BBNaija 2020: Trikytee àti Ozo ní wọ́n fọ́wọ́ òsì júwe ile fún ni bbnaija lọ́sẹ̀ yìí

Trikytee àti Ozo ní wọ́n fọ́wọ́ òsì júwe ile fún ni bbnaija lọ́sẹ̀ yìí

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe ilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà, Laycon mórí ní wan kọ́kọ́ pè jáde sùgbọ́n lẹ́yìn o rẹyin Trikytee ni wọ́n júwe ilé fún.

Trikytee ni olukópa kẹrinla ti yóò kúrò nínú ilé BigBrother

Ebuka ni, ààyà wà fún ẹnikẹni tó bá fẹ́ dìbò fún ẹnikẹ́ni láti jáwe olúbori pẹ̀lú mílíọ̀nu márundìndinláàdọ́run náírà le bẹ̀rẹ̀ láti alẹ́ òní títí di ọjọ́ Eti tọ n bọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ti Trikytee kúrò nínú ilé, lo sàlàye pé, ìyalẹ́nu ló jẹ́ pé , òun di àsìkò yìí nínú ilé Big Brother nítori pé ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀ ni oun ti ma n múra sílẹ̀ láti lọ.

Bákan náà lo sàlàyé pé, kò tẹ̀wọ̀n tọ láti sọ pé òun máá n sábà tèlé ẹni to bá ni àgbára nínú ilé ni òun má n rìn mọ́.

Ní kété ti wọ́n kéde pé ki Ozo máa lọ ilé ni ó gbìyànjú láti f'ẹ́nuko Nengi lẹ́nu bi ikíni ìdágberé

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò ti Ebuka ṣe fún Ozo, ó ni ìṣesí Nengi àti àwọn ǹkan to ni òun fẹ́ dà láyé wà lára ǹkan tó fi ìfẹ́ rẹ̀ sí.

O ní òun ri àra òun bi omi sùgbọ́n ìna ni Nengi, eni ti àwọn si lé jọ gbé ìdílé ró ni

Nígbà ti Ebuka bèrè lọ́wọ́ Dorathy bóya ó ti ṣetán láti lọ ilé, o ni rárá nítori ko si ibi ti oun fẹ́ lọ bí òun bá kúrò nilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà.

Ó kú ènìyàn márun-ún ti yóò bá ètò náà de ìparí ní sáà BigBrother Naijia yìí.

Àwọn náà ni Vee,

Neo

Nengi

Laycon

Dorothy

Àwọn mẹ́ẹ̀dógun lo tí kó ẹrù wọ́n kúrò níle ẹlẹ́gbọ̀n àgbà láti ìgbà ti ètò náà ti bẹ̀rẹ̀ Lilo, Ka3na, Eric, Tochi, Kaisha, Praise, Wathoni, Tolanibaj, Bighto, Lucy, Prince Kiddwaya, Trickytee àti Ozo,wọ́n lé Erica lọ nírori o rú òfin Bigbrother.

Tani ẹ rò pé yóò lọ nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà BigBrotherNaijia lálẹ́ òní?

Ọ̀tọ̀ lórìn bi wọ́n ṣe yàn àwọn ti yóò kúrò nílé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà lónìí.

Bí ètò ilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà ṣe ń káṣẹ̀ nílẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, àrà ọ̀tọ̀ ni bí wan ṣe fẹ́ yàn àwọn ti yóò lọ kúrò nínu ilé lónìí.

Nínú àwọn méje to ku nínú ilé ni ẹlẹ́gbọ̀n àgbà Trikytee, Vee, Laycon, Neo, Dorathy Ozo ní pín si ẹgbẹ́ méjì láti yàn ènìyàn méjì nínú ẹgbẹ́ méjèèjì tí yóò lọ kúrò nínú ilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà.

Nígbà ti Nengi jẹ́ olórí ilé.

Ẹgbẹ́ aláwọ̀ dúdú àti ẹgbẹ́ aláwọ̀ fúnfun.

