Kò sí ohun tó lè dá ìfẹ̀hónúhàn wa dúró – NLC sọ fún àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́

Oríṣun àwòrán, Joe Ajaero/Facebook
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Nigeria Labour Congress (NLC) ti sọ pe ko si ohun to le da ifẹhonuhan ti awọn n palẹmọ rẹ kaakiri orileede yii duro.
Wọn ni ikilọ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ orileede yii n ṣe wi pe ki awọn fi ifẹhonuhan naa ti sẹgbẹ kan ko le ṣeeṣe lasiko ọwọngogo yii.
Ṣaaju asiko yii ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ti rọ ẹgbẹ NLC lati so ifẹhonuhan ti wọn fẹẹ ṣe rọ fungba diẹ, pẹlu erongba lati gba alaafia laaye.
Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti bẹrẹ sii sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri Naijiria lati maa gbaradi fun ifẹhonuhan ti yoo waye lọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji ọdun ti a wa yii lori ọwọngogo ounjẹ to gbode.
Peter Afunanya to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuytẹ nigba to n sọrọ l’Ọjọru sọ pe ki ẹgbẹ NLC wa ọna miran bii jijo papọ pẹlu ijọba lati jiroro dipo ki wọn bẹrẹ ifẹhonuhan to ṣee ṣe ko ja si ibi ti ẹnikẹni ko lero.
Sibẹ, Aarẹ gbẹ NLC, Joe Ajaero ninu atẹjade to buwọ lu nirọlẹ Ọjọru jẹ ko di mimọ pe ko si ohun to le da erongba awọn lati ṣe ifẹhonuhan duro.
Ajaero sọ pe ki lo n da ajọ DSS duro lati f’ofin gbe gbogbo awọn to n gbero lati dabaru eto ifẹhonuhan alalaafia ti awọn fẹẹ ṣe.
“O ya wa lẹnu pupọ lati ri ọrọ amọran ti a ko nilo gba lati ọdọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS wi pe ka wọgile ifẹhonuhan ti a n gbero rẹ lori ọwọngogo ounjẹ ati igbe aye to le koko, pẹlu iya to pọ niluu, to fi mọ bi iṣẹ ati oṣi ṣe n gbilẹ si, ti owo naira si ti di ọwọngogo si dọla.
“Gẹgẹ bi DSS ṣe sọ, wọn ni ka ‘wọgile ifẹhonuhan nitori alaafia’, pẹlu ero wi pe ifẹhonuhan naa yoo da wahala silẹ tabi mu ipa danu, koda pẹlu akọsilẹ ifẹhonuhan alalaafia loriṣiriṣi ti a ti ṣe.
“O n ya wa lẹnu lori ipa ti ajọ DSS n ko funra rẹ lati jẹ agbẹnusọ ijọba.
“Bakan naa lo tun n ya lẹnu pe ajọ DSS mọ awọn kan ti wọn n gbero lati lo anfaani ifẹhonuhan yii lati fi da wahala nls silẹ, ki wọn si gbe e gba ọna ti awọn ko fẹ, sibẹ wọn ko tii bẹrẹ igbesẹ lati lọ fi ofin gbe gbogbo wọn.”
Ajaero ni awọn ko nii gba ohun ti ajọ DSS sọ, nitori pe ifẹhonuhan alalaafia lawọn yoo ṣe gẹgẹ bi eyi ti wọn ti n ṣe tẹlẹ, ti ko si mu jagidijagan dani.
“A fẹẹ jẹ ki ajọ naa mọ pe ifẹ, iṣọkan ati alaafia jẹ awa logun ju ohunkohun lọ, ti a si ni orukọ rere, a ko nii ṣe ohun to le da agbara tabi eto aabo orileede yii ru.
“Lẹyin ohun ti a sọ yii, a ko nii jẹ ki orukọ wa bajẹ tabi ka purọ mọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ. Ifẹhonuhan alaafia ni a fẹẹ ṣe lodi si igbe aye ọwọngogo to n ṣẹlẹ si gbogbo araalu, ti ko si yọ awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ sẹyin.
“A ko le kawọ gbera ka si maa ṣe bi ẹni pe ohun gbogbo n lọ deedee. Igbimọpọ buruku ti itan ko nii forijin wa ni.”















