Coronavirus in Africa: Wo ìdí tí coronavirus kò fi ṣọṣẹ́ púpọ̀ jù nílẹ̀ Africa bí i tàwọn tó kù

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

BBC se ayẹwo idi marun un ti ajakalẹ̀ arun coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra lati ibẹrẹ ọdun 2020 yii ko fi rinlẹ̀ ju bayii lọ ni awọn orile-ede ile adulawọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn eeyan ni ẹru n ba lati igba ti ajakalẹ̀ arun COvid 19 ti bẹ́ silẹ̀ pe eto ilera ilẹ̀ Adulawọ ko dara t ni eyi to le mu ki ọsẹ́ Covid 19 lagbara ju

Awọn eniyan ilẹ̀ Afirika le ni bilionu kan ni eyi ti awọn to lugbadi ajakale arun Covid 19 nibẹ̀ ko ju miliọnu kan ati abọ gẹ́gẹ́ bii akọsilẹ̀ fasiti John Hopkins.

Iye nọmba yii kere si ti awọn ilẹ̀ nmiran bii Yuroopu, Asia, ati America nibi ti nọ́mba awọn miran si n pọ sii.

Titi di asiko yii, iye awọn ti Covid 19 pa nilẹ̀ Adulawọ jẹ́ bii egberun metadinlogoji, 37, 000 ni eyi to kere niwọn si egberun lona ogorun mẹ́fa din ogun, 580, 000 ni America

Bẹẹ eniyan ọgbọ̀n le ni igba ẹgbẹ̀run 230, 000 lo ti ba a rin ni Yuroopu ati ẹgbẹ̀run marun le ni igba ni Asia, 205, 000.

Àkọlé fídíò, Njẹ Chloroquine nipa kankan lati le koju Coronavirus

Awọn case-fatality ratio ti wọ́n pe ni CFR ni ilẹ Adulawọ ni iye awọn to ba iṣẹlẹ naa rin ni Afirika kere jọjọ si awọn ilẹ to ku ni agbaye.

Ọpọ iwadii si fihan pe ko ri bẹẹ pe ki awọn to maa ku ni ilẹ Adulawọ pọ ju nitori eto ilera ilẹ Adulawọ ti ko mọnyan lori to.

Iwadii Partnership for Evidence-based Response to Covid-19 (PERC), to ṣe atojọ ni aladani ati ti ijọba fihan pe ọṣẹ́ ti Covid 19 ṣe nilẹ Adulawọ kere niye pẹlu afiwe nọmba iye eeyan to wa nibẹ.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nitootọ lo jẹ pe iye awọn ti wọn n ṣe ayẹwo coronavirus fun kere niye.

Sugbọn ko si ohun to fidi ẹ mulẹ pe iye awọn ti ajakalẹ arun Covid 19 n pa pọ ju nitori pe iku Covid 19 ko ṣe e bo mọlẹ.

Dokita John Nkengasong, to n dari ajọ to n mojuto itankalẹ ajakalẹ arun Africa Centres for Disease Control and Prevention (Africa CDC) ni iku covid ko ṣe e gbe pamọ rara.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Ṣé ọtí leè dènà tàbí pa àrùn Coronavirus bi?

Ki lo fa a ti iye ọṣẹ́ ti ajakalẹ arun Covid 19 ṣe ni Africa kò ṣe pọ?

Lọjọ kẹrinla, osu keji, ọdun 2020 ni iṣẹlẹ akọkọ ṣẹlẹ ni Egypt ni eyi to bi ẹru ati ifoya kaakiri ilẹ Adulawọ.

Ni kete lẹyin ikede akọkọ yii ni awọn ijọba orilẹ-ede ilẹ Adulawọ gbe igbesẹ akin lati gbogun ti itankalẹ ajakalẹ arun Covid 19.

Kiakia ni awọn ijọba ilẹ Adulawọ gbe igbesẹ ilanilọyẹ lori ọna lati tako itankalẹ bii ọwọ fifọ nigba gbogbo, itakete sira ẹni lawujọ, ati wiwọ ibomu.

Koda, awọn orilẹ-ede bii Lesotho bẹrẹ igbesẹ laitii ni iṣẹlẹ coronavirus kankan.

Lesotho ti ilẹkun ile iwe lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta ọdun ti wọn si kede isede ọlọsẹ mẹta pẹlu awọn orilẹ-ede ila oorun Afirika miran.

Pẹlu eniyan to le ni miliọnu meji ṣugbọn ti wọn ri iṣẹlẹ Coronavirus 1, 700 pẹlu eniyan ogoji to ti gbẹmi mi.

Coronavirus

Idi keji tun ni pe iranlọwọ ati atilẹyin wa lati ọdọ awọn ara ilu:

Ninu iwadii kan nipa orilẹ-ede mejidinlogun ti ajọ PERC ṣe loṣu kẹjọ ọdun yii lo ṣafihan pe ida marundinlaadọrun ninu ọgọrun eniyan lo wọ ibomu lọsẹ naa.

Laarin oṣu kẹta si oṣu karun un ni awọn eeyan fi dẹkun itankalẹ naa diẹ pẹlu gbigbe igbesẹ to yẹ.

O ni didẹwọ isede ati awọn ofin yii laarin oṣu kẹfa si oṣu keje jẹ ki iye awọn to lugbadi Covid 19 pọ sii nilẹ Adulawọ.

Coronavirus

Ọpọlọpọ iṣẹ lo sọnu ti awọn okowo miran jo ina ajorẹyin lasiko isede to pọ.