Ẹgbẹ́ aláwọ̀ Dudu ni a ti rí

Neo

Dorathy

Ozo

Nígbà ti ẹgbẹ́ aláwọ̀ funfun ni

Trikytee

Vee

Laycon

Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí yàn Laycon àti Trikyhtee bákan náà wọn mú Dorathy àti Ozo

Nínú àwọn mẹ́rin yìí a kò tíì kò tii mọ eniyan meji tí yóò lọlé lònìí

Tani ẹyi rò pé yóò lọ ilé nínú àwọn mẹ́rin yìí lálẹ́ òní

Nengi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Nengi

Nengi di olórí tuntun nílé ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà BBNaija

Nengi ti di olori ile ẹlẹgbọn ọn agba Big Brother Naijia ọjọ Aje ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an.

Igba keji ree ti Nengi yoo gba ipo olori laarin oṣu meji le diẹ.

Awọn mẹfa ni wọn jọ dupo olori ile, TrikyTee nikan ni ko dije nitori oun ni o wa nipo olori ki Nengi to jawe olubori.

Yatọ si awọn olori to ti jẹ tẹlẹ, Nengi ko ni ni igbakeji nile.

Pẹlu ipo olori ti Nengi wa bayii, o ti lanfaani lati wa nile ẹlẹgbọn ọn agba di ọsẹ ti eto naa yoo kasẹ nilẹ.

Prince àti Kiddwaya ní ọpọ́n ilé sún kàn nílé ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà BBNaija!

Prince ati Kiddwaya ni olugbe ile ẹlẹgbọn ti wọn ni ko ma kẹru wọn lọ sile lọsẹ yi.

Ninu awọn mẹrin ti orukọ wọn lewaju pe wọn le lọ sile, awọn ni iye ibo ti wọn ri kere ju lọ.

Ni bayi, Prince ati Kiddwaya ni olukopa inu idije Big Brother Naijia ẹlẹẹkejila ati ikẹtala ti wọn yoo ni ko maa lọ sile.

Awọn to ti ṣaaju rẹ lọ ile ni Lilo, Ka3na, Eric, Tochi, Kaisha, Prince, Wathoni, Tolanibaj, Bight O ati Lucy.

Bakan naa ni Erica to wa lara awọn olukopa ogun to bawọn bẹrẹ idije naa ti dero ile lẹyin ti wọn le kuro lọjọ Kẹfa oṣu Kẹsan, 2020.

Prince and Kiddwaya

Oríṣun àwòrán, @BBNaija/Twitter

Òní lòní ńjẹ́ nílé ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà BBNaija fún Dorathy, Prince, Kiddwaya, Ozo! Tani yóò lọ ilé?

Ọkan ninu awọn mẹsan an to ku ninu Ile Ẹgbọn Agba, Big Brother Naija n lọ sile loni gẹgẹ bi awọn oluworan ba ṣe dibo fun wọn si.

Ninu awọn mẹsan an to ku naa, awọn mẹrin ti wọn dibo pe wọn le ja kuro ninu BBNaija ni Dorathy Prince, Kiddwaya ati Ozo.

Awọn akopa

Oríṣun àwòrán, @goji1986

Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn mẹsan an to wa ninu ile naa ni anfaani lati fi orukọ ẹni meji silẹ ti wọn fẹ ko maa lọ sile.

Esi idibo naa fihan pe Prince lo ni ibo mẹfa, Dorothy tẹle pẹlu ibo mẹrin, Kiddwaya pẹlu ibo mẹta, Ozo ati Neo pẹlu ibo meji, nigba ti Nengi ati Vee ni ibo kọọkan.

Amọ, awọn oluworan ni o ṣeeṣe ki Prince jẹ ẹni ti yoo lọ sile, amọ Dorathy ni awọn eniyan wo wi pe ko lee lọ ninu awọn mẹrin naa.

Wo idi ti wọn fi fọwọ osi juwe ile fun Erica

Erica and Kiddwaya

Oríṣun àwòrán, @BBNaija Twitter

Wọn ti fi ọwọ osi juwe ile fun Erica, wọn si ti ni ko kuro ninu ile ẹlẹgbọn-ọn agba Big Brother Naija to n lọ lọwọ.

