Burundi: Wọ́n búra fún Evariste Ndayishimiye bii Ààrẹ Burundi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bii aarẹ to jẹ saaju rẹ, eyiun Ọgbẹni Nkurunziza, Ọgagun Ndayishimiye bori ikọlu ti wọn ṣe sawọn akẹkọọ to jẹ ẹya Hutu ninu ọgba ile ẹkọ fasiti naa, to wa ni olu ilu tẹlẹ fun orilẹ-ede Burundi, Bujumbura.
Idi ree to fi sa kuro ni orilẹ-ede naa, lọ dara pọ mọ igun ọmọ-ogun ọlọtẹ, ti wọn kan-an nipa fun lati doju ija kọ ìjọba ilẹ Burundi, ti ẹya Tutsi n lewaju rẹ.
Ọgagun Ndayishimiye ṣíṣẹ pọ timọ timọ pẹlu Ọgbẹni Nkurunziza lasiko ipade alaafia to waye nilu Arusha laarin ìjọba Burundi ati igun ọlọtẹ FDD.
Nitori abajade ipade alaafia to waye lọdun 2003 eyi to mu ki igun ọlọtẹ pin agbara pẹlu ijọba, Ọgagun Ndayishimiye de ile de olori ọmọ ogun ilẹ Burundi nigba naa.
Nigba to di ọdun 2006, wọn yan sipo Minisita fun ọrọ abẹle, ko to wa di olugbani nimọran si aarẹ ologun ati akọwe apapọ fun ijọba ẹgbẹ CNDD-FDD to n dari orilẹ-ede naa.
Ọgagun Ndayishimiye, to bi ọmọ mẹfa, lo jẹ olujọsin gidi ninu ijọ Katoliki, gẹgẹ bii aarẹ to ṣe ijọba saaju rẹ, oun naa n tẹnumọ ojuse Ọlọrun ninu iselu.
Aarẹ tuntun yii lo n gba akoso orilẹ-ede ti awujọ agbaye ti dẹyẹ si, ti adehun rẹ pẹlu awọn to n saanu fun si buru jai.
Aarẹ to wa nipo saaju rẹ si ni wọn fi ẹsun kan pe o n dari ijọba to n tẹ ẹtọ ọmọniyan loju pupọ, to si tun n kọju oro sawọn alatako, akọroyin atawọn ajafẹtọ ẹni.
Bakan naa ni orilẹ-ede ọhun to n wọya ija pẹlu ajakalẹ arun Coronavirus, eyi ti aarẹ to jẹ saaju, foju tẹnbẹlu rẹ.
Nitori ete iditẹ gba ijọba to fori ṣanpọn lọdun 2015, ogunlọgọ awọn ọmọ orilẹede Burundi lo sa kuro nilẹ naa lọ sawọn ibudo atipo ni awọn orilẹede to mule ti wọn.
Ta ni Ààrẹ tuntun tí wọn yóò búra wọlé fún ní Burundi lónìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni ọdun mejilelaadọta ni Evariste Ndayishimiye, aarẹ tuntun ti wọn yan ni Burundi ti ireti si wa pe wọn yoo bura wọle fun un lonii ọjọbọ ọsẹ.
Gbogbo eniyan ri i gẹgẹ bii onirẹlẹ eniyan ati olusin Ọlọrun.
O jẹ ọkan lara awọn gbajugbaja ọgagun lati ọdun 2005 nigba ti awọn ọrẹ timọ timọ ati akẹgbẹ rẹ ditẹ mọ ọ, Pierre Nkurunziza gbajọba.
Ọgagun Evariste Ndayishimiye jẹ akẹkọ imọ ofin ni ile iwe giga fasiti Burundi nigba ti ogun abẹle dide lọdun 1993 lẹyin ti wọn pa aarẹ ijọba awaarawa akọkọ ti Burundi ni, Melchior Ndadaye.
Bii ti ẹni to gba eku ida lọwọ rẹ, Pierre Nkurunziza lọdun 1995, Ọgbẹni Ndayishimiye mori bọ lọwọ iku ti wọn o ba pa a nigba ti wọn n pa awọn akẹkọ ẹya Hutu nileewe rẹ ni olu ilu orilẹede naa, Bujumbura.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba naa lo sa kuro lorilẹede to si dara pọ mọ ikọ awọn olugbẹsan lati koju ija si ijọba ti ẹya Tutsi n dari nigba naa.
Ọgbẹni Ndayishimiye gbaruku ti Pierre Nkurunziza o si ba a ṣiṣẹ papọ lasiko akanṣe ijiroro fun alafia ti wọn pe ni "Arusha peace talks" laarin ijọba atawọn FDD rebels.
Fun apẹrẹ, lọdun 1993 nigba ti FDD rebels pin agbara pẹlu ijọba Ọgbẹni Ndayishimiye ṣe igbakeji ọga awọn ọmọ ogun Burundi nigba naa, akẹgbẹ rẹ, Nkurunziza to jẹ minisita ọrọ abẹle.
Diẹ lasan ni apẹrẹ eleyii ninu ọpọlọpọ ajọṣepọ ti wọn ṣe.
Ọgbẹni Ndayishimiye jẹ baba ọlọmọ marun o si jẹ ọmọ ijọ katoliki tọkan tọkan to tun tẹle ọgbọn amulo ẹni to gbesẹ le e lọwọ nipa "titẹnumọ ohun tii ṣe ti Ọlọrun" ninu oṣelu.
Aarẹ tuntun yii n gbajọba orilẹede ti wọn fi ẹsun kan ẹni to gbaṣẹ lọwọ ẹ pe ijọba to dari tapa si ofin ẹtọ ọmọniyan ati ainaani ẹgbẹ alatako, awọn oniroyin atawọn ajafẹtọ.
Bakan naa, orilẹede yii n koju Coronavirus eyi ti aṣaju rẹ foju kere.
Latari ifipagbajọba eyi to kuna lọdun 2015, ẹgbẹgbẹrun ara Burundi lo ti sa kuro niluu lati lọ ṣatipo lawọn orilẹede ẹgbẹ wọn.
Ẹwẹ, aarẹ tuntun yoo ni lati bẹrẹ ijọba tirẹ lakọtun ni ti yoo si ṣẹṣẹ tun ṣagbejade ilana adari tuntun ni Burundi.














