Ìrẹsì tí àwọn ẹja n jẹ, Afafata, di ààyò àwọn ọmọ Naijiria nítorí ebi

Oríṣun àwòrán, SANI HAMISU
Ọwọngogo nkan lọja ni Naijiria ti mu ki awọn eeyan kan lapa ariwa ilẹ naa maa fi ireti wọn sinu irẹsi kan to ṣe pe awọn ẹlẹrọ irẹsi maa n kọ silẹ tawọn eeyan a si maa gbe fun awọn ẹlẹja ọsin ki wọn fi sin ẹja wọn.
'Afafata' lorukọ ti wọn n pe orukọ irẹsi yi lede Hausa to si tumọ si 'jija ogun' lati fi ṣapejuwe iru wahala ti wọn maa n ṣe ki wọn to se iru irẹsi naa jina.
Isah Hamisu to jẹ ẹlẹrọ irẹsi ni ilu Kano sọ fun BBC pe ''ni nkan bi ọdun meloo kan sẹyin, niṣe lawọn eeyan maa n da irẹsi yi nu pẹlu kanda irẹsi amọ nkan ti yi pada bayii''
Tohun ti bi irẹsi naa ti ṣe run si wẹwẹ to, ti o si tun dọti, bo ṣe dinwo lo mu ki awọn araalu ti nkan ko rọgbọ fun maa ta si irẹsi ni jijẹ.
Fatima Abdulahi to jẹ agbẹ ọlọsin ẹja sọ pe awọn ẹja oun nifẹ si afafata ṣugbọn bayii ti awọn eeyan naa ti n ba wọn jẹ, owo rẹ ti lọ soke.
Owo ori nkan lọja ni Naijiria ti lewo kọja afarada ju ti nkan bi ọgbọn ọdun sẹyin.
Pẹlu gbogbo wahala yi naa ni aarẹ Bola Tinubu wọgile ẹkunwo owo epo bẹntiroo ti idẹnukọlẹ Naira naa si tun da kun inira yii.
Apo irẹsi aadọta kilogiramu lọja ti wọn le fi bọ idile ẹlẹni mẹwaa laarin oṣu kan ti di ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin Naira bayii.
Alekun bi ida aadọrin ninu ida ọgọrun lo deba iye owo rẹ to wa ni aarin ọdun to kọja ti eleyi si kọja iye owo oṣu ọpọ idile ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Isah Hamisu
Ọwọngogo yi to mu kawọn eeyan maa tiraka lati ri ounjẹ jẹ lo ṣokunfa tawọn kan fi ṣe iwọde ifẹhonuhan lawọn ipinlẹ kọọkan lori bi ilu ṣe le.
Ni ipinlẹ Niger awọn oluwọde gbegi dina ti wọn si gbe iwe pelebe lọwọ ti wọn kọ sibẹ pe ọwọngogo nkan fẹ ẹ gbẹmi lọrun awọn.
Ko pẹ si igba naa ni iwọde mii waye ni Kano .
Eleyi mu ki Gomina Aba Kabir Yusuf gba wi pe lootọ ni ebi wa nilu to si ni o di dandan lati wa nkan ṣe si.
Ọna abayo ko ti waye ṣugbọn awọn araalu n dẹmi de jijẹ afafata.
Hajiya Rabi Isah to fi Kano ṣe ibujoko sọ fun BBC pe ti kii ba ṣe ti irẹsi yi, ebi ki ba pa oun ati awọn ọmọ tori ipa awọn ko ka irẹsi mii.
''Ẹgbẹrun mẹrin ni wọn n ta ike ọda iresi ti ipa mi ko ka. Afafata ti owo rẹ jẹ ẹgbẹru meji Naira laa n jẹ.''
Ike ọda irẹsi yi to idile kan jẹ lojumọ ni ipinlẹ Kano
''Ti ko ba si irẹsi afafata yii, a ti bọ idile mi ko ba jẹ inira nla.''
Pupọ awọn to n ta irẹsi naa lo si ti mọ iyatọ yi lara.
Saminu Uba, to n ṣiṣẹ ni ọja Medile ni Kano sọ pe aje n bugba jẹ pẹlu irẹsi afafata yi.
''Ọpọ ni ko ni ikapa lati ra ojulowo irẹsi ti wọn a si maa wa sọdọ wa lati wa ra tiwa ti owo rẹ ko gunpa ti ko si dun''
Ọkan lara awọn onibaara Hashimu Dahiru sọ pe lootọ lawọn eeyan n wa ọna mii lati fi ri ounjẹ jẹ.
''Iye owo nkan lọja kọja agbara - laarin oṣu meji pere gbogbo nkan ti gbowo lori''
''Ọpọ wakati lawọn iyawo wa fi n yọ okuta ninu irẹsi yii ki wọn to se e. Ti wọn ba se e tan gaa-an, ko tun ni dun. Amọ ọmọ ṣe o yo lọrọ to wa nilẹ yii''
Ileeṣẹ aarẹ lawọn n gbiyanju lati dẹkun ọrọ ebi yii to fi mọ pinpin nkan ounjẹ bi irẹsi, ọka baba, agbado wooro ọgọrun tọọnu lọna ati mu iye owo nkan walẹ lọja.
Ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹ aarẹ, Bayo Onanuga mu inu bi awọn araalu nigba to sọ pe Naijiria wa lara awọn orileede ti igbe aye rọrun nipa iye ti wọn n na lojumọ.
Iṣoro ọwọngogo nkan yii ko sẹṣẹ bẹrẹ labẹ ijọba Tinubu.
Labẹ ẹni to jẹ ṣaaju rẹ, Muhammadu Buhari, ijọba igba naa fofin de gbigbe irẹsi wọle lati ilẹ okeere ki awọn agbẹ baa le dako irẹsi labẹle.
Ṣugbọn ipa awọn agbẹ ko ka a lati pese iye irẹsi to le to araalu jẹ.
Irẹsi lati Thailand ni Naijiria n gbe wọle lowo pọọku
Tinubu ti faaye gba gbigbe ounjẹ wọle ṣugbọn idẹnukọlẹ Naira loju dọla ti mu ki gbigbe irẹsi wọlẹ di iṣoro nla.















