Ẹ wo àwọn ìdí tí ìjọba Naijiria kò fi ní le san ''subsidy'' mọ̀ ọ́ lórí iná mọ̀nàmọ́ná

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita ọrọ ina ọba lorileede Naijiria, Adebayo Adelabu ti sọ pe ijọba ko ni le maa san owo iranwọ mọ lori ipese ina ọba.
Ọjọru lo ṣalaye ọrọ yi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja.
O ni idi ni pe gbese owo to wa nilẹ ti ijọba fẹ ẹ san fun awọn ileeṣẹ to n pese ina ti pọ, to si ti wọ triliọnu mẹta Naira.
Lati le wa ojutu si eleyi, minisita naa sọ pe ayafi ki ijọba mu ọkan ninu sisan owo iranwọ lori ina tabi ki o si jẹ ki ẹkunwo kuro ki araalu san owo ina ti awọn yoo le ṣeto rẹ.
Ni koko, alekun yoo ba iye owo ti araalu n san lori owo ina mọnamọna.
Aisi ina ọba jẹ ọkan lara ipenija gbogbo igba ti araalu n koju ni Naijiria.
Ọpọ igba ni araalu kii ni ina ti awọn ẹrọ ipese ina ọba a si maa dẹnukọlẹ loore koore.
Ninu ọdun 2024 yii, ina ọba ti dẹnukọlẹ ninu oṣu keji ti o si mu ki ọpọ ilu ati abule ma ni ina ọba.
A rii ninu akọsilẹ wi pe lọdun 2023, igba mejila ọtọọtọ ni ina mọnamọna kaakiri Naijiria pana pii pẹlu bi oju opo ipinna jakejado Naijiria ti wọn n pe ni ‘National Grid ṣe kọ iṣẹ silẹ.
Wọnyii ati awọn idi miran ni araalu fi sọ pe ko yẹ ki alekun ba iye owo ina ti ipese rẹ ko daju lọpọ igba.
Ki wa lawọn idi ti Minisita fi sọ pe o di dandan ki ijọba dẹkun sisan ẹkunwo ina ọba?
Gbese pọ, dọla dẹnu kọlẹ
Minisita Adelabu ko ṣẹṣẹ maa tẹnu mọ ọrọ yiyọ ẹkunwo lori owo ina ti araalu n san.
Eleyi to tun sọ laipẹ yi ni pe ileeṣẹ ina nilo 2.9 triliọnu Naira lati le fi san ẹkunwo owo ina mọnamọna ni ọdun 2024.
O ṣalaye pe owo ti wọn ya sọtọ ninu owo iṣuna, kere lati san owo yii tori pe ko ju 450 biliọnu Naira ti o wa nilẹ.
Yatọ si eleyi o ni ijọba jẹ awọn ileeṣẹ to n pese gaasi ti wọn fi n peelo ina ọba ni owo to le ni biliọnu kan dọla.
Ti a ba fi eleyi kun gbese N1.3 triliọnu ti o ni awọn jẹ ileeṣẹ to n pese ina taa mọ si awọn GenCos, gbese naa di pupọ .
Lori gbese, o ni awọn wọnyii ni ko le jẹ ko rọrun lati san owo iranwọ lori ina mọnamọna mọ.
Idẹnukọlẹ owo dọla wa ninu awọn idi ti Minisita tun darukọ gẹgẹ bi idi ti awọn ko fi ni le san ẹkunwo mọ.
Bẹẹ lo tun salaye pe ijọba yoo dawọ duro lori awọn akanṣe iṣẹ kan ti o n lọwọ nitori pe pasiparọ owo Dọla si Naira ti gbẹnu soke.
O ni bawọn ko ba pari sisan owo iṣẹ to wa nilẹ wọn ko ni gbe omiran sita.
Ki ni ki araalu wa ṣe bayii?
Ọpọ nkan ni araalu lero pe o kọja arọwọto bẹrẹ lati owo ounjẹ to fi mọ owo bẹntiroo.
Ọjọ ti pẹ ti ailepese ina ọba ni Naijiria ti jẹ okunfa ifasẹyin fun orileede naa.
Lọwọlọwọ, iye ina ọba ti wọn n pese ni Naijiria ko to ẹgbẹrun marun-un megawatts.
Iye ti Naijiria nilo lati le sọ pe oun tiẹ bọ diẹ ninu wahala ipese ina ọba jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn, 30000MW.
Bi a ba pa gbogbo agbara awọn ileeṣẹ ipese ina Naijiria pọ wọn ko le pese ju ina 14000MW lọ.
Bi wọn ko ba ribi wa ojutu si wahala ina yii, inu inira lọpọ yoo si maa wa fọjọ pipẹ.
Lasiko taa wa yii, bbogbo nkan lo gbowo lori ti ọpọ si n kerora pe atijẹ atimu di inira fawọn.
Laipẹ yi naa ni ijọba kede pe awọn yoo ṣe agbekalẹ awọn ilana kan ti yoo mu ki ipese ounjẹ di irọrun.
Owo oṣu oṣiṣẹ kere si iye ti wọn le fi gbọ bukata, ti yiyọ owo iranwọ lara owo bẹntiroo si n jẹ okunfa inira ati airiṣẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria.
Awọn araalu kan tiẹ ṣe iwọde ni awọn ipinlẹ Naijiria kan lati fi ke gbajare si ijọba pẹlu bi nkan ko ṣe rọgbọ.
Ti wọn ba tun wa gbọ pe ijọba fẹ yọ ẹkunwo lori ina mọnamọna ko si ẹni to le sọ bi araalu yoo ṣe gba ikede yi sara.












