Iṣẹ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba torí àmúlò àbájáde ìgbìmọ̀ Oronsanye-Ìjọba Nàìjíría

Oríṣun àwòrán, X/Mohammed Idris
Minisita feto iroyin lorileede Naijiria Mohammed Idris ti fi da awọn oṣiṣẹ ìjọba loju pe ko amuṣẹ abajade igbimọ Oronsanye ti ijọba fẹ gunle ko tunmọ si pe iṣẹ yoo bọ lọwọ wọn.
Kaka bẹẹ o ni agbekalẹ ilana t'awọn n gbero yoo mu ki awọn ileeṣẹ ti iṣẹ wọn ba papọ parapọ di ọkan.
Niluu Abuja loni fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ.
"Koko ni pe ijọba fẹ mu adinku ba iye ti wọn n na ki agbega sí ba bi wọn ṣe n ṣeto.Ko tunmọ si pe ijọba yoo gba iṣẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ tabi sọ wọn si okolombo"
Minisita sọ pe abajade iwadii Oronsanye jẹ atọka si ifarajin aarẹ lati ṣe pẹlẹ pẹlu isuna ati isakoso nípa ayẹwo finifini awọn ileeṣẹ ati ẹka ijọba.
O ni fifi ontẹ jan abajade iwadii Oronsanye ti wọn ṣiṣẹ finifini lori rẹ waye ki kudiẹ kudiẹ kankan ma wa nibi awọn iṣẹ pataki.
O fikun pe ijọba fẹ gbe igbesẹ yi ki wọn baa le mojuto awọn ohun tó ṣe pataki fun araalu ṣaaju ohun gbogbo

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Others
Lojuna lati ṣatunto bi ijọba ṣe n ṣiṣẹ, Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti buwọ lu abajade igbimọ ti Stephen Oronsaye daba, eyi to sọ nipa bi wọn yoo da awọn ileeṣẹ ijọba kan papọ mọra wọn.
Nibi ipade igbimọ iṣakoso ti Aarẹ Tinubu jẹ alaga rẹ lọjọ Ajẹ, Mọnde to kọja lo ti sọ pe awọn bẹrẹ amulo naa.
Minisita fọrọ eto iroyin and ilanilọyẹ, Mohammed Idris naa si jẹ ko di mimọ fun awọn akọroyin Aso-Rock niluu Abuja.
Idris nigba to n sọrọ, sọ pe “Ninu igboya lonii, ijọba yii labẹ iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun nifẹẹ si abajade igbimọ Oransaye, ati pe wọn yoo bẹrẹ sii ṣamulo rẹ lai fi akoko ṣofo.
“Ni bayii, ohun ti eyi tunmọ si ni pe ọpọ awọn ileeṣẹ ati ajọ ijọba, to fi mọ awọn ẹka ileeṣẹ ijọba ni wọn yoo da papọ soju kan, ti wọn yoo si parapọ.
“Awọn kan ti mọ, a ti ṣe awọn kan, a si ti yọ awọn kan kuro. Awọn miran lati gbe lọ si ibomiran nibi ti ijọba ti lero wi pe wọn yoo ti wulo daadaa.
Awọn ohun mẹsan to yẹ ki ẹ mọ nipa abajade ọhun ree;
- Lọdun 2011 ni Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Ebele Jonathan gbe igbimọ aarẹ lori atunto awọn ileeṣẹ ati ajọ ijọba kalẹ kalẹ, eyi ti Stephen Oronsaye jẹ alagẹ igbimọ ọhun.
- Awọn to wa ninu Igbimọ Aarẹ naa ni: Stephen Oronsaye, alaga; Japh CT Nwosu, Rabiu D. Abubakar, N. Salman Mann, Hamza A. Tahir, Adetunji Adesunkanmi, ati Umar A. Mohammed, ti gbogbo wọn jẹ ọmọ igbimọ.
- Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2012 ni igbimọ yii gbe abajade ti ko din ni ẹgbẹrin abala (800pages) naa lọ siwaju aarẹ, nibi ti wọn ti tu ọpọ aṣiri nipa ifigagbaga to wa laarin awọn ileeṣẹ ijọba ati bi pupọ wọn ṣe n ṣiṣẹ to jọ ara wọn.
- Kii ṣe pe abajade yii da ikunsinu silẹ nikan, o tun tu aṣiri nipa bi ijọba ṣe n na owo anadanu.
- Abajade naa tun sọ, pẹlu awọn ohun miran nipa bi ijọba ṣe gbọdọ fi opin si awọn ileeṣẹ kọọkan, eyi ti wọn fi n gbe oriṣiriṣi akanṣe iṣẹ ti ko wulo jade.
- Abajade igbimọ Oronsaye yii fidi rẹ mulẹ pe ọkanlelogojilelẹẹdẹgbẹta (541) awọn ileeṣẹ ijọba apapọ lo wa.
- Abajade yii daba pe ki wọn din awọn ileeṣẹ ẹtalelọgọtalenigba (263) ku si ọkanlelọgọjọ (161), ki wọn si yọ ileeṣẹ mejidinlogoji danu, bẹẹ lo ni ki wọn pa ileeṣẹ mejilelaadọta papọ soju kan ṣoṣo.
- Bakan naa lo tun sọ pe ki awọn ileeṣẹ (agencies) mẹrindinlogun maa jabọ fun awọn ẹka ileeṣẹ ijọba (ministries).
- Lẹyin eyi ni ijọba tun gbe igbimọ miran ti wọn pe ni White Paper Drafting Committee ti adajọ agba Naijiria ati minisita fọrọ eto idajọ, Mohammed Adoke kalẹ lati ṣagbeyẹwo abajade naa, ki wọn si kọ awọn ohun ti wọn ba bọ sinu iwe funfun.















