Boko Haram: Ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ kọlu Gómìnà Borno lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aládòó olóró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin ti n jẹ jade nipa ọna ara ti ikọ Boko Haram fi ṣe ikọlu si Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ni igba keji.
N ṣe ni wọn so ado oloro mọ ara ketekete kan, ti wọn si kẹ si oju ọna ti ọkọ Gomina Zulum gba kọja.
Lasiko ti o n dari pada si Maiduguri lati ilu Baga ni iṣẹlẹ yii waye.
- Ìṣòro jíjẹ́ ìyá n dáàgbé ló sọ mí di àtúnbí krístíẹ́nì - Remi Tinubu
- Kí ló ń fa wàhálà láàrín Kunle Afolayan àti Mike Ezuruonye lórí ayélujára?
- Ọmọ ṣá bàbá rẹ̀ pa, ohun tó sọ pé ó ṣe nìyí...
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san N50m fún obìnrin tó fìyà jẹ
- Mi o fi ìgbà kankan sọ pé Buhari ni yóò jẹ ààrẹ kẹ́yìn ní Nàìjíríà- Akintoye
Ikọlu yii n waye lẹyin ọjọ meji ti wọn kọlu kẹyin, lasiko abẹwo rẹ si agbegbe kan lẹba adagun omi Lake Chad.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
O kere tan eeyan mejidinlogun lo ku ninu ikọlu taa n wi yii.
Lara wọn ni ọlọpaa ati ọmọ ogun mẹrinla wa ti awọn ara ilu mẹrin si pẹlu.
Ikọ Iswap to ṣe pe awọn ni wọn wa nidi ikọlu naa, yapa kuro lara Boko Haram to bẹrẹ ikọlu lọdun mẹwa sẹyin.
Eeyan kan to ba Gomina rin, ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni, ikọ ọhun dẹ pakute kẹtẹkẹtẹ ti wọn so ado oloro mọ ara rẹ, si oju ọna ti Gomina gba.
Nigba ti awọn ọmọ ologun yinbọn lu kẹtẹkẹtẹ naa, n ṣe ni ado oloro ara rẹ bu gbamu ti awọn ikọ agbesunmọmi si jade lati ṣina fun wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò fi ní bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì mọ́ lónìí
- Ẹgbẹ́ òkùnkùn yìnbọn lu ọmọ kan ní ikùn lásìkò ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn
- Laycon ni ọmọ ológo tó jáwé olúborí ní ètò BBNaija season 5 'Lockdown'
- Kí ló wà láàrin Olorì Badra àti Bobrisky, tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀?
- Wo ọ̀nà àbáyọ sí bo ṣe ń han‘run
- Ọ̀làjú sọ àṣà nù, wò ó báwọn obìnrin ṣe ń wà ọkọ kiri lórí ayélujára
- Nínú akànṣẹ́ mẹ́ta ọmọ Nàìjíríà tó dáńtọ́ lágbàáyé, Yorùbá méjì wà nínu wọn
Gomina Zulum lo n bọ lati ilu Baga to ti lo ṣe ayẹwo agbegbe naa, ti ogun Boko Haram ti jẹ ki ọpọlọpọ eniyan kuro nibẹ, tijọba ipinlẹ naa si woye pe, asiko ti to fun awọn eniyan lati pada sibẹ.
Amọ, iroyin ti o kọkọ jade ni pe eniyan ọgbọn lo ku ninu iṣẹlẹ naa lẹyin ti ikọ Boko Haram ṣekọlu si wọn.
Ni Oṣu Kẹfa,ọdun 2020 yii ni iru iṣẹlẹ naa waye, ti ikọ Boko Haram kọlu ọkọ gomina Zulum, eyi to jẹ ko pada si Maiduguri to ti n bọ.
Laipẹ yii ni ikọ Boko Haram naa pa ọkan lara awọn ọgagun ati ọmọogun mẹta miran lasiko ti wọn ṣe ikọlu si wọn.
Bakan naa ni awọn araalu to n gba ọna naa kọja, ni ikọ Boko Haram ma n da lọna, ti wọn a si gba owo lọwọ wọn, ji wọn gbe tabi ki wọn pa wọn.

Oríṣun àwòrán, Facebook/govborno
Boko Haram kọlu Gomina ipinlẹ Borno
O ti le ni eniyan ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogoji ti ikọ Boko Haram ti pa lati igba ti wọn ti n ṣọṣẹ lorilẹede Naijiria, ti wọn si ti sọ miliọnu meji eniyan di alairile gbe.
O kere tan awọn eeyan mẹrinla ti kagbako iku lọwọ afurasi ọmọ ikọ Boko Haram kan to ṣe ikọlu sawọn alaṣẹ ipinlẹ Borno lọjọ Ẹti.
Awọn alaṣẹ naa n kọwọrin pẹlu awọn ọmọ ogun lati ilu Monguno lọ si Baga nipinlẹ Borno.
Pupọ awọn to padanu ẹmi wọn jẹ ọmọ ileeṣẹ ọlọpaa ati ọmọ ogun Naijiria.
A ko ni iroyin to pọ nipa iṣẹlẹ naa ṣugbọn akọroyin BBC, Ishaq Khalid to ba awọn fijilante to n ran awọn ologun lọwọ sọrọ ni awọn ri oku mẹrinla ni abawọle ile iwosan Monguno.
Wọn ni ninu awọn tawọn ri, awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun wa ninu wọn.
Ohun ti a n gbọ ni pe ọpọ lo farapa ti awọn agbesunmọmi yi si gba ọpọ ọkọ lọwọ wọn.
A ko ti i le fidi ọrọ mulẹ awọn to ṣe ikọlu naa ṣugbọn awọn ọmọ ikọ Boko Haram a maa ṣoro lagbegbe yi loorekoore.
Awọn alaṣẹ ilẹ Naijiria ko ti i fidi ọrọ yi mulẹ.
Laipẹ yi ni awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi Boko Haram pa ọgagun ọmọ ogun Naijria kan to n dari ikọ ẹlẹẹkeeji Operation Lafiya Dole ni Borno yi kan naa.
Ko pẹ pupọ naa ti wọn ṣe ikọlu si Gomina ipinlẹ Borno Babagana Zulum lasiko to ṣabẹwo si Baga botilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun ni kii ṣe Boko Haram lo kọlu Gomina.

















