Èèyàn 11mílíọ̀nù tí kò tíì so NIN wọn pọ̀ mọ́ nọ́mbà fóònù yóò já kúrò lórí ìlà ìpè lónìí

Aworan obinrin

Oríṣun àwòrán, Other

Eeyan to le ni mílíọ̀nù mọ́kànlá ti wọn ko tii so nomba kaadi NIN wọn pọ mọ nọmba foonu wọn ni yoo ja kuro lori ila pipe ara ẹni pẹlu foonu lonii.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ to fìdí ọrọ yii mulẹ sọ pe eyi jẹ aṣẹ ti ajọ NCC to n ri si ọrọ awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ pa fun awọn.

Igbakeji ọgagba ajọ NCC, Ọmọwe Aminu Maida, tun fidi rẹ mulẹ fáwọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ pe ana Ọjọru tii ṣe ọjọ kejidinlogbon oṣu Keji ni ọjọ t'awọn onibara wọn ni lati so nọmba NIN wọn mọ ti foonu wọn.

Ọmọwe Maida ni o ṣe pataki fawọn araalu lati so nọmba NIN pọ mọ nọmba foonu papaa julọ tori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Igbesẹ yii ko fi ti aṣẹ ti ile ẹjọ giga to wa ni ilu Eko pa wi pe ki awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ ma tii ja opo awọn ti ko tii so NIN wọn pọ mọ nọmba foonu ṣe.

Adajọ Ambrose Lewis-Allagoa paṣẹ yii lẹyin ti amofin, Olukoya Ogungbeje gbe ijọba apapọ, agbẹjọro agba ni Naijiria, ileeṣẹ MTN, ajọ NCC ati Airtel lọ ile ẹjọ pe ki ile ẹjọ fofin fe igbesẹ naa titi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo fi dajọ lori ọrọ ọhun.

Amọ, ajọ NCC at'awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ ko tii pe ẹjọ kotemilorun lori idajọ ile ẹjọ giga naa.

Ọdun 2020 ni ijọba apapọ ṣe agbekalẹ eto naa pe ki araalu so nọmba NIN pọ mọ ti foonu wọn lati ṣe iranwọ fawọn ẹṣọ eleto abo ti wọn ba fẹ mu ọdaran.

Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti kọminu lori bi awọn agbofinro ko tii maa lo anfaani siso nọmba foonu pọ mọ NIN pẹlu b'awọn ajinigbe ṣe n fi foonu beere owo itusile lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe.

Ni báyìí, mílíọ̀nù 224 eeyan lo ni nọmba foonu ni Naijiria gẹgẹ bi ajọ NCC ṣe sọ.

Agbẹnusọ ajọ NIMC to n ri si kaadi idanimọ NIN, Kayode Adegoke ṣalaye pe mílíọ̀nù 104 ninu wọn lo tii forukọ silẹ fún NIN.