Ajimobi: Obaseki, Ambode àtàwọn gómìnà míràn tí tírélà gba ààrín àwọn àtàwọn bàbá ìsàlẹ̀ wọn kọjá

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC

Àkọlé àwòrán, Idibo aarẹ ọdun 2023

Awọn ‘Baba Isalẹ’ ni eto oṣelu Naijiria ni ọpọlọpọ eniyan gbagbọ wi pe wọn kii dije dupo fun ara wọn,

Amọ awọn ni o maa n sọ nipa ẹni ti yoo bori tabi ti yoo kuna ni idibo sipo lagbegbe wọn.

Gẹgẹ bi eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Edo ṣe ti n sunmọle bayii, awọn Baba Isalẹ yii ni wọn n sọ bi o ṣe maa ri.

Awọn Baba Iṣalẹ yii ni wọn maa n lo owo ati ipọ wọn lati fi gbaruku ti ẹni ti wọn ba tilẹyin ninu ididbo naa.

Awọn eniyan lo gbagbọ pe ẹni to ba ni Baba isalẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ni anfaani lati dije dupo ti wọn yoo si bori, bi wọn ko tilẹ ni ọpọlọpọ imọ nipa oṣelu.

Wo gómìnà márùn ún tí wọ́n ti fojú winá pẹ̀lú bàbá ìsàlẹ̀ wọ̀n

Saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo ni Osu Kẹwaa, Odun 2020, ohun to gba ẹnu awọn eniyan kan ni ija to bẹ silẹ laarin Adams Oshiomọlẹ ati Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki.

Ni ọdun 2016 ni Obaseki deede yoju si gbagede oṣelu Naijiria lẹyin ti Adams Oshiomole gbe e wa lati ilu Eko nibi ti o ti n ṣiṣẹ, ti ọpọ eniyan ko si mọ ọ ni gbagede oṣelu ipinlẹ Edo.

Iroyin gbe e wi pe lasiko idibo sipo gomina ni ọdun 2016 naa ni Gomina Adams Oshiomole gbe ipolongo rẹ kari,

Nibe naa lo si ti n logun rẹ fun awọn eniyan nigba naa lati tako Pasito Osagie Ize-Iyamu to n dije dupo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP.

Nibayii, ti ọdun mẹrin miran ti de, ọpọlọpọ nkan ti yi pada, Adams Oshiomọle ti le Obaseki kuro lẹgbẹ Oṣelu APC

Eyi waye lẹyin ti o fi lede wi pe oun naa fẹ dije dupo gomina fun saa keji lẹgbẹ oṣelu APC.

Ibaṣepọ laarin awọn mejeeji ti fori sanpọn, ti Obaseki si ti mura lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣẹlu PDP.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC

Àkọlé àwòrán, Idibo aarẹ ọdun 2023

Ambode ati Tinubu

Ohun itiju lo jẹ fun Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambode lasiko idibo sipo gomina ni ipinlẹ Eko lọdun 2019 nibi ipolongo kan.

Eyi sele nigba ti baba isalẹ rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu na ọwọ Babajide Sanwo-Olu sọke gẹgẹ bi oludije sipo gomina ni ipinlẹ Eko lẹyin to ni ki Ambode lo rọọkun nilẹ lẹyin ọdun mẹrin to lo nipo.

Amọ, ohun ti awọn eniyan sọ ni pe, bi Tinubu ṣẹ na ọwọ rẹ soke ni idibo sipo gomina lọdun 2016 lasiko ti ko si ẹni to mọ ọ rara, ti ko tilẹ di ipo ọṣelu kankan mu tẹlẹ ki o to di igba naa.

Nigba naa, gomina to wa nibẹ, Babatunde Fashola fẹ ki kọmisọnna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Supo Shasore dije dupo sipo gomina lasiko naa,

Amọ Tinubu kọ jalẹ pe Ambode ni yoo ṣe gomina naa pẹlu gbogbo agbara rẹ.

