Satchet Alcohol ban: Ìjọba àpapọ̀ yóò fòfin de títà àti rírà ọtí inú ọ̀rá bíi 'pẹlẹbẹ', 'pàrágà'

Awọn ọti inu ọra kan

Oríṣun àwòrán, others

Paraga, kainkain, fona gau ati omiran wo lẹyin tun mọ?

Gbogbo awọn ọti inu ọra ati inu igo wọnyii ni ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati fi ofin de e laipẹ, iyẹn bi ọrọ oludari agba ajọ to n gbogun ti ilokulo ohun jijẹ ati ogun, lorilẹede Naijiria, NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisọla Adeyẹye ṣe sọ.

Ajọ NAFDAC ni ijọba apapọ fẹ gbe igbesẹ yii nitori ipa ti mimu ọti lọna ti ko tọ n mu ba ilera ilu pẹlu igbayegbadun araalu.

O ni bi awọn eeyan ṣe n lanfani lati mu ọti wọnyii nigbakugba to ba wu wọn ninu ọra pelebe pelebe ati igo kekeke n ṣe ọpọ akoba fun awujọ paapaa julọ bi iwadii ti ṣe fihan pe awọn eroja yii lo fihan pe ohun lo n ṣokunfa bi awọn eeyan ṣe n mu ọti bi ẹni n mu omi lawujọ.

O ni ijọba ti kọkọ fofin silẹ fun awọn to n pọn ọti inu ọra pelebe ati igo kekeke ni ibẹrẹ ọdun 2020 pe ki wọn din iwọn ti wọn n ṣe jade ku pẹlu ida aadọta ninu ọgọrun, (50%) gẹgẹ bi igbesẹ akọkọ lati dẹkun awọn ọti inu ọra naa.

Ajọ ilera agbaye, WHO ti gbe e sita ninu iwadii kan pe eeyan miliọnu mẹta lo n ku lọdun nitori ọti mimu.