''N25,000 owó LAPO ni mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ 'Cake' ṣíṣe, àmọ, mò ń pa N70,000 lójúmọ̀ báyìí''

Ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ni Arabinrin Tosin Ibiwoye fi bẹrẹ isẹ ''cake'' ṣiṣe, amọ, lonii o sọ pe iṣẹ naa ti di nla ti o si ni ere tabua lori.
Ibiwoye to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ ileeṣẹ ‘AS Cakes & Pastries niluu Ilorin sọ pe ''mo lọ ya ẹgbẹrun mẹẹdọgbọnowo LAPO ti mo fi gba ṣọọbu nigba yẹn ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ọhun lo wa di ẹgbẹrun lọna ọgọta, ẹgbẹrun lọna aadọrin lojoojumọ.''
Ibiwoye to ti bẹrẹ iṣẹ yii fun bii ogun ọdun ṣalaye pa ọpọlọpọ eeyan ni oun ti kọ ni iṣẹ ọhun.
Ọmọ iṣẹ mẹrindinlaadọta ni Arabinrin Ibiwoye ni bayii.
''Lẹnu iṣẹ yii, awa naa n ni ọkọ, oriṣiriṣii mọtọ.
A n kọ ile, a n ran ọmọ lọ ile ẹkọ, emi gan tun n san owo oṣu fawọn to kẹkọọ jade.
Ki lo tun wa ku lẹnu iṣẹ yii ti eeyan ko tii gbe ṣe?''
Ibiwoye ni oun ko le gba iṣẹ ijọba tori owo nla ni oun n ri nibi iṣẹ oun.
