Ọdun 2019 ni idibo gbogboogbo naa ni Babajide Sanwo-Olu naa fi idi Ambode janlẹ ninu idibo abẹlẹ saaju idibo sipo gomina naa, amọ Ambode si wa ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Ajimobi fẹ́ di ‘Jagaban‘ tí ìpínlẹ̀ Oyo - Ladoja

Baba isalẹ Adedibu ati Ladoja

Rashidi Ladoja jẹ gomina ipinlẹ Oyo ni ọdun 2003 si ọdun 2007, ti Adedibu si ṣe agbatẹru fun Ladoja gẹgẹ bi oludije lẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2003, ti o si ran an lọwọ lati bori.

Ladọja fun ara rẹ fi idi ẹ mulẹ fun ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Human RIghts Watch pe Adedibu ṣe bẹbẹ lasiko idibo lati jẹ ki o bori idibo naa.

Amọ o ni bi oun ṣe wole ni o gbe igbesẹ lati gba ara rẹ lọwọ Adedibu, ti oun ko si tẹle awọn ilana rẹ mọ.

Ladọja ni oun kọ lati jẹ ki Adedibu lu owo ipinlẹ naa ni ponpo lẹyin ti Adedibu ni ki oun maa fi ida marundinlọgbọn owo Security Vote to to miliọnu marundinlogun Naira si apo oun ni oṣoosu.

Bakan naa ni Ladoja kọ lati jẹ ki Baba iṣalẹ rẹ fi orukọ silẹ fun awọn Kọmisọnna ti wọn yoo jọ ṣe ijọba.

Ninu ọrọ tirẹ, Adedibu ni alaamọrẹ ẹda ni Ladọja, ti o si saa gbogbo ipa rẹ lati jẹ ki o kuro nipo gomina nipinlẹ naa, amọ o lo saa rẹ tan, idibo miran ni ko bori ninu rẹ mọ.

Supporters of Rabiu Kwankwaso, wearing red hats, on a cattle campaign cart in Kano state, Nigeria
Àkọlé àwòrán, Supporters of Rabiu Kwankwaso wear red hats

Ganduje ati Kwankwaso

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje naa ti pin gaari pẹlu baba isalẹ rẹ, Rabiu Kwankwaso to ṣe agbatẹru fun un lasiko idibo sipo gomina ni ọdun 2016.

Ganduje sọ wi pe idi ti oun fi yapa kuro labẹ Kwankwaso ni pe o jẹ ẹni ti imọtara ẹni nikan n da laamu.

O fẹsun kan an wi pe nitori o jẹ baba isalẹ fun awọn, o fẹ gaba lẹ wọn lori, ki o si sakoso gbogbo nkan to n wọlẹ si ipinlẹ naa fun ara rẹ nikan.

Amọ, Kwankwanso naa lo fa ọwọ rẹ soke ni idibọ ọdun 2016.

Godswill Akpabio

Godswill Akpabio lati Udom Gabriel Emmanuel

Ọpọlọ̀pọ eniyan lo gbagbọ wi pe Godswill Akpabio ni baba isalẹ fun wọn ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Amọ ija to de lorin di owe laarin Gomina ipinlẹ naa, Udom Gabriel ati Akpabio lẹyin to kuro ni ẹgbẹ oselu PDP lọ si ẹgbẹ oṣelu APC.

Ohun to han gbangba ni si awọn eniyan pe Udom di gomina ipinlẹ Akwa Ibom nitori ibaṣepọ rẹ pẹlu Baba isalẹ Akpabio ti o gbe le ejika lati dije dupo gomina ni ọdun 2015 to si yege.

Amọ ni bayii wọn ko foju rinju mọ lẹyin ti Udom yẹba fun Akpabio, eleyii to fa gbọnmi si omi o to laaarin wọn , ki wọn to pin gari, ti Akpabio si fi PDP silẹ lọ si APC.

Àkọlé fídíò, Toyin Ibietan: Àlòkù táyà ọkọ̀ ló mú mi rí nǹkan ṣe lásìkò ìgbélé COVID-19