Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, ẹ tún èrò yín pa lórí ìwọ́de tí ẹ fẹ́ ṣe - Mínísítà ètò ìdájọ́

Oríṣun àwòrán, NIGERIA LABOUR CONGRESS/FACEBOOK
Agbejoro agba ati Minisita fọrọ eto idajọ ni Naijiria, Lateef Fagbemi ti rawọ ẹbẹ sẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Labour Congress (NLC) lati pa iwọde ifẹhonuhan ti wọn fẹẹ ṣe sẹgbẹ kan.
Ninu lẹta ti minisita naa kọ ranṣẹ si ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC laipẹ yii lo ti sọ pe iwe aṣẹ kan wa nilẹ to tako igbeṣẹ ẹgbẹ naa lati jade ṣe iwọde ifẹhonuhan lasiko yii.
Agbejọro agba naa sọ pe igbesẹ tabi erongba NLC yii jẹ eyi to ṣi wa niwaju ile ẹjọ ti National Industrial Court.
Iwọde ifẹhonuhan ti ẹgbẹ Labour fẹẹ ṣe yii ni wọn lo tako aṣẹ ti ile-ẹjọ pa, ti igbẹjọ naa ti wọn ṣi fi ti ṣẹgbẹ kan ṣi n lọwọ.
Bakan naa lo sọ pe gbogbo ileri ti ijọba apapọ ṣe fun ẹgbẹ Labour ninu iwe adehun ti wọn jọ tọwọ ni wọn ti mu ṣẹ.
Siwaju sii lo rọ agbẹjọro ẹgbẹ oṣiṣẹ naa, Amofin Fẹmi Falana lati ba awọn onibara rẹ sọrọ lori igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe yii, eyi ti yoo si tako iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ tẹlẹ.
Ati pe igbesẹ ọhun yoo tun tako aṣẹ ti ile-ẹjọ gbe kalẹ nipa dida alaafia ilu laamu.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun ti a wa ninu ẹ yii ni ẹgbẹ NLC gbe atẹjade sita wi pe iwọde ifẹhonuhan yoo waye kaakiri Naijiria lọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2024 lati fi tako ipenija eto ọrọ aje tawọn araalu n koju lorileede yii.















