Policeman smoking shisha: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí fídíò ọkùnrin kan tó ń mu "shisha"

Ọlọpaa to n fa shisha

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti bẹrẹ iwadii lori fọnran kan to lu ori ayelujara pa ninu eyi ti ọkunrin to wọn aṣọ ọlọpaa ti mu ''shisha.''

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Uba fi sita lọjọ Aiku, ileeṣẹ ọlọpaa awọn yoo ṣe agbeyẹwo fidio naa boya ayederu fidio ni.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa to fi si oju opo Facebook rẹ pe awọn yoo tun ṣe iwadii ọhun to wa ninu fọnran naa boya ọlọpaa ni ni tootọọ tabi ọdaran to kan wọ aṣọ ọlọpaa lasan.

''Ṣugbọn nigba ti iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ, o ṣe pataki lati jẹki awọn araalu mọ pe ohun ti ọkunrin to wa ninu fidio naa n ṣe lodi si ilana ati ofin to de awọn ọlọpaa orilẹede Naijiria,'' Ọgbẹni Uba lo sọ bẹẹ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

O wa rọ awọn araalu ti o ba mọ ohun kan tabi omiiran nipa fidio ọhun lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa.

O ni ẹnikẹni to ba ni ohun kan lati fi to ọlọpaa leti le fi ranṣẹ si adirẹsi yii- [email protected], tabi ki wọn kan si oju opo ileeṣẹ ọlọpaa lori ayelujara.

Lati ọjọ Abamẹta lawọn eeyan ti n sọrọ lori fọnran ọkunrin naa to n fi shishan ṣagbeji ara nibi to joko si.