Manchester City: De Bruyne gba àmì ẹ̀yẹ Premier League mọ́ Henderson lọ́wọ́ lẹ́yìn tí Lyon fi City ṣ'ẹ̀sín

Kevin de Bruyne

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ti wọn kan abuku oloronbo ninu idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 2020, ẹlẹsẹ-ayo, Kevin de Bruyne gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ninu idije Premier League fun saa bọọlu to ṣẹṣẹ pari.

De Bruyne gba ami ẹyẹ naa mọ Trent Alexander-Arnold, Jordan Henderson ati Sadio Mane lati Liverpool, Danny Ings ti Southampton, ẹlẹsẹ ayo Leicester, Jamie Vardy ati aṣọle Burnley Nick Pope lọwọ.

De Bruyne gba goolu mẹtala sawaọn fun Man City bo tilẹ jẹ pe ipo keji ni wọn gba ti Liverpool si gba ife Premier League.

De Bruyne to jẹ ọmọbibi ilẹ Belgium ṣe okunfa bi Man City ṣe gba ogun goolu sawọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Agbabọọlu Arsenal tẹlẹ ri, Thierry Henry nikan lo ti ṣe iru rẹ ri lati igba ti Premier League ti bẹrẹ.

Awọn balogun ẹgbẹ agbabọọlu ogun to wa ni Premier atawọn onimọ nipa ere bọọlu lo dibo lati yan de Bruyne gẹgẹ bi agbabọọlu to dantọ julọ.

De Bruyne ni agbabọọlu ilẹ Belgium ti yoo gbami ẹyẹ naa lẹyin ti Vincent Kompany ati Eden Hazard kọkọ gba a siwaju.

Ẹwẹ, ọjọ Abamẹta ni akọnimọọgba Liverpool, Jurgen Klopp gba ami ẹyẹ akọnimọọgba to pegede julọ ni saa bọọlu 2019/2020.

Premier League gbìnàyá padà, ọ̀gá àti ọmọṣẹ́ fìjà pẹ̀ta

Lati ayebaye lawọn aṣiwaju ti maa n gbadura pe ki ọmọlẹyin wọn o gberi koda ju awọn gan an lọ.

Ni ere bọọlu gbigba atawọn ere idaraya miran, ọpọ igba ni ọga ati ẹni to ti figbakan ri jẹ ọmọṣẹ rẹ ni ere idaraya maa n pada wa figagbaga. Bẹẹni awọn tẹgbọntaburo a maa jọ tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa.

Lọjọru ni ifẹsẹwọnsẹ idije Premiership ilẹ Gẹẹsi yoo tun gbinaya lẹyin idaduro oṣu bii mẹta nitori arun coronavirus to bẹ silẹ kaakiri agbaye.

Pataki ninu ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye loni ni laarin Manchester city ati Arsenal.

Yatọ si pe ifigagbaga laarin ẹgbẹ agbabọọẹu mejeeji yii a maa larinrin, ohun kan ti yoo tun tayọ ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn tọtẹ yii ni awọn akọnimọọgba mejeeji ti yoo maa leawju awọn ikọ mejeeji; Pep Guardiola ati Mikel Arteta.

Guardiola ati Arteta

Oríṣun àwòrán, Victoria Haydn

Ni iwoyi saa liigi premiership to lọ, ọmọ iṣẹ ni Mikel Arteta jẹ labẹ Pep Guardiola ki wọn to yan an gẹgẹ bi olukọni tuntun fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Awọn mejeeji yii yoo ba forikori fun igba akọkọ lẹyin ti Arteta fi Manchester city silẹ.

Ireti ọpọ onwoye bọọẹu ni pe ikọ Manchester city yoo fi ajuls han ni ifẹsẹwọnsẹ yii. Awọn ikọ mejeeji lo ni kudiẹkudiẹ lọwọ ẹyin wọn ṣugbọn ko si aniani pe awọn atamatase agbawaju fun ikọ Man city yoo lee ṣe ọpọlọpọ ọṣẹ.

Ni tiwọn, ami mẹta pere lo n dabu Arsenal ninu ilepa wọn lati ri aaye fun idije Europa ni saa to n bọ, gbogbo ipa ni wọn yoo fẹ sa lati lee kopa ninu awọn idije ilẹ Yuroopu ni saa to n bọ.