo gbajuẹ fun ọmọ ilẹ wọn ko ni lọ lai fi oju wina ofin.















