Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí ajínigbé tó ń sọṣẹ́ lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, NSCDC
Ajọ abo ara-ẹni labo ilu, NSCDC ẹka ipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ọba mu awọn ajinigbe mẹrin ati agbodegba kan ti wọn n se ọsẹ l'agbegbe ijọba ibilẹ Ọwọ si Ọsẹ.
Iroyin sọ pe agbegbe yi jẹ okan lara awọn agbegbe ti awọn onisẹ laabi yi ti n sọsẹ julọ nipinlẹ Ondo ti wọn si ti gba ogunlọgọ milionu naira lọwọ awọn ara ilu ti ọpọlọpọ ẹmi si ti sọnu bakan naa.
Lasiko to n foju awọn afurasi naa han ni Ọjọru Ọsẹ yi, Ọgagba ajọ NSCDC, Ọgbẹni Oluyẹmi Ibiloye sọ pe wọn mu ọkàn lara awọn afurasi naa ati agbodegba rẹ ni Eti-Ọsẹ nijọba ibilẹ Ọwọ, nipinlẹ Ondo.
O ni ọwọ palaba awọn mẹta to ku segi ninu igbo Ọba ti o wa ni Ipele nijọba ibilẹ Ọwọ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ṣe aseyọri leyin isẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn ṣe ti awọn ikọ ajọ naa si bọ soju isẹ lati fi panpẹ ọba mu awọn ajinigbe naa.
Ọgbẹni Ibiloye sọ pe, ọkan lara awọn ajinigbe naa wọya ija pẹlu awọn ikọ naa bi o se kọ oju ibọn si wọn ki wọn to kapa rẹ.
O ni agbodegba ti wọn mu naa tun n gbin igbo lagbegbe Eti-Ọsẹ.
Ọgagba NSCDC ni eniyan mẹta ti awọn ajinigbe yi ti gba owo lọwọ wọn ti jade sita ti wọn si da wọn mọ gẹgẹ bi awọn ti o gba owo itusilẹ lọwọ wọn.
Ọgagba naa sọ pe okan ninu awọn afurasi naa to lọwọ ninu ijinigbe to si n gbin igbo ni wọn yio fa a le ajọ to n gbogun ti gbigbe ati ilo oogun oloro lọwọ lati gbe igbesẹ ti o tọ.
Awọn ti ọwọ tẹ naa ni, Dairu Abdullahi ẹni ọdún marundinlọgbọn, Uyobon Jim ẹni ọgbọn ọdun, Isiaku Jubril ẹni ọdún mẹtadinlogooji, Nura Idris ẹni ọgbọn ọdun ati Muhammed Sulieman to jẹ ẹni aadọta ọdún.
















