Barcelona vs Bayern: Koeman di akọ́nimọ̀ọ́gbá Barcelona tuntun lẹ́yìn ìjàmbá Champions League

Ronald Koeman

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Omi tuntun ti ru lẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Ronald Koeman ti di akọnimọọgba tuntun ikọ naa.

Oun lo rọpo Quique Setien ti wọn ṣẹṣẹ fọwọ osi juwe ile fun un ni kopẹ kopẹ.

Koeman ẹni ọdun mẹtadinlọgọta fi iṣẹ rẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Netherlands silẹ nibi ti adehun to fọwọ si ti ku ọdun meji lati gba iṣẹ Barcelona.

Koeman gbabọọlu fun ikọ Barcelona laarin ọdun 1989 si 1995, o si gba ami ẹyẹ La Liga mẹrin ati ife ẹyẹ kan ni Yuropu.

Ronald Koeman gbe ife ami ẹyẹ Yuropu lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ronald Koeman gbami ẹyẹ Yuropu pẹlu Barca lọdun 1992

Ipo keji ni Barcelona gba ni saa bọọlu to ṣẹṣẹ pari ninu eyi ti wọn ko si ri ife kankan gba fun igba akọkọ lati ọdun 2008.

Lionel Messi ati Gerard Pique

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Barcelona to yan Ramon Planes gẹgẹ bi oludarieto kata-kara agbọọlu eleyi ti Eric Abidal di mu tẹlẹ ki wọn to ni ko maa lọ lọjọ Iṣẹgun.

Akitiyan lati yan akọnimọọgba mii bẹrẹ lẹyin ti Bayern Munich lu Barca lalu bolẹ ninu idije UEFA Champions League pẹlu ami ayo mẹjọ si meji.

Ìjàmbá ṣe wá ní Barcelona, aṣọ ò bá Ọmọ́ye wa mọ́- Gerard Pique

Paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta, bi oju ọhun ko ba fọ tan, yoo pada di bai bai. Bayii lọrọ ṣe ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ti Bayern Munich lu lalubami.

Ami ayo mẹjọ si meji ni Bayern fi ṣagba Barcelona ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lorilẹede Portugal lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2020.

Ọkan lara awọn gbajugbaja agbabọọlu Barcelona, adilemu, Gerard Pique ke gbajari pe abuku nla kan Barca, o ni omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu.

Pique ni kii ṣe igba akọkọ, tabi ekeji tabi ẹkẹta ti irufẹ abuku yii yoo kan Barcelona.

Adilemu naa sọ pe asiko ti to fun gbogbo agbabọọlu Barcelona lati ati awọn alaṣẹ lati wa nnkan ṣe si ina ẹgbẹ agbbọọlu naa to n jo ajo rẹyin bayii.

Amọ akọnimọọgba Barca fun ra rẹ, Quique Setien ni oun ko tii le sọ bo ya oun yoo fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ laipẹ.

Gerard Pique

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni otitọ ni pe ijamba ṣe Barca lọwọ Bayern, ṣugbọn ọrọ naa gba ki onikaluluku ronu ọna lati tẹ agbabọọlu Barca siwaju.

Ẹwẹ, agbabọọlu Manchester United nigba kan ri, Rio Ferdinand sọ pe asiko ti to fun ẹlẹsẹ ayo Lionel Messi lati ronu lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Barcelona.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ferdinand sọ pe pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe polukurumusu ni Barcelona bayii, o dabi wi pe asiko ti to fun Lionel Messi lati fi Barca silẹ.

Ohun ti Ferdinand n sọ ni pe bi a ba pẹ lori imi, eṣin keṣinṣin lo n ba ni nibẹ.