Coronavirus: Àwíjàre ọlọ́pàá ni pé dókítà múra bíi onínàbì láago mẹ́wàá alẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Oniruuru ẹmi ni arun Coronavirus ti gba, boya lati ipasẹ kiko arun naa ni abi ni ọna miran.
Sugbọn eyi to se ni laanu ni awọn ẹmi to bọ sọwọ awọn agbofinro lasiko ti wọn n se isẹ wọn lati ri daju pe awọn eeyan tẹle ofin fidimọle.
Sugbọn eyi to se laanu ninu gbogbo rẹ ni ti obinrin alaboyun kan ati ọmọ inu re to dero ọrun lasiko to n rọbi lọwọ lọjọ to kẹyin osu kẹjọ ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìdí tí wọ́n ṣe lé Erica dànù kúrò nílé BBNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- Kí ló ṣe Ibrahim Chatta tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Ọlọ́pàá wú òkú obìrin tó ń múra ìgbéyàwó lọ́wọ́ tí 'gate-man' rẹ̀ ṣekúpa
- "A fẹ́ yọ ààrẹ ẹgbẹ́ Yorùbá YCE nípò torí àwọn ìwà tí kò bójúmu"
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Ẹ fura o, Boko Haram ti pàgọ́ sí Abuja, yóò ṣe ìkọlù láìpẹ́ - Iléèṣẹ́ Aṣọ́bodè lọgun
Idi ni pe dokita obinrin kan to yẹ ko sare lọ sile iwosan lati sisẹ abẹ fun alaboyun naa lasiko isede nitori Coronavirus, lo bọ sọwọ awọn ọlọpaa to da duro ladugbo Ikeja nilu Eko.
Gbogbo ẹbẹ dokita naa sawọn ọlọpaa ọhun pe oun fẹ sare lọ dahun ipe pajawiri to le la ẹmi lọ nile iwosan lo ja si pabo.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn papa fi dokita naa silẹ lẹyin wakati kan amọ ẹpa ko boro mọ nitori oku alaboyun ati ọmọ inu rẹ lo ba nile iwosan naa.
Gẹgẹ bi iwe akọroyin fun iwe iroyin Punch ti salaye isẹlẹ isẹlẹ naa, se ni dokita obinrin naa bu sẹkun nigba to de ile iwosan, to si gbọ nipa ohun to sẹlẹ si tiya tọmọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ sọ fun akọroyin naa pe isẹlẹ naa waye ni deede aago mẹwa kọja isẹju mẹẹdogun lalẹ.
O ni awijare awọn agbofinro naa ni pe dokita obinrin yii ko mura bii alakọwe, o si seese ko jẹ pe oninabi ni.
Ẹ wo ohun tí baba Adeboye sọ lórí ọ̀rọ̀ Coronavirus

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Baba Adeboye, gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe maa n pe iranṣẹ Ọlọrun naa ṣalaye ninu fidio to gbe jade pe ko si buburu kan ti yoo kan awọn to ba gbagbọ ninu Ọlọrun.
O ni 'Mo fẹ fi asiko yii fi daa yin loju pe, ko si arun Coronavirus kankan ti yoo de ọdọ yin; nitori pe ẹ n gbe ninu ibi ikọkọ Ọga ogo."
Eyi gan an lo n fa awuyewuye lori ayelujara lori bi awọn eeyan ṣe n sọrọ pe ohun ti iranṣẹ Ọlọrun yii sọ ninu fidio naa ko tọna.
Amọṣa ohun to wa ninu fidio yii nikan lawọn to n tako iranṣẹ Ọlọrun naa n wo, wọn ko wo ẹsẹ ọrọ rẹ to ti sọ wi pe, yatọ si pe Ọlọrun n ṣọ awọn tirẹ, gbogbo awọn eeyan lo gbọdọ tẹle ilana imọtoto to yanranti nitori imọtoto lo kangun si iwa mimọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ohun ti Pasito Adeboye n gbiyanju lati sọ ni wi pe yatọ si iwa mimọ, gbigbe igbe aye imọtoto ṣe pataki lati bori arun Coronavirus.
Amọṣa ọpọ eeyan lo foju fo amọran rẹ lori ṣiṣe imọtoto ara ẹni ati ayika ẹni, fido ọhun nikan wọn gbajumọ.
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Bí Fayemi bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀, àwọn oníbáwí rẹ̀ wà l'Ekiti-Peter Fatomilọla
- Coronavirus: Wo ohun tí o ní láti ṣe láti dáàbò bo ara rẹ
- Wọ́n gbé òkú ọgá iléẹ̀kọ́ àti òṣìṣẹ́ méjì míì tó kú nínú ìbúgbàmù lọ sílé ìgbókùsí ológun ojú omi l‘Eko

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Ninu amọran to tẹlẹ fidio naa ni baba Adeboye ti sọ pe "Ẹ maṣe gbagbe pe ara gbigbe labẹ ojiji Ọlọrun ni pe ki ẹ maa gbe igbe aye imọtoto."
Baba tẹsiwaju pe yatọ si jijẹ ọmọ Ọlọrun, o yẹ ki awọn eeyan maa ṣe awọn nnkan bi fifọ ọwọ ẹni pẹlu ọṣẹ ati omi, ati jijẹ ki ayika ẹni wa ni mimọ.
Pasitọ EA Adeboye jẹ ọkan pataki lara awọn iranṣẹ Ọlọrun to lokimi nilẹ Naijiria ti okiki rẹ si kan de oke okun.














