A gbọ́dọ̀ lé àwọn darandaran tó ń pa èèyàn kúrò nílẹ̀ Yorùbá - Sunday Igboho

Ajijagbara fun idasilẹ orilẹ ede Yoruba, Oloye Sunday Igboho sọ pe asiko ti to bayii lati le gbogbo awọn darandaran to pa eeyan kiri kuro nilẹ Yoruba.
Igboho sọ ninu fidio kan to ṣe wi pe gbogbo ọmọ Yoruba gbọdọ fi ọwọ so ọwọ pọ lati gba ara wọn lọwọ awọn darandaran to n ṣọṣẹ nilẹ Yoruba.
Igboho ni kii ṣe awọn sọja ni Yoruba nilo lati gba ara wọn lọwọ awọn darandaran to n pa eeyan kiri lori oko won.
"A ni lati fẹnu ko ki a fi imọ ṣọkan lori iṣori eto abo to n koju wa nilẹ Yoruba.
A ko ni lati duro ijọba tabi ẹnìkankan.
Wọn ti gba ọpọ ninu ilẹ wa, a o le lọ si oko mọ.
Wọn pa awọn ọba wa ni ipinlẹ Ekiti.
Lẹyin ti a ba le awọn darandaran apaayan yii danu tan nilẹ wa, nigba naa ni a o le maa lọ si oko pada lai bẹru.
A o ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn baba wa lati wa ojutuu si ọrọ abo nilẹ Yoruba," Igboho ṣalaye.
Igboho ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe oun ko ṣiṣẹ fun oloselu kankan.
O ni ọrọ iran Yoruba lo jẹ oun logun.