Ati alẹ ọjọ Abamẹta lo ti dabi pe nnkan ko ni ṣenu ire fun Erica lẹyin iwa to wu ninu ile naa, eyii to jẹ igba kẹta rẹ.

Iwa naa si ti mu ki ọpọ awọn ololufẹ rẹ maa bu ẹnu atẹ lu ṣaaju ki wọn to fi ọwọ osiu juwe ile fun un.

Ṣaaju ni ija kan ti kọkọ waye larin Erica ati Laycon, nibi ti Erica ti sọ awọn ọrọ kobakungbe kan.

Erica wọjọgbọn lẹyin ti Biggie ṣafihan fọrọn rogbodiyan ọhun fun un, to si tun sọ pe o ba ohun ini oun jẹ ni bo ṣe da omi sori ibusun olori ile naa, eyii to ni ko ṣetẹwọgba.

Biggie tun fẹsun kan Erica pe o ru ofin miran lẹyin to kọ lati gba igbakeji olori ile naa, Prince, laaye lati sun si ibi to yẹ ki olori ile ọhun sun si.

Biggie pari ọrọ rẹ pe awọn iwa to wu lodi si ofin to so ile ẹlẹgbọn agba naa ro.

Lẹyin na lo ki Neo nilọ lori iṣẹlẹ naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣẹyin?

Tolanibaj, Wathoni àti Brighto dé òpin ìrìnàjò ní ilé ẹlẹ́gbọ́n àgbà BBNaija

Tolanibaj, Brighto, ati Wathoni

Oríṣun àwòrán, BBNaija/twitter

Tolanibaj, Wathoni ati Brighto ni wọn le kuro nile Big Brother Naija l'ọsẹ yii.

Awọn mẹtẹẹta ni ẹnikeje, ikẹjọ ati ẹni ksan-an ti wọn le kuro lori eto ori tẹlifisan ọhun.

Tolanibaj, TrickTee, Kiddwaya, Prince, Erica, Lucy, Leo, Wathoni, Dorathy, Vee ati Laycon ni awọn ololufẹ eto naa fi orukọ wọn silẹ pe ko kuro nile ẹlẹgbọn agba.

Ṣugbọn, ibo awọn mẹtẹẹta lo kere julọ.

Wathoni

Oríṣun àwòrán, Twitter

Wo nkan to yẹ ki o mọ nipa wọn

Wathoni

Florence Wathoni Anyansi jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, o si jẹ oniṣẹ adani ni ẹka oge ṣiṣe.

Bakan naa lo tun ma n tẹ akọsilẹ jade lori ayelujara, nipa jijẹ òbí.

Tolanibaj

Oríṣun àwòrán, Twitter

Tolanibaj

Tolani Shobajo jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn. Ọmọ ipinlẹ Eko ni, o si n ṣiṣẹ agbohunsafẹfẹ.

Brighto

Oríṣun àwòrán, Twitter

Brighto

Ezekiel Bright 'Brighto' Osemudiame naa jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn. Ipinlẹ Edo lo ti wa. O si jẹ awakọ ọkọ oju omi.

Ọsẹ to kọja ni ibanuje sọri agba Praise kodo, wọn ni ko kẹru rẹ kuro ninu ile Big Brother.

Olukopa Big BBNaija

Oríṣun àwòrán, BIGBROTHER NAIJA/AFRICA MAGIC

Ṣugbọn Ikede yi to jẹ eyi to maa n waye lọsọọsẹ lẹyin tawọn olukopa ninu ere ile ẹlẹgbọn ba dibo tan kọ lawọn eeyan n ran lẹnu loju opo Twitter.

Ọrọ ti Ebuka atọkun eto sọ nipa Laycon ati Erica ati bi o ti ṣe doju ọrọ kọ Vee.

