Sunday Igboho: Òǹyẹ̀ kankan kò lè yẹ àgbékalẹ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunday_igboho
Ilumọọka olokoowo ati ajafẹtọ awujọ, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, ti woye pe onyẹ kankan ko le yẹ ikọ alaabo Amotekun.
Sunday Igboho woye ọrọ yii nigba to n sọ ero rẹ lori oniruuru atako to n waye nipa agbekalẹ ikọ alaabo ọhun, tawọn gomina mẹfẹẹfa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria da silẹ.
Igboho, nigba to n fesi si ọrọ asaaju ẹgbẹ Miyetti Allah nipinlẹ Bauchi, Alhaji Sadiq Ahmed, to ni ki ijọba wọgile ikọ naa nitori pe, ko si aabo mọ lati gbe nilẹ Yoruba nitori agbekalẹ ikọ Amotekun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Boko Haram gbọ̀nà àrà yọ, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló so àdó olóró mọ̀ láti kọlu Gómìnà Borno
- Ìṣòro jíjẹ́ ìyá n dáàgbé ló sọ mí di àtúnbí krístíẹ́nì - Remi Tinubu
- Kí ló ń fa wàhálà láàrín Kunle Afolayan àti Mike Ezuruonye lórí ayélujára?
- Ọmọ ṣá bàbá rẹ̀ pa, ohun tó sọ pé ó ṣe nìyí...
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san N50m fún obìnrin tó fìyà jẹ
- Mi o fi ìgbà kankan sọ pé Buhari ni yóò jẹ ààrẹ kẹ́yìn ní Nàìjíríà- Akintoye
Ahmed ni ikọ Amotekun jẹ idunkooko nla mọ isọkan orilẹede Naijira, lasiko to ba bẹrẹ isẹ aabo ẹmi ati dukia lẹkun naa.

O fikun pe, wọn se agbekalẹ ikọ Amotekun lati ba okoowo awọn ara oke ọya jẹ ni, ko si tun lee da wọn lọwọ kọ lati se ọrọ aje wọn lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.
Amọ nigba to n fun Ahmed lesi ọrọ rẹ, Sunday Igboho se apejuwe ọrọ yii bii iwa anikanjọpọn ati eyi ti ko boju mu.
"Gbogbo eeyan lo mọ awa Yoruba pe a ko ni mọra, ta si tun ni ifarada nipa awọn ara oke ọya, paapaa lasiko ti wọn ba tọ wa nija.
Nitori naa, asisọ ọrọ ni ki eeyan kan ni Amotekun n dunkooko mọ oun tabi jẹ ewu fun aabo ẹmi ati dukia, ọrọ naa ko ye mi."
Igboho tẹsiwaju pe, wọn se agbekalẹ ikọ alaabo ọhun lati daabo bo ẹmi ati dukia nilẹ Yoruba ni lai naani ẹya, ẹsin ti ẹni kọọkan n se.
"Amọ ki eeyan kan wa woye pe agbekalẹ ikọ alaabo Amotekun to wa lati gbe ijọba nigbọnwọ, ni yoo ba ọrọ aje awọn eeyan kan jẹ, jẹ iwa aimọkan ati ọna lati ba erongba rere agbekalẹ ikọ Amotekun jẹ."
Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n'Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Ọrọ di boo lọ, ko yago fun mi ladugbo Soka nilu Ibadan lasiko ti gende meji to gbe ohun ija oloro lọwọ, ti wọn pe ara wọn ni ọmọ onilẹ ya bo agbegbe naa.
Owurọ ọjọ Isẹgun ana niroyin gba igboro Ibadan kan, tawọn eeyan si n pe sori redio gbogbo nilu naa pe ẹmi awọn eeyan to n gbe ladugbo naa ko de tori awọn gende agbebọn to ya bo wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- Buhari, èyí to fí ogún ọdún pilẹ̀ wèrè lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó gẹ́ - Bishop Kukah
- "Òògùn ni wọ́n fi bò mí lójú tí mo fi bá ara mi láàrin àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn"
- Na òṣìṣẹ́ Amotekun, ko san ₦250,000 owó ìjìyà, ko sì tún fi ẹ̀wọ̀n oṣù kan jura
- Wọ́n yìnbọn pa àwọn tó fipá bá ọmọ ọdún 12 lòpọ̀ ní gbangba lẹyin ìdájọ́
- Ajínigbé méjì kàgbákò lásìkò tí wọ́n fẹ́ ẹ́ já ọmọ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ l'Ondo
A gbọ pe se ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ, tawọn eeyan si n sa asala fun ẹmi lasiko ti awọn ọmọ onilẹ ọhun ni ki awọn onile gbe ile wọn kuro lori ilẹ awọn.
Se lawọn ọmọde ati agba, alaboyun ati awọn iyalọmọ, to fi mọ awọn arugbo n sa asala fun ẹmi wọn, ti awọn to si laya lati beere pe ki lo fa isẹlẹ naa, jẹ ajẹkun iya.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ salaye pe ọpẹlọpẹ asaaju ọmọ Yoruba kan, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho to tete de sadugbo ọhun lasiko ti laasigbo naa gbona janin-jani.
A gbọ pe Igboho ati ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ Babatunde Arowolo, ti gbogbo eeyan mọ si Bako, lo de lasiko lati gba awọn eeyan adugbo naa silẹ, ni kete ti aawọn ọmọ onilẹ naa si foju gaani rẹ, ni wọn ba juba ehoro.
Sunday Igboho, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe, lootọ ni oun lọ si adugbo Soka lana lati gba awọn eeyan adugbo naa silẹ lọwọ ijẹgaba awọn ọmọ onilẹ.
O ni ni kete tawọn ọmọ onilẹ foju kan oun ati Bako ni wọn fẹsẹ fẹ, eyi to mu kawọn doola ofo ẹmi ati dukia ti ko ba waye latipasẹ isẹlẹ yii.
"Adugbo Soka nilu Ibadan ni mo n gbe, ti awọn agbegbọn kan si ya wọ adugbo mi lati maa dunkoko mọ awọn eeyan mi, n ko si lee la oju mi silẹ, ki n wa larọwọto, kawọn eeyan kan maa se awọn eeyan mi lese tabi pa wọn ni ipakupa.
Bakan naa ni Igboho ni o ti to ẹẹmẹfa ti awọn ọmọ onilẹ naa ti ya bo awọ̀n eeyan adugbo naa, ti wọn si n yinbọn ti wọn n pa awọn mẹkunnu, ti ọpọ wọn si ti ku lai jale, to si n beere pe se gbogbo mẹkunnu lo ni owo lọwọ lati tun ilẹ ra.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Awọn ara adugbo naa ti wa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati tete da si ọrọ naa tori kii se igba akọkọ ree ti awọn ọmọ onilẹ yoo wa maa dun mahuru-mahuru mọ wọn lori ilẹ ti wọn ti ra lati ọdun gbọọrọ.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi lati gbọ tẹnu rẹ, o ni ka pe oun pada laipẹ.















