Ayẹyẹ ètò ìsìnkú Akeredolu bẹ̀rẹ̀ nílùú Akure pẹ̀lú ìsọjí ìta gbangba

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu
Wọn ti bẹrẹ eto isinku gomina ana nipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu.
Eto isinku naa ni wọn bẹrẹ pẹlu isọji ijere ọkan kan, eyii to waye ni gbagede MKO Abiola Democracy Park, niluu Akure.
Gomina Aiyedatiwa ti ke si awọn ẹṣọ alaabo lati pese abo to peye nipinlẹ naa ṣaaju, lasiko, ati lẹyin eto isinku gomina ana ọhun.
Nnkan bii aago marun un irọlẹ Ọjọbọ ni isọji naa bẹrẹ.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Rotimi Akeredolu jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
Bi eto isin idagbere Akeredolu yoo ṣe lọ ree

Oríṣun àwòrán, Ray of Hope
Ọjọbọ, February 15, 2024:
Isọji ijere ọkan ni gbagede MKO Abiola Democracy Park, Akure
Ọjọ Ẹti, February 16, 2024:
Irun Jimọ yoo waye ni Akure Central Mosque
Ọjọ Abamẹta, February 17, 2024:
Isin idagbere ti ile ẹkọ girama Layola, ti yoo waye ni gbọngan Loyola College Old Ife Rd, Agodi, niluu Ibadan
Ọjọ Aiku, February 18, 2024:
Isin alẹ idagbere ni Fasiti Obafemi Awolowo. Eyi yoo waye ni ile ẹgbẹ OAU, Old Ife Road, Agodi, Ibadan.
Ọjọ Ẹti, February 19, 2024:
Ijoko ile ẹjọ pataki yoo waye ni ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Oyo to wa ni ile ẹjọ giga, Ring Road, Ibadan, nipinlẹ Oyo.
Lẹyin ti ijoko naa ba waye ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria yoo ṣe isin idagbere fun Akereolu, ni ile ẹgbẹ wọn, Aare Afe Babalola Bar Centre, Iyagakun, Ibadan.
Isin orin onigbagbọ ati idagbere yoo waye ni gbọngan Jorgor Centre, Liberty Road, niluu Ibadan.
Ọjọ Iṣẹgun, February 20, 2024:
Isin ikẹyin yoo waye ni owurọ ni ile ijọsin All Saints Church, Jericho, Ibadan. Lẹyin eyi ni wọn o tẹ oloogbe si ile rẹ, nibi ti awọn eeyan ti wọn ba fi iwe pe, yoo ti ni anfaani lati wo oku rẹ.
Ọjọru, February 21, 2024:
Ajabue (Oro ile) yoo waye fun oloogbe niluu Owo, nipinlẹ Ondo.
Lọjọ yii kan naa ni ijoko pataki yoo waye fun un ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, to wa ni ilu Akure.
Bakan naa ni wọn o tẹ oku rẹ ni itẹ ẹyẹ, ni papa iṣere ilu Akure fun gbogbo araalu lati wo.
Aṣalẹ idaro ati idagbere ni yoo kẹyin rẹ ni irọlẹ ọjọ naa, niluu Owo.
Ọjọbọ, February 22, 2024:
Eto isin orin onigbagbọ yoo waye nile ijọsin St Andrews Cathedral, Imola, niluu Owo, ipinlẹ Ondo.
Alẹ aisun onigbagbọ yoo waye ni irọlẹ ọjọ naa bakan naa ni ile rẹ, Maranatha Villa, Owo.
Iwọde pẹlu ti tan abẹla ati ikorajọpọ awọn ẹgbẹ ẹlẹmu, Kegites Club, yoo waye ni alẹ ọjọ naa mọju ọjọ keji.
Ọjọ ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024, ni wọn o sin oku Gomina Rotimi Akeredolu, ni ilẹ isinku kan to wa niluu Owo. Amọ, ẹbi nikan ni yoo kopa nibi eto naa.
Ọjọ Abamẹta ni wọn o fi idije bọọlu kan sọri rẹ ni papa iṣere Akure, niluu Akure.
Isin idupẹ ni yoo kadii gbogbo ayẹyẹ naa ni ile ijọsin St. Andrews Church, Imola, Owo.