Fun apẹrẹ lorilẹ-ede South Africa ni awọn eeyan miliọnu meji ati igba eeyan padanu iṣẹ wọn.

Ọpọ orilẹ-ede nilẹ Adulawọ di dandan ki wọn si ibi iṣẹ okowo pada lẹyin ti iye nọmba naa n pọ sii.

Ida mẹfa ninu mẹwaa awọn ti PERC ṣe fihan pe niṣe lo yẹ ki ijọba kọọkan ṣi okowo pada ki awọn eeyan si maa ba karakata lọ ṣugbọn ki wọn ṣi maa bọwọ fun ofin asiko isede naa

Nigba ti awọn miran fi ibẹru han lori jijade pada, ṣugbọn, awọn miran ni ebi kii wọnu ki ọrọ miran bii Covid 19 bo ṣe lagbara to naa tun wọ ọ.

coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idi kẹta tun ni ti iye eeyan to wa nilẹ̀ Adulawọ ti wọ́n ki i fi bẹẹ ko arugbo wọn sile itọju lọtọ:

Ọ̀pọ awọn arugbo nilẹ Adulawọ ni awọn ẹbi wọn maa n tọju wọn ninu ile wọn lai gbe wọn sile itọju arugbo.

Ni gbogbo agbaye ọjọ ori awọn to ku to pọ julọ jẹ lati ọgọrin ọdun soke.

Awọn to ni covid 19 ni Sub Sahara Africa jẹ awọn ti ọjọ ori wọn din ni ẹni ọgọta ọdun ti ida ọgọrin ninu ọgọrun ko si ki n fi ami coronavirus han.

Dokita Matshidiso Moeti to jẹ adari WHO nilẹ Adulawọ ni ilẹ Yuroopu, North america ati ilẹ Asia nibi ti awọn arugbo pọ si julọ.

Bakan naa nitori pe ọna irinajo lati ibi kan si ibi keji ni ọpọ agbegbe ilẹ Adulawọ ko rọr\uin, eyi ko jẹ ki awọn eeyan tun tan arun naa kalẹ pupó bii ti awọn orilẹ-ede ti idagbasoke wọn ti pọ.

coronavirus

Fifi ẹnu ootọ ọrọ yanju irọ to wa nibẹ

Ṣe ootọ ni pe oju ọjọ to dara ṣe iranlọwọ fun Afrika?

Iwadii kan lati fasiti Maryland ni orilẹ-ede America ṣafiwe odiwọn ooru ọjọ ati otutu lasiko ajakalẹ arun Covid 19.

Wọn wo bi arun naa ṣe kọkọ tankalẹ laarin aadọta ilu lagbaye ni eyi ti wọn ni o tete tankalẹ lawọn ibi to tutu ju ibi to gbona lọ.

Mohammad Sajadi to jẹ aṣaaju ikọ iwadii naa ni abajade naa fihan pe ibi tutu lo ti n tankale ju ibi to mu ooru lọ.

Iwadii naa tun fihan pe arun naa tankalẹ lasiko otutu ni orilẹ-ede South Africa pupọ ju igba ti ooru ti n bẹrẹ lọ nibẹ.

coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọna ajọṣepọ eto ilera to jẹ ti alagboole to dara pupọ:

Eyi jẹ idi karun un ti ajakalẹ arun Covid 19 ko fi ṣọṣẹ ju bi o ti yẹ lọ nilẹ Adulawọ.

Asiko ti ajakalé arun yii jade naa ni orilẹ-ede DR Congo si n ba ajakalẹ arun Ebola faa.

Sibẹ awọn orilẹ-ede alamuleti DR Congo n ṣayẹwo to yẹ lori eeyan to ni Ebola ati Covid 19.

Ọpọlọpọ orile-ede to jagun Ebola lo lo igbesẹ ti wọn fi bori Ebola lati fi koju ajakalẹ arun Coronavirus.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Naijiria to jẹ orilẹ-ede ilẹ alawọdudu ti ero pọ si julọ naa lo ọgbọn atẹyinwa wọn ti wọn fi bori arun polio nipa lilọ kaakiri abule lọ fun awọn ọmọ ni abẹrẹ ajẹsara.

Wọn lo ọna ilanilọyẹ yii lati ba awọn eeyan sọrọ lori ajakalẹ arun Covid 19 tuntun yii.

Dokita Rosemary Onyibe to ti n sisẹ pẹlu eto polio tẹlẹ sọrọ lori lilo ọna pinpin abẹrẹ ajẹsara polio lati fi wa awọn ti o ti lugbadi Covid 19 ati ṣiṣe abẹwo to yẹ.

Imọran ikéyin lori covid 19

Nitootọ ni ilẹ Afirika ko ni iku ati iṣẹlẹ Coronavirus yii bii tawọn orilẹ-ede agbaye miran ṣugbọn ko tii yẹ ki wọn sinmi.

Bẹẹ, eto ilera orilẹ-ede Adulawọ ko dabi ti awọn orilẹ-ede agbaye to ti goke agba.

Agbara ilẹ Adulawọ jẹ ti ajumọṣe gbogbo ẹbi ati ara ni eyi to yẹ ki wọn tun fi ṣe daadaa sii.

Dokita Moeti ni o ṣeeṣe ki arun naa tun gbẹnu soke sii ni ile Adulawọ ti wọn ko ba gbe awọn igbesẹ to yẹ.