Olorí Koro gbà ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ajínigbé: ọwọ́ olọ́pàá Kwara tẹ afurasí mẹ́tàlá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti kede pe awọn ti ribi doola iyawo Kabiyesi ilu Koro ti awọn ajinigbe gbe salọ lẹyin ti wọn ṣeku pa oriade naa.
Ọba Olusegun Aremu Cole lawọn ajinigbe yi ṣekupa laafin rẹ ni ọjọ Kini oṣu Keji ọdun 2024 ti wọn si gbe Olori rẹ ati eeyan kan salọ.
Atẹjade lati ọwọ alukoro ọlọpaa Kwara,Dsp Ejire Adfeyemi-Toun, sọ pe Olori ọba Bọsẹ Arẹmu ati Fẹranmi Olowu to pẹlu rẹ lawọn ti ribi doola ti wọn si ti darapọ mọ ẹbi wọn.
O tẹsiwaju pe ajọṣepọ laarin awọn ọlọpaa,DSS,ọdẹ ibilẹ ati fijilantẹ lo ṣe sababi bi wọn se ribi doola wọnn.
O tẹsiwaju pe awọn tun ri awọn afurasi ọkunrin mẹtala kan mu ti wọn si wa ni ahamọ ọlọpaa.
O ni awọn ti bẹrẹ si fọrọ wa wọn lẹnu wo lati le ribi mu awọn ajinigbe yoku to na papa bora.
Ṣaaju asiko yi lawọn ajinigbe ti beere owo idoola ọgọrun miliọnu Naira fun itusilẹ Olori Bọsẹ Arẹmu ati Fẹranmi Olowu ti wọn ji gbe.
Idunadura lori iye yi n tẹsiwaju lasiko tawọn agbofinro naa n kan lu igbo ti wọn si bẹrẹ si ni wa awọn ti wọn ji gbe yi.
Laarin igba yi la tun gbọ pe awọn ajinigbe naa di iye owo ti wọn fẹ gba ku si nkan bi ogoji miliọnu Naira.
A ko mọ boya wọn san owo yi amọ Kehinde Bayode, alaga igbimọ iṣakoso ijọba ibilẹ lagbegbe Ekiti sọ fun awọn akọroyin lọjọ Aiku pe ọwọ ti tẹ afurasi kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa pada sọ pe awọn ko mọ si afurasi ti wọn sọ pe ọwọ tẹ yi amọ iwadii ati igbiyanju ṣi n tẹsiwaju lati da awọn Olori pada lalaafia.
Ọrọ taa gbọ kẹyin re ki ikede to jade pe ọlọpaa ti ribi doola Olori naa ati eeyan kan to wa pẹlu rẹ.
A ko le sọ boya wọn pada san owo idoola yi tabi ko jẹ sisan tori alukoro ọlọpaa Kwara Dsp Ejire Adfeyemi-Toun ko mẹnu ba ọrọ yi ninu atẹjade to fi sita lorukọ kọmiṣana ọlọpaa Kwara












