Morocco ń retí àti gba ife ẹ̀yẹ AFCON lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, Senegal ní yóò sọ bóyá yóò rí bẹ́ẹ̀ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ òní

Aworan Balogun Morocco Achraf Hakimi (apa osi) ati agba ọwọ iwaju Senegal, Sadio Mane (apa ọtun) yoo ma koju arawọn ni ipele aṣekagba AFCON

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan Balogun Morocco Achraf Hakimi (apa osi) ati agba ọwọ iwaju Senegal, Sadio Mane (apa ọtun) yoo ma koju arawọn ni ipele aṣekagba AFCON
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilu Morocco yoo wa lati fi opin si idaduro aadọta ọdun 50 lati gba ife ẹyẹ Afcon keji nigbati wọn ba koju Senegal ni ipele aṣekagba idije 2025 Africa Cup of Nations ni lọjọ Aiku.

Ṣugbọn awọn Kiniun Atlas yoo tun wa ọna lati ko ere gbogbo owo ti wọn na si idagbasoke ere bọọlu lorilẹede naa.

Ifẹsẹwọnsẹ yii ti yoo waye ni olu ilu Morocco, Rabat (19:00 GMT) da ilẹ Afrika si ipin meji, nigbati orilẹede to dantọ ju ni apa ariwa Afrika, ti wọn wa ni ipo kọkanla ni agbaye yoo ma koju Senegal to jina si wọn wa ni iwọ oorun Afrika.

"A ti n duro de ife ẹyẹ yii fun aadọta ọdun bayi," Olugbeja ẹgbẹ agbabọọlu Morocco Romain Saiss sọ fun BBC World Service.

"O ti pẹ fun gbogbo eniyan ni orilẹ-ede wa. O jẹ ala to wa si imusẹ fun gbogbo awọn araalu Morocco."

Morocco lo ni ọwọ ẹyin to da ju ninu idije yii, ti wọn o si ti mi awọn wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ marun un, to si jẹ pe ẹẹkan pere ni wọn mi awọn wọn niwaju amoye Yassine Bounou, ṣugbọn o daju pe yoo koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to ni agbara pẹlu Senegal, ẹgbẹ agbabọọlu to ti mi awọn mejila ninu idije yii.

Awọn ara Iwọ-oorun Afirika, Senegal naa lero lati gba ife ẹyẹ keji lẹyin ti wọn gba akọkọ ni orilẹede Cameroon lọdun 2021.

Milọnu mẹwaa owo dọla ni ẹni to ba bori yoo gba lọtẹ yii.

Ẹwẹ, igba kẹrin ree to jẹ pe awọn akọnimọgba ilẹ Afrika ni wọn ko awọn ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Afrika wọ ipele aṣekagba, pẹlu Walid Regragui ti Ilu Morocco ati Pape Thiaw ti Senegal, wo awukọse Djamel Belmadi (Algeria, 2019), Aliou Cisse (Senegal, 2021) ati Emerse Fae (Ivory Coast, 2023).

Aṣeyọri ifẹsẹwọnsẹ yoo jẹ kiko ere owo ti Morocco ti na lori ere bọọlu

Walid Regragui,

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbigba Afcon ti jẹ iṣẹ akanṣe igba pipẹ fun Morocco - ati pe o jẹ ọkan ti o ni atilẹyin Ọba Mohammed VI, ẹniti o kọkọ jiroro lori ero rẹ lati lo bọọlu bii irinṣẹ fun idagbasoke awujọ ati eto-ọrọ aje ni ọdun 2008.

Ijagunmolu ti waye lori papa, ṣugbọn pupọ ninu wọn jẹ awọn aṣeyọri awọn ọdọ dipo awọn ẹgbẹ agbabọọlu Atlas Lions - paapaa bo ti jẹ pe awọn ni ẹgbẹ agbabọọlu afrika akọkọ ti yoo Semi final ni idije ife ẹyẹ agbaye ni ọdun 2022.

Awọn ọdọ labẹ-ọdun mẹtadinlogun gba ami ẹyẹ baba ni idije Olimpiiki Paris ti ọdun 2024 ati awọn to wa labẹ ẹni ogun ọdun gba ife ẹyẹ agbaye lẹyin ti wọn ṣẹgun Argentina ni Oṣu Kẹwaa ọdun to kọja.

Ilu Morocco tun ti gbe igba oroke ninu idije Awọn orilẹ-ede Afirika (CHAN) mẹta - eyiti wọn ti kopa ni (2018, 2020 ati 2024) ati pe ẹgbẹ naa tun gba Fifa Arab Cup ni oṣu to kọja.

Sibẹsibẹ Ilu Morocco ko ṣọwọn lati gbe ife ẹyẹ Afcon soke lati igba ti wọn ṣẹgun orilẹede Ethiopia ni ọdun 1976, pẹlu eyi jẹ ifarahan wọn keji ni ipele aṣekagba Afcon lati igba naa.

"A n ko ere ti awọn nnkan ti a ṣe fun ere bọọlu Morocco ṣugbọn a ko gbọdọ gbagbe ibi ti a ti wa," Regragui sọ, ẹniti o agbabọọlu Morocco ti o kẹhin lati ṣe idije ipari Afcon, to lulẹ sọwọ orilẹede Tunisia ni ọdun 2004.

"Inu mi dun pupọ fun awọn agbabọọlu ati fun awọn ara ilu Morocco," o sọ lẹyin ti wọn ṣẹgun Nigeria.

"O jẹ ẹbun nla fun wọn lati wa ni ipele aṣekagba ṣugbọn a yoo nilo latipada ni kiakia nitori a fi agbara pupọ sinu ere."

N jẹ Mane yoo pari saa rẹ pẹlu aṣeyọri?

Sadio Mane

Oríṣun àwòrán, Reuters

Senegal bori orilẹede Egypt, to ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba meje ọtọọtọ, to si jẹ Sadio Mane lo mi awọn to gbe wọn ipele aṣekagba.

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa lo gba pẹnariti to mu wọn bori, gba ife ẹyẹ ọdun 2021 nigba ti koju Egypt bakan naa.

Agba ọwọ Liverpool tẹlẹ ni o ṣeeṣe lo tun gba ami ẹyẹ mi, to I ti kede eyi idije ti yoo gba kẹyin.

"Wọn ma n bori ipele aṣekagba ni," Mane sọ.

"Inu mi yoo dun pupọ lati gba idije Afcon mi ti o kẹhin, lati gbadun rẹ ati lati jẹ ki orilẹ-ede mi bori."

Ẹwẹ, Senegal ni ọpọlọpọ awọn agbabọọlu to damuṣe to wa pẹlu Mane, bii Iliman Ndiaye, Nicolas Jackson, Habib Diallo, Ismaila Sarr ati Ibrahim Mbaye, ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

Awọn Kiniun Teranga yoo wa laisi Balogun wọn, Kalidou Koulibaly ati agbawọ-aarin Habib Diarra nitori wọn gba kaadi, ṣugbọn goli Edouard Mendy ati agbabọọlu Idrissa Gana Gueye wa ninu awọn iyoku ti yoo kopa.

Thiaw, akọnimọgba wọn yoo ni anfani lati di akọnimọgba akọkọ ti gba idije CHAN ati Afcon.