Àwọn akẹ́kọ̀ọ́, aráàlú àtàwọn òṣìṣẹ́ tú sí ìgboro láti ṣe ayẹyẹ ìkẹyìn fún Akeredolu

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, bbc

Wọn ti gbe oku Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu lọ ilu Akure lẹyin oniruru ìsìn ati imọyifún oloogbe naa to waye ni ilu Ìbàdàn fún Ojó mẹrin.

Awọn eyan ipinlẹ Ondo, to fi mọ Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo tẹwọ gbà ará Gomina tẹlẹ ọhun ati awọn mọlebi rẹ ni ọgba ọfisi gomina to wa ni Alagbaka, niluu Akure.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, bbc

Gomina Aiyedatiwa ninu ọrọ rẹ sọ pẹ oṣe pataki lati bu ọla fún oloogbe Akeredolu ni oruko ọọfisi gomina, paapaa julọ lati fún awọn oṣiṣẹ ìjọba láánfàní lati yẹ oloogbe naa si tori ipa to ko ninu igbayegbadun wọn.

Awọn adari ikọ Amotekun kakiri lati awọn ipinlẹ miran ni wọn waa ni ipinle Ondo gẹgẹ bi awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ naa ṣe peju sì ọfisi gomina.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, bbc

Irinajo oku gomina Akeredolu lati Ilu Ibadan sì ilu Akure

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, bbc

Lẹyìn oniruru eto ayẹyẹ ìkẹyìn fún oloogbe Akeredolu ni ilu Ìbàdàn, awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ gbera lati ilu Ìbàdàn lọ sì ilu Akure ni tẹsiwaju eto ìṣinku rẹ.

Bi igbaradi fún ayẹsi olóògbé Oluwarotimi Akeredolu ṣe n lọ ninu ọgbà ọọfisi gomina ipinlẹ Ondo, awọn akẹẹkọ ile ẹkọ girama ni ilu Akure naa tuyaya tuyaya sì ẹgbẹ ọna lati pàdé ara olóògbé Oluwarotimi Akeredolu.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, bbc

Lati àgbègbè roadblock ni popona márosè Akure si Ilesha, titi dé aarin igboro olu ilu ipinlẹ Ondo ni awọn ọmọ ile ẹkọ naa wa.

Awọn ikọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun naa dúró wamuwamu sì awọn oríta to ṣe gboógì, bẹe lawọn oṣiṣẹ ìjọba naa bọ sita.

Ni nnkan bii aago mọkanla abọ owurọ Ọjọru ni ara gomina ọhun wo ilu Akure ti awọn èèyàn si bọ síta pelu àsìá orilẹ̀-ede Naijiria lati bu ọla fún oloogbe Akeredolu.

Ẹgbẹ́ àwọn amòfin ṣe ayẹyẹ ìdágbére fún Akeredolu

Rotimi Akeredolu
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni orilẹẹde Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Oyo, ti ṣe se ayẹyẹ isin imọriri ati idagbere fun Gomina Rotimi Akeredolu to di oloogbe.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Rotimi Akeredolu jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.

Nibi eto naa to waye niluu Ibadan, ni awọn agba agbẹjọro bii Lateef Fagbemi, ati awọn miran.

Saaju iku rẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu, ni baba isalẹ fun ẹgbẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ naa, laarin ọdun 2017-2023.

Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo, Amofin Folasade Aladeniyi, sọ pe Arakurin Akeredolu jẹ ọkunrin takuntakun ti ko si ẹni ti kole gbena woju rẹ.

Amofin Aladeniyi sọ pe oloogbe lo ṣiṣẹ́ takuntakun fun idasilẹ ọlọpa ipinlẹ ti Aarẹ Tinubu buwọlu laipẹ yii.

Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ti oun naa ba wọn peju sibi eto idagbere naa sọ pe oloogbe jẹ ọga to se mu yan-an-yan láwùjọ.

"Gbogbo isẹ rere ti wọn se le mi naa ma tẹsiwaju lori wọn.

