Coronavirus: Ọkùnrin kan kú lẹ́yìn tí wọ́n lù ú nítorí ìbẹ̀rù coronavirus

Awọn eleto ilera

Ọkunrin kan ti wọn fi ẹsun kan pe o ni arun coronavirus ti dero ọrun lọsan gangan lẹyin ti awọn ọdọ tinu n bi dawọjọ lu u.

Ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye ni abule Kibundani ni agbegbe Kwale l'orilẹ-ede Kenya, ni nkan bi agogo mẹsan alẹ.

Iroyin sọ pe wọn fi ọkunrin ṣẹ sin ati ẹlẹya ki wọn o to lu u, pe awọn furasi pe o ni ajakalẹ arun coronvirus lara.

Ọkunrin naa, George Kotini Hezron n pada sile rẹ lọjọ buruku, eṣu gbomimu ọhun, lẹyin to ṣe faaji tan nile ọti. Ọna irinajo rẹ lo ti pade awọn ọdọ naa, to bẹrẹ si ni fi ṣe yẹyẹ.

Olori ọlọpaa ni agbegbe Msambweni, Nehemiah Bitok sọ pe "awọn ọdọ naa lo anfaani pe ọkunrin naa ti mu ọti yo, ti wsn si lu u bi ko ku.

Araalu kan lo fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa l'eti lẹyin.

Ọgbẹni Bitok sọ pe ọkunrin naa ku lasiko to n gba itọju nileewosan.

Bakan naa lo sọ fun BBC pe ọwọ ko ti i tẹ ẹnikẹni lori iṣẹlẹ naa, ati wi pe iwadii n lọ.

Eniyan meje ni ileeọẹ eto ilera Kenya ti kede pe o ni coronavirus l'orilẹ-ede naa.