Major US Twitter accounts hacked: Ẹ wo bí àwọn gbájúẹ̀ ṣe ṣọṣẹ́ ní Amerika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọlọla lorilẹede Amerika ti lugbadi awọn gbajuẹ lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter pẹlu imọ ẹrọ ayederu Bitcoin.
Oju opo Barack Obama, Bill Gates, Elon Musk, Jeff Bezos ati Joe Biden to fi mọ Kanye West lo lugbadi awọn gbajuẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ni oju opo ikansiraẹni Gates Bill, nkan ti wọn ko si bẹ ni pe ti o ba fi $1000 sọwọ si mi, ma a fun yin pada ni $2,000.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Oju ọpọ ikansiraẹni Apple naa ko gbẹyin ni bẹ. Ohun ti wọn ko si bẹ ni pe ki o fi owo ṣeranwọ fun Bitcoin.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ninu ọrọ wọn, awọn alaṣẹ oju ọpọ Twitter ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn pẹlu bi awọn gbajuẹ ṣe gba owo lọwọ awọn eniyan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn fikun pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Wo bí o ṣe leè lo èròjà agbohùnsílẹ̀ tuntun tí Twitter gbé dé
Awọn eeyan ti n pariwo lori ayelujara atawọn opo ikansiraẹni gbogbo lẹyin ti ileeṣẹ Twitter kede pe awọn ti gbe eroja kan dide loju opo wọn eyi to lee mu ki awọn eeyan maa ka ohun wọn lati fi ranṣẹ pẹlu akọsilẹ wọn gbogbo lori Twitter.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, awọn foonu to ni eroja iOS nikan lanfani naa ṣi silẹ fun.
Eyi si tunmọ si pe awọn to ba n lo foonu to ni eroja Android ko tii le lanfani ati loo.
Ileeṣẹ naa ṣalaye pe, idi ti wọn fi gbe sita ko yẹ lẹyin bi awọn ọrọ kan kii ṣe n duro bi awọn to kọ wọn ṣe fẹ loju opo twitter, ṣugbọn bi wọn ba fi ẹnu wọn sọ ọ yoo tubs gbe pẹẹli sii.
Bawo wa ni eroja aka ohun silẹ yii yoo ṣe maa ṣiṣẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogoje iṣẹju nikan lo lanfani ati gba.
ṣe ẹ ranti pe nigba ti twitter kọkọ bẹrẹ, iwọnba ogoje ọrọ pere nikan lo lee gba ni atẹjade kan. O dabi ẹni pe irufẹ ara yii naa ni wọn fẹ fi bẹrẹ pẹlu eroja aka ohun silẹ naa. O ko nilo lati tẹ bọtini idaduro nitori, gẹgẹ bi ileeṣẹ twitter ṣe sọ eroja naa ni yoo funra rẹ daa duro ti yoo si tun bẹrẹ omiran lẹsẹkẹsẹ.
Ko saye ati lo o fi da eeyan lohun
Ẹ ko ni lee lo ohun ti o ba ka silẹ pẹlu eroja naa lati fi da eeyan lohun tabi taare atẹjiṣẹ eeyan kan si ẹlomiran.
O lee maa gbọ ọ bi o ba n ṣe nnkan miran.
Twitter ko fẹ ki ọrọ a n ka ohun silẹ tabi gbọ ohun ti a ka silẹ di eyi ti ko ni jẹ kawọn onibara wọn o ma lee ṣe awsn nnkan miran to ba yẹ ki wọn ṣe.
Ko si fun ikansiraẹni
Bi o ba n gbọ ohun ti a ka silẹ ohun ti yoo kọkọ wa si ọ lọkan ni oju opo ikansiraẹni Whatsapp nibi tawọn eeyan ti maa n lo ohun ti wọn ka silẹ fi ba ara wọn sọrọ.
Amọṣa ọrọ ko ni ri bẹẹ fun ti twitter yii. Ohun ti wọn fẹ ṣe ni pe oju ila itagbangba (public forum) wọn nikan ni ohun ti araalu ba ka yoo maa wa.












