Wo bí o ṣe le fi ìbẹ́pẹ wo inú rírun, ìtọ̀ ṣúgà, aràn inú, orí tó pá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ

IBEPE

Oríṣun àwòrán, Getty

O fẹrẹ ma si kinni kan ti ko wulo lara eso ibẹpẹ. Bẹrẹ lati ibi ewe rẹ titi to fi kan kóró inu rẹ, lo wulo fun ara eniyan.

Bi wọn ṣe n yo eeyan bii ounjẹ ni wọn tun n ṣiṣẹ iwosan fun agọ ara .

Eso abalaye ti ki i figba kankan kuro loko ni ibẹpẹ.

Amẹrika ni wọn tọpasẹ ibẹrẹ rẹ si, awọn arinrinajo ni iroyin si sọ pe o mu eso ibẹpẹ wa si Afrika ati India.

Awọn onimọ nipa eso igi fidi ẹ mulẹ, pe takọ-tabo ni igi ibẹpẹ.

Wọn ni awọn mi ti wọn ni adamọ akọ ati abo wa, ṣugbọn eyi to jẹ abo atawọn to ni adamọ mejeeji ni wọn n so eso didun ti a n jẹ.

Awọn anfaani ilera to wa ninu ibẹpẹ ree

Awọn onimọ nipa ounjẹ fi ye wa pe, ibẹpẹ kun fun eroja Fiber, eyi ti ara nilo lojumọ.

Fiber yii lo n ri si ki ṣuga ma pọju ninu ẹjẹ, ko ma si ṣe alaito.

Fiber naa lo n ri si bi ounjẹ ṣe tete n da ninu ara.

O tun kun fun Vitamin ati eroja Antioxidant ti ara nilo lati wa nipo alaafia.

Alfred Kanssou, Dokita onimọ nipa ounjẹ lati Cotonou, ṣalaye pe ibẹpẹ ni eroja kalori, proteeni, kabọaidreeti ati eyi ta n pe ni faiba (fibre), ti gbogbo wọn jẹ ko ṣe e ma ni fun alaafia ara.

Eyi ti wọn n pe ni glycemic naa wa ninu ẹ pẹlu Vitamin C.

O ni oun ki i fi owo ra Vitamin C mọ nibi ti wọn ti n ta oogun, ibẹpẹ kun fun Vitamin C rẹpẹtẹ ti ara nilo.

‘’Ti mo ba ti n jẹ ibẹpẹ bayii to n dun, bẹẹ naa lo n fun mi ni Vitamin C. Eso ti mo maa n ni kawọn to ba nilo Vitamin C maa jẹ niyẹn’’

Bẹẹ ni gbajumọ ọlọgbin ibẹpẹ tawọn eeyan mọ si Uncle Charles sọ.

Awọn dokita naa fidi ẹ mulẹ pe odiwọn Vitamin C ti ara nilo lojumọ wa ninu ibẹpẹ jijẹ.

Vitamin A, E,B5, B9 ati Potassium wa ninu ibẹpẹ.

Bi o ba fẹẹ ri awọn anfaani yii lara ibẹpẹ, ri i daju pe eyi to pọn daadaa lo n jẹ

pawpaw

Oríṣun àwòrán, getty

Dokita Kanssou tẹsiwaju pe ibẹpẹ to pọn daadaa lo ṣe ara loore ju, paapaa ti eeyan ba fẹ jẹ anfaani eroja antioxidant ati Vitamin E inu rẹ.

" Jijẹ ibẹpẹ to pọn maa n jẹ ki ẹni ti inu ba n run ri iwosan."

O daa fun egungun to lile.

Ibẹpẹ jijẹ deede pẹlu awọn eso onikoro mi-in maa n dena aisan jẹjẹrẹ ọyan ati ti oju ara fun obinrin.

Pipọn ti ibẹpẹ pọn lawọ ni i ṣe pẹlu eroja Beta-Carotene to wa ninu rẹ. Lycopene naa wa nibẹ, paapaa to ba ti pọn tan.

Bi ọkunrin ba n jẹ ibẹpẹ to pọn deede, Lycopene inu ibẹpẹ le dena jẹjẹrẹ ẹpọn fun un.

Wọn maa n lo ibẹpẹ jijẹ fun itọju aisan itọju ṣuga ( type 2 diabetics) nitori eroja polyphenols to wa ninu ẹ lo n ṣiṣe àrà naa fun itọju arun itọ ṣuga.

Lilo ibẹpẹ jijẹ fun oge ara

Bi ori eeyan ba pa, ti irun n rẹ jẹ, beta-carotene to wa ninu eso yii yoo ran an lọwọ lati nirun lori. Dokita Alfred fidi eyi mulẹ ninu alaye rẹ.

Koro inu ibẹpẹ dara fun itọju aran inu

koro inu ibepe

Oríṣun àwòrán, getty

Koro inu ibẹpẹ maa n ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ itọju, ọkan pataki lara rẹ ni itọju aran inu.

Awọn kokoro aifojuri bii Fungi, Bacteria, Pinworms, Ringworms ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn n da inu laamu ni koro ibẹpẹ wulo fun ti eeyan ba n jẹ ẹ.

Dokita Alfred sọ pe koro ibẹpẹ jijẹ maa n jẹ ki ounjẹ tete dà ninu eeyan.

" O le mu koro mẹta si mẹrin ki o jẹ ẹ ni tutu bẹẹ, o si le sa a soorun ko gbẹ daadaa, ko o lọ ọ, ko o si maa lo iyẹfun rẹ.

O le bu u sinu omi tabi nnkan mimu mi-in bii tii, ko o gbe e mu.

Eyi daa fun odò inu pupọ, o si maa n pa awọn aran buruku to maa n yọ inu lẹnu’’

Iwulo ewe ibẹpẹ

ibepe

Oríṣun àwòrán, getty

O le fi ewe ibẹpẹ meloo kan sinu omi gbigbona, to ba toro tan, ma a mu un lẹẹẹmẹta lojumọ., 'tea' abalaye to n to ara ni.

O dara fun ki egbo tete san pẹlu, ẹsẹ to wu teeyan fẹ ko fa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹṣọ ati iṣura pataki to yẹ keeyan ni lọgba ati ninu oko ni ibẹpẹ jẹ.

Ewe rẹ titi to fi de gbongbo lo wulo.