Teachers‘ new salary in Nigeria: Wike ní owó oṣù tuntun fáwọn olùkọ́ tí Buhari kéde yóò dá aáwọ̀ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nyesom Wike
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ja gudugbẹ ọrọ lulẹ lẹyin to sọ pe akanṣe owo oṣu fawọn olukọ ti ijọba apapọ kede rẹ laipẹ yii yoo da aawọ silẹ lẹka eto ẹkọ ni Naijiria.
Wike to sọrọ ọhun nipasẹ kọmiṣọnna eto iroyin ati ibaraẹnisọrọ, ṣalaye pe lotitọ ni o dara lati ṣeto owo oṣu tuntun fawọn olukọ.
Ṣugbọn o ni o ṣe pataki lati maa fi ọrọ oṣelu bọ ọrọ naa.
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
- Ìfẹ́hònúhàn 'End SARS' ń tẹ́síwájú láì jẹ́ pé Buhari ṣe.....
- Mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ mi- Baba ọmọ ti SARS pa
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Ènìyàn 17 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ mẹ́ta tó ṣẹlẹ̀ ní Osun, òpópónà Ibadan sí Eko àti Delta
Ko ṣai sọ pe o dara lati mu ọrọ awọn olukọ ni baada nitori ipa ribiribi ti wọn n ko lori idasoke awujọ.
Amọ, o sọ pe ijọba apapọ fi ẹtẹ silẹ, o n pa lapalapa nitori o kọ eti ikun si ọrọ eto ati maa pin owo tuntun fawọn ipinlẹ ṣugbọn o kede akanṣe owu oṣu tuntun fawọn olukọ.
Wike ni ikede akanṣe owo oṣu tuntun fawọn olukọ yo fikun ẹru to wa lori awọn ijọba ipinlẹ.
Ọjọ Karun osu Kẹwa ọdun 2020 yii tii ṣe ayajọ ọjọ awọn olukọ lagbaaye ni ijọba apapọ kede akanṣe owo oṣu tuntun fawọn olukọ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @UNICEF_Nigeria
Àkànṣe owó oṣù lá wa olùkọ́ ń fẹ́ yàtọ̀ sí tàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì - NUT
Ọjọ Karun osu Kẹwa ọdọọdun ni ayajọ ọjọ awọn olukọ lorilẹede Naijiria eyi to ko lọjọ Abamẹta.
Sugbọn ọjọ naa ko lọ lasan lai jẹ pe awọn olukọ beere ọkan o jọkan ohun ti wọn n poungbẹ lọwọ ijọba, pataki ibeere wọn si ni agbekalẹ akanse owo osu fun awọn osisẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Kí ló ṣe jẹ́ pé èmi ni yóò ní àrùn jẹjẹrẹ lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlá?"
- A gbẹ́sẹ̀ lé ilé kan tó jẹ́ ti Bukola Saraki, torí àpò ìjọba ló ti mú owó sanwó ilẹ̀ - Ilé aṣòfin
- Irọ́ ni Cameron pa mọ́ mi lórí ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ Chibok- Jonathan figbe ta
- Ìrọ̀rùn dé l'Ekiti! A óò bẹ̀rẹ̀ sí san 30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lóṣù yìí- Fayemi
- Kiki Osinbajo gbóṣùbà fún Seyi Awolowo, MC Oluomo tọrọ ìbò fún Mike ní BBNaija
Nigba to n gbẹnu awọn olukọ sọrọ, aarẹ apapọ fun ẹgbẹ awọn olukọ jakejado orilẹede Naijiria lasiko ayajọ ọjọ olukọ naa, Mohammed Nasir Idris salaye pe yoo dara ki akanse owo osu wa fawọn olukọ ki ijọba lee safihan bi awọn olukọ ti se pataki si taa ba wo ọrọ aje ti ko fara rọ yii.
"Igbagbọ wa ni pe akanse owo osu fawọn olukọ (TSS) yoo mu ki isẹ olukọ da yatọ, ti yoo si tun fun isẹ olukọ ni idamọ to dara, taa si to si ipo ẹyẹ lawujọ, a wa n rọ ijọba lati tete buwọlu ibeere yii."

Oríṣun àwòrán, @GovernorObaseki
Idris, lasiko to n sọrọ lori akori ayajọ ọjọ olukọ naa, ti wọn pe ni 'Ọdọ Olukọ ni ọjọ ọla fun isẹ olukọ', tun kesi ijọba apapọ lati tete san owo ida mẹtadinlọgbọn ati aabọ owo ajẹmọnu isẹ fawọn olukọ to wa lawọn ileekọ girama tijọba apapọ, nitori eyi lo ni yoo jẹ ki ori awọn olukọ naa wu lati sisẹ bo se yẹ.
Wayi o, agbẹjọro agba fun Naijiria Abubakar Malami, to soju fun aarẹ Buhari nibi eto ti wọn fi n sami ayajọ olukọ naa, kede pe ijọba apapọ yoo fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ lati pese eto koriya fawọn olukọ, paapa awọn to wa lagbegbe igberiko.

Oríṣun àwòrán, @UNICEF_Nigeria
Malami ni yatọ si pe eyi yoo mu kawọn ọdọ setan lati sisẹ olukọ, bakan naa tun ni ijọba yoo seto idanilẹkọ atigbadegba fun wọn.
















