Wo àwọn oúnjẹ mẹ́rin tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kanra jẹ báyìí nítorí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, bbc/jelilat olawale
Ilumọọka olorin Highlife nii Victor Olaiya lo forin bẹnu to sọ pe Ilu le ko sowo lode.
Orin rẹ yi ti wa di ohun ti ọpọ mu bẹnu ni Naijiria tori bi nkan ko ṣe rọgbọ faraalu.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo n tiraka lati ri nkan ra paapa eyi ti wọn yoo mu bẹnu amọ ti ọwọngogo ọja ti n mu ki ebi maa pa tọmọde tagba.
Ounjẹ ẹmẹẹta lojumọ ko si fun ọpọ mọ tawọn to si n ri jẹ ti n mu iyipada ba iru ounjẹ ti wọn n jẹ tẹlẹ.
Eyi ko ṣẹyin pe owo to yẹ ki wọn fi ra ounjẹ ko kaju rẹ mọ to si ti mu ki ọpọ maa da bi ọgbọn ki nkan le jọ ara wọn.
Ki ni awọn iyipada to deba iru ounjẹ ati bi awọn eeyan ṣe n jẹ lawujọ?
BBC Yoruba bọ si igboro taa si mu abọ wa lori nkan to yi pada ninu ounjẹ tawọn araalu n jẹ lasiko ti ọwọngogo ọja gbode yii.
Irẹsi ibilẹ n figa gbaga pẹlu ti ilẹ okere
Ni ọpọ idile irẹsi jẹ ounjẹ ti wọn ko le ṣe lalae jẹ lojumọ.
Bawọn eeyan ṣe n ṣe irẹsi ni jọlọọfu ni wọn ṣe ni funfun ati lọna miran ti ipa ba ka.
Amọ bayii ti nkan ti gbowo lori, iru irẹsi tawọn eeyan n jẹ ti n yatọ bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apo irẹsi ilẹ okere ti di nkan bi ẹgbẹrun marundinlaadọrin si mẹrindinlaadọrin Naira lawọn ọja kọọkan.
Akẹgbẹ rẹ to jẹ irẹsi ibilẹ ṣebi ẹni pe owo tiẹ ko gara pupọ ni nkan bi ẹgbẹrun lọna aadọta Naira si ẹgbẹrun marundinlọgọta Naira.
Iyatọ owo laarin awọn mejeeji yi ti mu ki awọn araalu kan pada si jijẹ irẹsi ibilẹ dipo ti ilẹ okere.
Jọlọọfu sise naa ti yi ipo pada pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe n se irẹsi wọn ni alasepọ tawọn kan n pe ni kọnkọṣọn.
Lafun tabi agbado lilo dipo Semovita
Semo jẹ ounjẹ kan ti ọpọ nifẹ si lati maa jẹ ni Naijiria.
Ounjẹ yi ti awọn ileeṣẹ kọọkan n peloo rẹ ti gbowo lori kọja agbara ọ́pọ ọmọ Naijiria.
Kaka ki ẹku si ma pa sese, ọgbọn ni ọpọ n da si ọrọ yi nipa piparọ sẹmo pẹlu agbado lilọ,ọ́ka baba,gari tabi lafun nibi ti wọn ba ti ri.
Koda awọn miran a maa lo gari lẹbu to kuna daada lati fi ṣe ounjẹ okele ki wọn ṣaa ti ri nkan fi banu lo ṣe pataki lọpọ idile.
Apo kekere Semo ti n ba nkan bi ẹgbẹrun mọkanla si mẹtala.
Amọ bi eeyan ba ti ri agbado,ọka baba tabi ounjẹ miran lọ nile ẹlẹrọ, okele ti de ti wọn fi n rọpoi Semovita niyẹn.
Anamọ ti gba ipo lọwọ Irish Potato

Oríṣun àwòrán, Google
Anamọ, oduku tabi dẹkẹli-eyikeyi ti ẹyin baa mọ si, ounjẹ yi ti di nkan ti ọpọ nifẹ si ni Naijiria tori pe iye owo rẹ ko gara pupọ.
Ṣaaju asiko yi, awọn idile kọọkan ko nifẹ si anamọ tori pe o maa n nira diẹ lati bẹ.
Dipo rẹ, awọn eeyan a maa ra ẹda rẹ ti wọn n pe ni Irish potato.
Irish potato yi ko wọpọ ni ilẹ Yoruba bi anamọ.
Iyatọ to wa laarin iye owo wọn nisinyi si ti mu ki awọn eeyan pada sidi anamọ tabi oduku ni jijẹ.
Wọn le ṣe bi ẹni se iṣu tabi ki wọn din,eyikeyi ọna la le gba jẹ anamọ ti awọn eeyan si ti wa gba tiẹ gẹgẹ bi ounjẹ to ba asiko yi ti ọwọngogo ọja peleke.
Apẹrẹ kekere Irish Potato kan la gbọ pe wọn n ta ni nkan bi ẹgbẹrun marun un Nairia.
Elo si ni apẹrẹ anamọ? Ko ju bi ẹgbẹrun kan si ẹgbẹrun kan abọ Naira lọ!
Pọnmọ dipo Ẹran ati ẹja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju asiko ọwọngogo nkan to gbode yi, awọn eeyan kan nifẹ si pọnmọ jijẹ.
Bẹẹ naa si ni awọn kan wa to ṣe pe wọn ko nifẹ si pọnmọ jijẹ to ṣe pe bi wọn ko ba jẹ ẹran, ẹja Turkey tabi nkan mii wọn ko faramọ pọnmọ jijẹ.
Ni asiko taa wa yi, ọpọ lo ti ri pọnmọ gẹgẹ bi koṣemani ninu ọbẹ ti wọn ba se.
Iye owo ẹran ati ẹja to fi mọ Turkey ati nkan elo mii ti gbowo lori.
Pọnmọ ṣi gbe pẹẹli diẹ tawọn araalu si yan laayo dipo awọn eleyi ti owo wọn lọ soke juu lọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn onimọ kan sọ pe ko si anfani ti pọnmọ n ṣe lara, awọn ti ko ni ikapa lati ra ẹran tabi ẹja a maa sọ pe ki awọn ṣaa ti ri nkan fi pa oju ọbẹ da ni.
Ni awọn idile mii, sise ọbẹ lailẹran kii ṣe nkan ajoji mọ tori pe igba taa wa yi ko rẹrin rara.















