Ṣé lóòtọ́ ni Pasuma fẹ́ ṣe ìgbéyàwó lọ́dun yìí?

Aworan Wasiu Alabi

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Alabi ti ọpọ mọ si Pasuwa ti kede igbesẹ rẹ lori ṣíṣe igbeyawo.

Pasuma, ẹni ọdun marundinlọgọta, to jẹ Baba fun ọmọ mẹwaa ni oun ti setan lati gbe iyawo si ile lẹyin ayẹyẹ ọdun ipapoda iya rẹ, Alhaja Adijat Kuburat, ẹni to jade laye ninu oṣu kẹrin ọdun to kọja.

O sọ eyi ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu gbajumo oṣere tiata, Iyabo Ojo.

Lasiko ifọrọwerọ naa, Iyabo Ojo bere pe nigba wo lo n gbero lati se igbeyawo.

Pasuwa fesi, "Ọpọ eeyan lo ti n bere ibere yii lọwọ mi fun ọgbọn ọdun bayii, ti ìwọ naa si n bí mi bayii ni bi ti mo ba aye mi de bayii.

"Ẹ fọkan balẹ, ma ṣe igbeyawo lẹyin ayẹyẹ iranti ọdun kan fun iya mi."

Bakan naa lo sọrọ nípa ipo to wa lẹyin ti iya rẹ jade laye lọdun to kọja.

"O ti waye, ko si nnkan ti mo le se si. Mo nifẹ iya mi, ti mo si se ohun kohun lati ri pada sugbọn nnkan ti Ọlọrun fẹ ti mo si ni lati juwọ silẹ.

"Mo saa gbogbo agbara mi lati tọju iya mi, ko rọrun lati padanu iya tabi ẹni to ba sumọ eeyan."