Edo after election: Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá

Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin Edo

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ile Igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Edo ti yọ Abẹnugan Ile, Francis Okiye kuro ni ipo.

Iyọkuronipo rẹ ko ṣẹyin bi adari ọmọ ile to pọju lọ, Henry Okhurobo ṣe ni ki wọn yọ ọ lori ẹsun pe oun lo iwa agbara pẹlu wọn.

Awọn mẹsan an ninu awọn mẹwaa to wa nibi ijoko ile naa lo buwọlu lẹta iyọnipo rẹ.

Ba wo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ?

Oṣu Keje, Ọdun to kọja ni ija ti bẹrẹ laarin awọn ọmọ Ile, lẹyin ti awọn mẹsan an kan lalẹ Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Keje yan abẹnugan Ile laarin awọn mẹrinlelogun to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, labẹ aṣẹ gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki.

Awọn aṣofin mẹrinla to ku ko si ni ibi ti wọn ti gbe igbesẹ naa, ti wọn si tako igbesẹ naa ati ẹgbẹ oṣelu APC si kọ igbeṣẹ naa, wọn si kesi gomina Obaseki lati pa aṣẹ miran.

Amọ, Ileẹjọ Giga nipinlẹ Rivers tako igbẹsẹ ki gomina pa aṣẹ miran.

Igbiyanju lati ṣe ibura wọle fun awọn aṣofin tuntun naa lo fori sanpọn, nigba ti awọn kan le wọn kuro ni Ile Igbimọ Aṣofin, lẹyin ti wọn ni wọn n tun ayika ati Ile Igbimọ Aṣofin naa ṣe lọwọ.

Amọ, ẹgbẹ oṣelu APC ni gomina ipinlẹ Edo lo kọ awọn janduku si Ile igbimọ aṣofin nitori ko fẹ ki wọn yọ oun kuro ni ipo.

Bakan naa ni ileẹjọ miran paṣẹ ki Ile Igbimọ Aṣofin apapọ ma ṣe lo agbara lori Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Edo.

Àkọlé fídíò, Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún

Eleyii pẹlu ohun to mu ki ija ati ikunsinu to wa laarin gomina ipinlẹ Edo, Obaseki ati gomina ana nipinlẹ naa, Adams Oshiomolẹ to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC nigba naa.

Awọn kan sọ wi pe Gomina Obaseki to wa ni idi bi wọn ṣe le Obaseki kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC ni wọọdu rẹ, Oshiomole naa si ri daju pe Obaseki to jawe olubori ninu idije sipo gomina labẹle ni ẹgbẹ oṣelu APC, ti Pasito Osagie Ize-Iyamu si bori.

Nibayii ti gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti wọlẹ pada, awọn oniroyin bere ẹ lọwọ boya yoo gba ki awọn aṣofin mẹrinla ti ẹgbẹ oṣelu APC pada si Ile Igbimọ Asofin?

Amọ, Obaseki dahun wi pe oun ko laṣẹ lati burawọle fun awọn mẹrinla naa, lẹyin ti wọn kọ lati ṣe ayẹyẹ iburawọle.

Àkọlé fídíò, Ondo election 2020: Àwọn ara ìpínlẹ̀ Ondo ránṣẹ́ sí Akeredolu ohun ti wọ́n ń retí ní báyìí