Ààrẹ Tinubu yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ ojú òpó reluwé tuntun ní ìpínlẹ̀ Èkó

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Ipinlẹ Eko yoo gbalejo aarẹ orileede Naijiria Bola Ahmed Tinubu ti yoo ṣe ifilọlẹ oju opo reluwee tuntun mii.
LỌjọbọ yi ni aarẹ yoo balẹ si ipinlẹ to ti fi ọpọ ọdun jẹ Gomina lati wa sefilọlẹ reluwe to lọwọ ninu ìpìlẹ rẹ.
Kọmisana eto iroyin sí Gomina ipinlẹ Eko,Gbenga Omotosho salaye pe abala kini akanṣe eto reluwee yi lati Agbado n'ipinlẹ Ogun yoo k'ero titi de Oyingbo laarin gbungbun Eko.
O salaye pe ti reluwe yi ba bẹrẹ iṣẹ lẹkunrẹrẹ igba mẹtadinlọgoji ni yoo fi ma gbe ero ti o si le ko to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta eeyan lojumọ.
Ifilọlẹ yí yoo mu ki iye reluwe aarin ilu ti ijọba ipinlẹ Eko pe meji.
Akọkọ reluwe ijọba taa mọ si Blue Line n gbero lati Marina de Mile 2.
Ibudo iduro ja ero mẹjọ ni oju opo Red Line yi ni : Agbado, Iju, Agege, Ikeja, Oshodi, Mushin, Yaba ati Oyingbo.
Ṣaaju ni Aarẹ Tinubu ti sabẹwo sí ipinlẹ Ondo lori irinajo ọlọjọ meji to ṣe si awọn ipinlẹ iwọ oorun Guusu Naijiria.
Nibi abẹwo naa o kan si awọn olori ẹgbẹ itẹsiwaju Yorùbá , Afenifere to si tun kan si idile Gomina ana ni Ondo Rotimi Akeredolu lati bawọn kẹdun ipapoda rẹ.












