Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ẹjọ́ tí àwọn ẹlẹ́sìn Ifa pe Emir Ilorin àti iléesẹ́ ọlọ́pàá

Aworan awon onifa

Ile ẹjọ giga ti o kalẹ si ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara ti wọgile ẹjọ ti awọn ẹlẹsin Ifa lagbaye, International Council for Ifa Religion, pe Ileesẹ olọ́paa ati Emir Ilu Ilọrin.

Eyi waye loni ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu keji ọdun 2024, niwaju Justice Taoheed S Umar.

Ti ẹ o ba gbagbe, awọn onisẹse yi ti gbogbo wọn pe metalelogorin niye lo pe ajọ Ọlọpaa ati Emir Ilu Ilọrin lẹjọ fun ẹsun fifi ẹtọ ẹni dun ni.

Ohun ti o wa ninu iwe ipẹjọ ti gbogbo wọn tọwọbọ to si tẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe awọn olujẹjọ meji yi ko gba awọn onisẹse Ilorin laaye lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn ni ogunjọ osu kẹjọ, ọdun 2023 fun ajọdun Isẹse lagbaye.

Ìdí tí adájọ́ fi wọ́gilé ẹjọ́ náà

Níbi igbẹjọ toni, agbẹjọro awọn olupẹjọ ti ohun naa jẹ eekan onisẹse iyẹn, Ọgbeni Malcolm Omirhobo (SAN) ko yọju si ile ẹjọ sugbọn o fi isẹ ran agbẹjọro mii tii se, Lọya Adeyemi.

Ọgbeni Adeyẹmi lo mu iwe kan wa si ile ẹjọ wi pe Ọga oun ran oun lati se atunse ninu iwe ipẹjọ ti awọn pe saaju.

O ni lotitọ, ohun mọ pe oni wa fun igbẹjọ ni pẹreu sugbọn o se pataki ki awọn ṣe awọn atunse naa ki igbẹjọ to tẹsiwaju.

Adajọ TS Umar koro oju si igbesẹ yi, o sọ wi pe igbẹjọ ni oni wa fun kii se fun atunse iwe ipẹjọ.

O ni kaka ti wọn yoo fi ma ṣe atunse iwe ipẹjọ, yi o dara ki ile ẹjọ wọgile ẹjọ ọhun lati fun wọn ni anfani lati se gbogbo atunse ti wọn fẹ ṣe, ki wọn si pe ẹjọ mii lakọtun.

Lẹyin eyi ni adajọ TS Umar wọgile ẹjọ naa, o si ni ki wọn padawa nigba ti wọn ba se tan.