Boko Haram: Àwọn Alfa tíjọba Borno bẹ̀ lọ́wẹ̀ ti gbé ní Saudi fún ọ̀pọ̀ ọdún

Babagana Zulum

Oríṣun àwòrán, @mzk11uk

Ijọba ipinlẹ Borno ti gbọna mii yọ lọna ati fopin si ikọlu ẹgbẹ aṣẹrubalu Boko Haram, bi gomina ipinlẹ naa, Babagana Zulum ṣe bẹ awọn alfa ọgbọn lati Saudi lọwẹ lati ba gbadura fun ipinlẹ ọhun.

Agbẹnusọ fun gomina ọhun, Isa Gusau sọ fun awọn oniroyin pe awọn alfa naa to jẹ ọmọ Naijiria, ti gbe ni ilu Makka fun ọpọlọpọ ọdun.

Gusau ni, awọn alfa ọhun lo n fi tọsan toru gbadura ni Ka'aba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣalaye pe ẹni to dagba julọ ninu awọn alfa naa ti lo ogoji ọdun ni Ka'aba.

Agbẹnusọ fun gomina naa ni "Ka'aba jẹ ibi mimọ julọ to wa ni moṣalaṣi Al-Haram ni Makkah."

O sọ siwaju si pe, idi ti ijọba ọhun fi gbe igbesẹ lati bẹ awọn alfa naa lọwẹ wa lati ran awọn ọmọ ologun Nigeria lọwọ ninu ija wọn pẹlu ẹgbẹ Boko Haram.

Gusau ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Borno nilo adura gidigidi lasiko yii ki alafia le jọba ni ipinlẹ naa.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti ọga agba fun ajọ ologun Naijiria, Tukur Buratai ni oirilẹ-ede yii nilo adura lati koju ẹgbẹgun Boko Haram.