O ṣapejuwe iṣejọba ọga rẹ, gẹgẹ bi eyi to mu idagbasoke ba ipinlẹ Ondo.

Oloogbe Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu lo jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn amofin ni orilẹ-ede Nae lati ọdun 2008 si ọdun 2010.

Bakan naa lo tun jẹ alaga ẹgbẹ ni ilu Ibadan ni ọdun 1992 si 1993.

Àwọn agbẹjọ́rò
Awọn alejo nibi eto naa
Awọn akọrin nibi eto idagbere naa
Iyawo oloogbe, Arabinrin Betty Akeredolu naa lọ sibi eto naa
Àkọlé àwòrán, Iyawo oloogbe, Arabinrin Betty Akeredolu naa lọ sibi eto naa

Bi eto isin idagbere Akeredolu yoo ṣe lọ ree

Ọjọbọ, February 15, 2024:

Isọji ijere ọkan ni gbagede MKO Abiola Democracy Park, Akure

Ọjọ Ẹti, February 16, 2024:

Irun Jimọ yoo waye ni Akure Central Mosque

Ọjọ Abamẹta, February 17, 2024:

Isin idagbere ti ile ẹkọ girama Layola, ti yoo waye ni gbọngan Loyola College Old Ife Rd, Agodi, niluu Ibadan

Ọjọ Aiku, February 18, 2024:

Isin alẹ idagbere ni Fasiti Obafemi Awolowo. Eyi yoo waye ni ile ẹgbẹ OAU, Old Ife Road, Agodi, Ibadan.

Ọjọ Aje, February 19, 2024:

Ijoko ile ẹjọ pataki yoo waye ni ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Oyo to wa ni ile ẹjọ giga, Ring Road, Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Lẹyin ti ijoko naa ba waye ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria yoo ṣe isin idagbere fun Akereolu, ni ile ẹgbẹ wọn, Aare Afe Babalola Bar Centre, Iyagakun, Ibadan.

Isin orin onigbagbọ ati idagbere yoo waye ni gbọngan Jorgor Centre, Liberty Road, niluu Ibadan.

Ọjọ Iṣẹgun, February 20, 2024:

Isin ikẹyin yoo waye ni owurọ ni ile ijọsin All Saints Church, Jericho, Ibadan. Lẹyin eyi ni wọn o tẹ oloogbe si ile rẹ, nibi ti awọn eeyan ti wọn ba fi iwe pe, yoo ti ni anfaani lati wo oku rẹ.

Ọjọru, February 21, 2024:

Ajabue (Oro ile) yoo waye fun oloogbe niluu Owo, nipinlẹ Ondo.

Lọjọ yii kan naa ni ijoko pataki yoo waye fun un ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, to wa ni ilu Akure.

Bakan naa ni wọn o tẹ oku rẹ ni itẹ ẹyẹ, ni papa iṣere ilu Akure fun gbogbo araalu lati wo.

Aṣalẹ idaro ati idagbere ni yoo kẹyin rẹ ni irọlẹ ọjọ naa, niluu Owo.

Ọjọbọ, February 22, 2024:

Eto isin orin onigbagbọ yoo waye nile ijọsin St Andrews Cathedral, Imola, niluu Owo, ipinlẹ Ondo.

Alẹ aisun onigbagbọ yoo waye ni irọlẹ ọjọ naa bakan naa ni ile rẹ, Maranatha Villa, Owo.

Iwọde pẹlu ti tan abẹla ati ikorajọpọ awọn ẹgbẹ ẹlẹmu, Kegites Club, yoo waye ni alẹ ọjọ naa mọju ọjọ keji.

Ọjọ ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024, ni wọn o sin oku Gomina Rotimi Akeredolu, ni ilẹ isinku kan to wa niluu Owo. Amọ, ẹbi nikan ni yoo kopa nibi eto naa.

Ọjọ Abamẹta ni wọn o fi idije bọọlu kan sọri rẹ ni papa iṣere Akure, niluu Akure.

Isin idupẹ ni yoo kadii gbogbo ayẹyẹ naa ni ile ijọsin St. Andrews Church, Imola, Owo.