Ondo election 2020: Àwọn ara ìpínlẹ̀ Ondo ránṣẹ́ sí Akeredolu ohun ti wọ́n ń retí ní báyìí

Àkọlé fídíò, Ondo election 2020: Àwọn ara ìpínlẹ̀ Ondo ránṣẹ́ sí Akeredolu ohun ti wọ́n ń retí ní báyìí

Inu wa ko dun ṣugbọn.... Alaga ẹgbẹ oṣelu SDP

Lẹyin ti ajọ INEC kede Rotimi Akeredolu pe oun lo wọle ibo lẹẹkeji ni ipinlẹ Ondo lọjọ Aiku ni awọn eeyan sọ ohun to wa ni ọkan koowa wọn.

Ogbẹni Oladele Olugbemi to jé alaga ẹgbẹ SDP ni Ondo salaye fun BBC pe ko si ohun ti ẹgbẹ naa le ṣe lẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ondo.

O ni: O dun wa pe wọn ti ta ibo wọn ni Ondo nitori pe igboro ko rẹrin.

Ogbeni Olalere Ola to jẹ aṣoju ADP sọ nipa bo ṣe pe ebi ati iṣẹ lo jẹ ki awọn eeyan ta ibo wọn laiwo ẹyin wo ni Ondo.

Ogbeni victor Olabintan to jẹ aṣoju ẹgbẹ APC to gbegba oroke ni tirẹ sọ pe inu gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC dun pupọ si abajade esi idibo naa.

Awọn ADP ni inu Olorun kod un si ipinlẹ Ondo bayii.

Awọn ara ilu naa ba BBC sọrọ, wọn ṣalaye ohun to wu wọn ati ohun ti wọn n reti lọdọ Akẹti to jẹ gomina tuntun to wọle bayii.