Ẹ̀yin ìyàwó, ẹ máa dákẹ́ fáwọn ọkọ yín tí ìjà bá ṣẹlẹ̀, Mínísítà rọ àwọn obìnrin

Aworan Uju Kennedy-Ohaneye

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Women Affairs/X

Minisita ọrọ awọn obinrin, Uju Kennedy-Ohaneye ti rọ awọn aya lati maa dakẹ fawọn ọkọ ti ariyanjiyan ba ṣẹlẹ ninu ile.

Kennedy-Ohaneye sọrọ yii nibi apero awọn kọmiṣọna ọrọ obinrin ni Naijiria to waye ni Ọjọru niluu Abuja.

Minisita ni didakẹ fawọn okunrin lasiko ija yoo dẹkun lilu ara ẹni ati iku ojiji to le tibẹ wa.

Minisita naa ni "mo n bẹ awọn obinrin lati ma wa wahala nilẹ wọn.

Ẹ jẹ ki a maa lepa alaafia ni ile wa, tori ti alaafia ba wa ninu ile, obinrin lo ni ipa to pọju lati ko nibẹ.

Ẹ gbẹnu yin dakẹ! Fifun ọkunrin lesi ko da nkankan ju ki o yọri si iparun tabi iku lọ.

Koda, o tun le yọri si ki awọn ọmọ di idakuda lawujọ.

Gbigbe ẹnu dakẹ o tumọ si pe omugọ ni yin, bi ko ṣe ọlọgbọn."

Arabinrin Kennedy-Ohaneye ni "iwọ ṣa gbe'nu dakẹ nigba ti ọkunrin ba n pariwo ti o n sọ oriṣiiriṣii.

Wa a ri pe yoo pada wa bẹ ọ laipẹ, ti o ba jẹ ọkunrin to dara.

Ti ki i ba ṣe ọkunrin to dara, iwọ ṣa fi i silẹ.

Nitori pe ni ọpọ igba ti a ba sọrọ tabi fesi pada, o maa n ko iya jẹ awa obinrin ti ọpọ si maa n farapa.

Ọkunrin yii kan naa to ti lu ẹ naa lo maa pada wa bẹ ọ.

Ki lo wa fẹ ṣe fun un?

Ṣe o maa pa a ni?

Nitori naa, o ṣe pataki lati kiye sara."

Minisita ọrọ awọn obinrin ko ṣai kepe ijọba lati buwọlu ofin ti yoo ṣe agbekalẹ ile ẹjọ alagbeka ti yoo maa ri awọn ẹsun to nii ṣe laarin ọkunrin si obinrin.

O ṣèlérí lati ṣiwaju iwọde ifẹhonuhan lọ si ọfiisi minisita eto idajọ pe ki ijọba buwọlu ofin naa.