Akẹ́kọ̀ọ́ tí orí kó yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé l’Ekiti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe jí àwọn akẹgbẹ́ àti olùkọ́ rẹ̀ lọ

Gabriel Lawrence ti ori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe to jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ile ẹkọ Apostolic Faith Church ni Emure Ekiti nipinlẹ Ekiti sọ pe ‘’ni bii ago mẹrin abọ ni a de ibi ti wọn ti ji wa gbe.
Ṣadeedee ni a gbọ ti ibọn dun lẹẹmẹta, ẹsẹkẹsẹ ni awakọ wa sọ kalẹ lati yẹ ọkọ wo.
Bi o ṣe bọ silẹ ni wọn na ibọn si i lati iwaju ati ẹyin ọkọ.
Ọlọrun ni o ko mi yọ ti wọn ko fi ri emi naa jigbe, ẹsẹ ni a fi rin de ilu ti a n sare lai wẹyin.''
Akẹkọọ Lawrence ni ''awọn ajinigbe yii gba eti awakọ wa, awọn marun un lo kọkọ jade si wa.
Awọn mẹrin ko ibọn dani ninu awọn marun un yẹn, ẹnikan ko ọta dani.
Wọn na ibọn si wa lati iwaju ati ẹyin mọto, ti wọn ṣe ṣi ilẹkun niyẹn wi pe ki a maa jade.
Awọn ti o kọkọ jade lati ijoko to wa niwaju, wọn lu wọn.
Wọn ni ki gbogbo wa dọbalẹ loju titi ti a wa, igba to ya wọn ko wa si ẹgbẹ ọna, wọn si bẹrẹ si ni tọka si awọn ti wọn fẹ mu.
Gabriel Monday to jẹ ọkan lara awọn obi ọmọ ti ori ko yọ ni ‘’mo jẹ baba ọkan ninu awọn ọmọ ti ori ko yọ.
Ni ọjọ Aje ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ yẹn, mo ti sọ fun ọmọ mi nipa iṣẹ ti o maa ba mi ṣe loko pẹlu awọnn aburo rẹ.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun nigba tawọn eeyan bẹrẹ si ni ki mi barika pe a ku akoyọ.
Mo tiẹ n beere pe ta lo loyun ti o bimọ, afigba ti wọn ṣalaye fun mi pe awọn ajinigbe da ọkọ ile ẹkọ awọn ọmọ lọna, wọn si ji awọn ọmọ kan lọ.
A ti gbọ pe awọn ajinigbe ti n pe awọ obi awọn ti wọn jigbe, wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa lori ẹnikọọkan.
O ni ko si ibi tawọn agbẹ ti fẹ ri miliọnu mẹwaa tawọn ajinigbe n beere fun.
Ọgbẹni Sunday rawọ ẹbẹ si ijọba lati ran wọn lọwọ gba awọn ọmọ ti wọn jigbe lọ.
O ku diẹ ki iya kan ya were lẹyin to gbọ ohun to ṣẹlẹ bo tilẹ jẹ pe ori ko ọmọ rẹ yọ.
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Sunday Abutu sọ pe awọn ọlọpaa to bẹrẹ si ni wa ibi ti awọn akẹkọọ naa wa.
Abutu ni gbogbo awọn akẹkọọ naa lawọn yoo ṣe awari wọn ti wọn yoo si pada sile lọ ba awọn ẹbi wọn.
O wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati fi to ọlọpaa leti ohun kohun ti wọn ba gbọ nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ.