Ohun taa le sọni pe o kere tan ara ile mẹta lo dibo yan Praise pe oun ni ko maa lọ ile.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

Ṣaaju, ninu eeyan mẹẹdogun, Trichytee, Wathoni, Praise ati Vee ni ara ile mẹrin ti ibo wọn kere ju lati ita lọsẹ yii.

Ẹwẹ, Tolanibaj, Nengi ati Brighto lo sọ fun Big Brother pe Praise lawọn fẹ ri akẹyinsi rẹ ko maa lọ ile.

Loju opo Twitter niṣe lawọn eeyan kan n gboṣuba kare fun Vee bo ti ṣe da Ebuka lohun tawọn miran si n sọ pe ki awọn eeyan sọra fun Ebuka.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Praise ni olukopa ẹlẹẹkefa ti yoo kogba lọle kuro lori eto BBNaija alagbelewo to n lọ lọwọ.

Aworan awọn olukopa ninu eto ile ẹlẹgbọn

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA

Wọn ti foju ọna ile han Kaisha nibi eto agbelewo ẹlẹgbọn agba Big Brother Naija to n lọ lọwọ.

Wọn yọ Kaisha ati lẹyin ti ibo ti awọn ololufẹ eto agbelewo naa to dibo di fun oun atawọ̀n mẹ̀ta miran ko gbewọn to tawọn ẹlẹgbẹ wọn yoku.

Awọn olukopa mẹrin lorukọ wọn wa lori iwe ile ya fun ọsẹ kẹrin.

Awọn naa niwọnyii:

1.Trikytee

2.Kaisha

3.Wathoni

4.Neo

Amọṣa lẹyin eto alalẹ ọjọ Aiku nibi ti wọn ti maa n kede ẹni ti ile ya fun ni olugbalejo eto naa, Ebuka Obi-Uchendukede orukọ Kaisha gẹgẹ bi awọn olukopa ti awọn to n wo eto naa dipbo fun pe ki wọn maa gba ile wọn lọ.

Kaisha yoo maa tẹle, Tochi ati Eric ti wọn yọ bii jiga kuro ni ile naa ni opin ọsẹ kẹta rẹ lọjọ Aiku to kọja ninu awọn mẹjọ torukọ wọn wa ninu iwe ile ya fun ọsẹ naa.

Aworan Praise

Oríṣun àwòrán, BBNAIJA

Ki ni Kaisha sọ lẹyin to kuro ni ile ẹlẹgbọn agba?

Ninu ọrọ rẹ to sọ lẹyin ti wọn yọọ jade, Kaisha ni ko ya oun lẹnu pe awọn ẹgbẹ ohun dibo yọ oun jade nitoripe oun mọ ninu iwa ati iṣe wọn si oun pe wọn ko nifẹ oun rara.

Nigba ti wọn bii pe ki lo wa laarin oun ati Neo, Kaisha ni oun nifẹ Neo lootọ ni ibẹrẹ.

O ni ni bayi ti oun ti ṣetan ni ile ẹlẹbọn agba BBNaija bayii, oun n lọ gbaju mọ ileeṣẹ itọju ara ti oun da silẹ ni ati pe oun yoo tun mojuto eto ẹkọ ohun.

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Biggie bu omi ikilọ wọn Nengi ati Kaisha lara fun ija ti wọn ja ninu ile ẹlẹgbọn agba

Saaju ni ẹlẹgbọn agba funrarẹ ti bu omi ikilọ wọn Nengi ati Kaisha larafun wahala to bẹ silẹ laarin lowurọ ọjọ Abamẹta.

O ni irufẹ iwa bẹẹ tako abala kini ofin kejidinlogun to de ihuwasi ninu ile eto ẹlẹgbọn agba BBNaija.

Bakan naa ni ẹlẹgbọn agba ṣalaye pe ikils naa kan gbogbo awọn olukopa nitori ofin igbele naa ko faye gba ija tabi iwa ipa yoowu.

O jẹ ko di mims fun gbogbo wọn pe aparo kan ko ga ju ọkan lọ laarin wọn nitori naa ko si eyi to ju eyi lọ ninu gbogbo wọn.

