Àwọn ajínigbé ń bèèrè N100m fún ìtúsílẹ̀ Olorí ọba àti èèyàn méjì tí wọ́n jígbé ní Kwara

Aworan igbakeji gomina ipinlẹ Kwara

Àwọn ajinigbe to pa ọba Peter Olusẹgun Arẹmun olukoro ti ilu koro ni ijọba ibilẹ Ekiti ipinlẹ Kwara ti beere ọgọrun kan miliọnu naira ki wọn to le fi Olori Bọsẹ Arẹmu ati Fẹranmi Olowu ti wọn ji gbe silẹ.

Ọkan lara awọn ara ilu ọhun to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe awọn ajinigbe naa pe baba Fẹranmi lori ẹrọ ibanisọrọ ti wọn si beere fun owo ọgọrun kan miliọnu naira.

Baba Fẹranmi ti oun naa ti gbe ilẹ Hausa ri to si gbọ ede Hausa daadaa ni a gbọ pe o ba awọn ajinigbe na sọrọ lede Hausa.

Ohun ti a gbọ ni pe baba Fẹranmi sọ fun awọn ajinigbe ọhun pe oun o ni ọgọrun kan miliọnu naira ti wọn n beere fun sugbọn oun o gbiyanju lati wa iye ti oun ba le ri jọ.

Arabirin Faith Olawale to ba BBC Yoruba sọrọ lati ilu Koro sọ pe awọn ajinigbe ni awọn yoo pe Baba Fẹranmi pada laipẹ.

Arabirin Olawale ṣalaye pe gbogbo ilu naa lo ti parọrọ lalẹ ti onikaluku ṣi ti tete wọle rẹ lọ nitori ibẹru bojo iṣẹlẹ naa si wa lọkan awọn eyan ilu naa.

Ti ẹ o ba gbagbe lalẹ ọjọ Aje ọjọ kini oṣu keji ọdun yii lawọn ajinigbe naa yabo afin olu ti ilu Koro, Ọba Peter Olusẹgun Arẹmu ti wọn si ran ọba alaye naa lọ ọrun ọsan gangan ti wọn ṣi tun ji olori rẹ ati awọn meji mi gbe lọ.