Èèyàn kan kú, 21 farapa lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbi àjọyọ̀ kan ní Kansas

Ènìyàn kan tí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí àwọn mọ́kànlélógún mìíràn sì ti farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn tó wáyé ní Missouri, Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí olórí ìlú Kansas ṣe ìwọ́de ìdùnnú ní Super Bowl.
Àwọn aláṣẹ ní èèyàn mẹ́jọ nínú àwọn tó fara gbọta náà ni wọ́n wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run tí àwọn méje mìíràn sì fara gbọta ló lè mú wọn wà ní ipò yìí.
Àwọn ọmọdé mẹ́sàn-án ló wà nínú àwọn tó farapa – tí ìrètí sì wà pé wọn yóò padà bọ̀ sípò.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́ta tó lọ́wọ́ nínú yínyin ìbọn náà.
Nígbà tó ń bá àwọn ènìyàn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kansas, Stacey Graves ní ènìyàn méjìlélógún ló fara gbọta ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn náà tí ẹnìkan sì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Àwọn ọlọ́pàá tó lé ní ọgọ́rin ló wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé láti mójútó ayẹyẹ náà. Graves ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn náà ti bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá dáhùn láti ṣe àmójútó rẹ̀, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí le lórí.
Iléeṣẹ́ rédíò abẹ́lé kan ní ọ̀kan lára àwọn DJ àwọn, Lisa Lopez pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn aláṣẹ ní àwọn tó fara gbọta nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn mẹ́ta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àgbà nọ́ọ̀sì kan, Stephaine Meyer ní àwọn ọmọdé mẹ́sàn-án tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́fà àti ọdún mẹ́ẹ̀dógún tí àwọn náà fara gbọta ni wọ́n ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn Children’s Mercy Hospital.
Àwọn ilé ìwòsàn mìíràn náà ṣàlàyé pé àwọn ń ṣe ìtọ́jú àwọn èèyàn tí kò fara gbọta àmọ́ tí wọ́n farapa látàrí bí wọ́n ṣe ń ti ara wọn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Àwọn aláṣẹ kò dárúkọ àwọn èèyàn tí wọ́n farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà bákan náà ni wọn kò fi orúkọ àwọn afurasí tí wọ́n mú léde.
Ọ̀gá ọlọ́pàá, Graves ní ìdí tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn náà kò ì tíì hàn sí àwọn.
Òṣìṣẹ́ ètò ààbò sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn CBS pé ìbọn yínyìn ṣeéṣe kó wáyé nígbà tí àríyànjiyàn bá wà láàárín àwọn kan tó sì gba ibẹ̀ di nǹkan ńlá. Àmọ́ wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní àwọn èèkàn ìlú Kansas ṣì wà níbi ayẹyẹ náà kí ìbọn yínyìn tó bẹ̀rẹ̀ ní èyí tó mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Paul Contreras, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́ta sọ fún iléeṣẹ́ KETV pé òun ṣèrànwọ́ láti mú ọ̀kan lára àwọn tó ń yìnbọn náà kí àwọn ọlọ́pàá tó dé láti mú un lọ.
Lásìkò tí àwọn ènìyàn ìlú Kansas ń ṣe ayẹyẹ fún èèkàn ìlú wọn kan lórí àṣeyọrí rẹ̀ níbi ayẹyẹ eré ìdárayà tó gbajúmọ̀ ní Amẹ́ríkà ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀.
Mayor ìlú Kansas, Quiton Lucas ní òun àtàwọn ẹbí òun ni àwọn wà papọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn náà bẹ̀rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ sì di ẹni orí yọ ó dilé.
Bákan náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú àẹ̀jáde kan tí wọ́n gbé jáde àti pé gbogbo àwọn ènìyàn òun ló wà ní àláfíà.