Big Brother Naija season 5 eviction: Eric àti Tochi ti ilé pe lálẹ́ oni

Eric ati Tochi ni wọ́n lé kúrò nílé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà BBNaija lọ́sẹ̀ yìí

Láti ìgbà ti ilẹ̀ ti mọ́ lówùrọ òni ni àwọn ọmọ Naijiria tí n fójú sọ́na wípe tani- ẹgban àgbà yóò lé lọ sílé.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló sì ti ń sọ ẹni ti wan ni lọ́kan pé yóò lọlé, sùgbọ́n bí o ṣe bá àwọn lan lójiji pé Eric àti Tochi ló lọ sílé, àwọn míràn ni kò ya àwọn lẹ́nu pé èyí ṣẹlẹ̀.

Ní kété ti Eric àti Tochi jáde ni wọ́n ti n dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Naijria pé wọ́n kú àdúrótì lásìkò ti wọ́n wà nílé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà.

Tí ẹ ò bá gbàgbé, Lilo to jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin Eric ni wọ́n lé kúro nílé ẹlẹ́gbọ̀n-ọ̀n àgbà lọ́sẹ̀ tó kọja.

Wọ́n sọ èyí di mímọ̀ lójú òpó Twitter wọ́n.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ní báyìí o ti ku àwọn akópa mẹ́rìndílógún nínú ilé ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà.

  • Victoria Adeyele AKA Vee
  • Timmy Sinclair AKA Trikytee
  • Terseer Kiddwaya
  • Praise Nelson
  • Florence Wathoni Anyansi
  • Tochukwu Okechukwu AKA Tochi
  • Kate Jones AKA Ka3na
  • Eric Akhigbe
  • Ngozi Nlewedim AKA Erica
  • Ezekiel Bright Osemudiame AKA Brighto
  • Aisha Umaru AKA Kaisha
  • Emuobonuvie Akpofure AKA Neo
  • Tolani Shobajo AKA Tolanibaj
  • Olamilekan Agbeleshe AKA Laycon
  • Rebecca Hampson AKA Nengi
  • Lucy

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọ́n, wọ́n ti sọ bí ǹkan yóò ṣe ri láàrin Lilo àti Eric nígbà ti wọ́n bá fi ojú kan ara wọ́n.

Díẹ̀ lára àwọn ǹkan ti wọ́n ń sọ lójú òpó Twitter rèé

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Big Brother Naija season 5 eviction: Nengi, Kaisha, Laycon, Praise àbí ta ni ilé ń pè?

Aworan awọn oludije ti wọn le da pada silẹ lori eto BB Naija

Oríṣun àwòrán, BBNaija/Twitter

Loni ọjọ Aiku, ọjọ kẹsan an, oṣu kẹjọ yii ni ibeere nla ti gba ọkan awọn ololufẹ eto Big Brother Naija season five yii.

Lẹyin ti Ka3na ati Lilo to bẹrẹ ikopa pẹlu awọn to ku ti dero ile onikaluku ni ọkaa awọn eeyan naa ti gbe soke.

Ojọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2020 ni awọn eeyan yii wọle sile ẹlẹgbọn ọn agba ni eyi to fihan pe irinajo wọn ṣi ku aadọrin ọjọ nibẹ sii.

Ka3na ati Lilo

Oríṣun àwòrán, Others

Ka3na àti Lilo ló kọ́kọ́ dágbére fún ètò Big Brother Naija 2020

Ka3na àti Lilo ló kọ́kọ́ dágbére fún ètò Big Brother Naija 2020

Lilo ati Ka3na ni eeyan meji akọkọ ti wọn le kuro ninu eto Big Brother Naija season 5 lockdown, lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti lo.

Orukọ awọn mejeeji, pẹlu Erica ati Praise ni awọn olulufẹ eto naa fi silẹ pe ko pada sile, lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti wa ni ile naa.

