Àwọn ajínigbé ji èèyàn mẹ́ta gbé ní kwara, ẹnìkan kú, ọwọ́ tẹ afurasí márùn-ún

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Niṣe lọrọ di bi o ko le lọ ki o yago lọna lopin ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn sọ pe awọn agbebọn ajinigbe yawọ agbegbe Sulu to wa ni ẹkun Omupo, ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara.
Aarọ kutu, ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2024 ni awọn ajinigbe yawọ agbegbe naa, ti wọn si ji eeyan mẹta gbe wọnu igbo lọ.
Iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ jẹ ko di mimọ pe inu ile awọn eeyan naa wa lasiko ikọlu ọhun.
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, Toyin Ahmed to ba aṣojukọroyin BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn kan ti wọn funra si gẹgẹ bii Fulani adaranjẹ lo ṣọsẹ buruku naa.
Ahmed ni ninu ile ni wọn ti lọ gbe awọn mẹtẹẹta yii, pẹlu afikun pe awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn ikọ ojulalakan-fin-ṣọri ti a mọ si fijilante lo sare tẹle wọn wọ inu igbo lasiko naa.
Ọkunrin naa ni awọn ọlọdẹ yinbọn pa ọkan lara awọn ajinigbe yii lasiko ti wọn yiju pada si wọn.
Ahmẹd ni idunnu nla lo jẹ pe awọn ọlọdẹ ati awọn fijilante yii doola ẹmi awọn ti wọn jigbe, wọn si ri wọn gba pada.
O ni lẹyin o rẹyin lọwọ tẹ afurasi marun-un ninu wọn, ti wọn si ti lọ fa wọn le ọlọpaa lọwọ loju ẹsẹ lai fi asiko ṣofo.
Nigba toun naa n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Toun ṣalaye pe awọn afurasi tọwọ tẹ ti wa lahamọ awọn, ṣugbọn to ni iwadii ṣi n lọwọ.
Toun fi kun ọrọ rẹ pe olu ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo awọn tọwọ tẹ naa wa, ati pe oun yoo gbe atẹjade sita nipa iṣẹlẹ naa laipẹ.















