Sunday Igboho: Kò bójúmu bí wọn ṣe ní ká wá fi orúkọ́ sílẹ̀ bíi ọmọ ẹgbẹ́ Àmọ̀tekún lórí ayélujára

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Ilumọọka awujọ kan to tun jẹ ajafẹtọlu, Oloye Sunday Adeyemọ, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti gbarata lori ilana agbekalẹ ẹgbẹ Amotekun.

Igboho, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ohun ti awọn daba rẹ kọ ni ijọba n se, ko si tọ bi wọn se gbe Amotekun sabẹ ijọba rara.

O wa fi ọwọ gbaya pe oun funra oun gan setan lati lọ sere ọwọ ninu igbo pẹlu awọn ọdaran, ti wọn ba kan bura fun awọn nikan.

Bakan naa lo tun koro oju si bi wọn se ni kawọn eeyan to ba fẹ se Amotekun wa maa fi orukọ silẹ lori ayelujara, eyi to ni ko bojumu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tun wẹ, aarẹ ọdẹ Asọludẹrọ, Nureni Ajijola Anabi naa kin Igboho lẹyin pe ko yẹ ki ẹnikẹni ti ko ba fi ogun bura wa lara awọn Amotekun nitori wọn yoo ba ẹgbẹ naa jẹ.