Ẹnu ti kun Ka3na lopin ọsẹ to kọja, lẹyin ti iroyin jade pe oun ati Praise jọ ni ibalopọ.

Ninu fidio kan lo ti han pe awọn mejeeji jọ n fi ara gbo ara lori ibusun, ti wọn si yi aṣọ bori.

Ọkọọkan lọmọ ọwọ maa n yọ, lo difa fun bi awọn oludije mejeeji ṣe dagbere fun ile ẹlẹgbọn loni tii ṣe ọjọ keji, oṣu Kẹjọ.

Bayii si ni esi ibo naa ṣe lọ

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Lọṣe yii, mejidinlogun ninu awọn eeyan ogun to n kopa ninu eto agbelewo yi ni wọn kọkọ forukọ wọn sita, ti awọn ara ile si dibo lati yọ awọn ti yoo palẹmọ ẹru lọ sile.

Ẹlẹgbọn agba funra rẹ, Biggie lo mu ayipada yi ba ofin idije naa.

Awọn ọmọ inu ile mẹrindinlogun ni orukọ wọn wa ni bebe lati ko kuro ninu ile:

  • Ozoemena Chukwu AKA Ozo
  • Victoria Adeyele AKA Vee
  • Boluwatife Aderogba AKA Lilo
  • Timmy Sinclair AKA Trikytee
  • Terseer Kiddwaya
  • Dorathy Bachor
  • Praise Nelson
  • Florence Wathoni Anyansi
  • Tochukwu Okechukwu AKA Tochi
  • Kate Jones AKA Ka3na
  • Eric Akhigbe
  • Ngozi Nlewedim AKA Erica
  • Ezekiel Bright Osemudiame AKA Brighto
  • Aisha Umaru AKA Kaisha
  • Emuobonuvie Akpofure AKA Neo
  • Tolani Shobajo AKA Tolanibaj
  • Olamilekan Agbeleshe AKA Laycon
  • Rebecca Hampson AKA Nengi
  • Lucy
Esi ibo ti awọn ololufẹ eto Big Brother Naija Laockdown di lati mọ ẹni ti yoo kọkọ kuro nibi eto naa.

Oríṣun àwòrán, @bbnaija/twitter

Àkọlé àwòrán, Esi ibo ti awọn ololufẹ eto Big Brother Naija Laockdown di lati mọ ẹni ti yoo kọkọ kuro nibi eto naa.

Wọn ti pari idibo lori awọn olugbe ile ẹlẹgbọn agba ti wọn le dibo lati yọ ninu abala idije naa ti a mọ si Big Brother Naija lockdown Season 5.

Olori ile Lucy ati igbakeji rẹ Prince ni wọn ni 'imuniti' tori naa wọn ko ni si lara awọn ti wọn yoo dibọ lati ran lọ sile.

Ababọ esi idbo yi ni yoo tọka awọn oludije ti yoo kẹru kuro ninu ile ẹlẹgbọn agba.

Oludije ti ibo rẹ ba kere ju lọ ni wọn yoo fọwọ osi juwe ile fun

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Bawo ni idibo ijuwe ile fawọn oludije yoo ṣe lọ ni ti ọdun yii?

Ebuka Obi- Uchendu

Oríṣun àwòrán, BBNaija/Twitter

Àkọlé àwòrán, Ebuka Obi-Uchendu ni atọkun eto naa

Ni gbogbo ọjọ Aiku lawọn oludije yoo kopa ninu idibo iyọnikuro ninu ile ẹlẹgbọn.

Ọkọọkan ninu awọn oludije yoo lanfaani lati yan awọn akẹgbẹ wọn mẹrin ti o ni ibo to kere julọ ninu iyara ifọrọwanilẹnuwo,'Diary Room'.

Oludije tawọn akẹgbẹ rẹ ba di ibo to pọju lọ fun ni yoo kẹru rẹ kuro lọsẹ naa.

Igba akọkọ ree ti awọn alakoso ere ile ẹlẹgbọn yoo gbe iru ofin yi kalẹ lati yọ awọn oludije kuro ninu ile ọhun.