Ẹgbẹ́ oníṣèṣe gbé Emir Ilorin àti ọlọ́pàá lọ ilé-ẹjọ́ lórí bí wọ́n ṣe dá àjọ̀dún wọn dúró

Aworan Malcolm Omirhobo (SAN)

Oríṣun àwòrán, Malcolm Omirhobo (SAN)

Awọn ẹlẹsin Isẹse lagbaye, International Council for IFA Religion ti wọ ajọ ọlọpaa Naijiria ati Emir Ilorin lọ ile ẹjọ giga ni ilu Ilọrin ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbẹjọro onisẹse naa, Lọya Femisi, ṣe sọ, ipinnu lati wọ ajọ Ọlọpaa lọ ile ẹjọ ko sẹyin bi wọn ṣe da awọn onisẹse Ilu Ilọrin duro lati se ọdun Isẹse agbaye to waye ni ogunjọ oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Ọgbẹni Fẹmisi salaye pe ajọ ọlọpaa sọ pe kawọn oniṣẹṣe gbe ọdun wọn kuro ni Ilọrin, o ni wọn fi ẹtọ wọn dun wọn.

O ni eyi lo faa ti wọn fi gbe ẹjọ naa dide si ajọ ọlọpaa, Emir Ilu Ilọrin ati awọn yoku.

Ọgbẹni Femisi tun sọ wi pe awọn ọrọ ti ọga agba ọlọpaa sọ lori afẹfẹ lọjọ ọdun naa yatọ gedegbe si ọrọ ajọsọ awọn nigba ti awọn se ipade pọ.

O fi kun un pe awọn ni ẹri to daju lati gbe kalẹ fun ile ẹjọ.

Lonii ni igbẹjọ naa waye loni ọjọ kẹrindinlọgbọn niwaju Adajọ Taoheed Umar.

Agbẹjọro agba, Oloye Malcolm Omirhobo (SAN) lo duro fun awọn onisẹse nile ẹjọ.

Tẹ o ba gbagbe, Ọgbẹni yi ni ogbontarigi agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan to si jẹ onisẹse.

Oun kan naa lo mura bii Babalawo wọ ile ẹjọ 'Supreme' l'Abuja ati ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Eko losu kẹfa ọdun 2022.