Àǹfàání tó wà nínú fífi iyọ̀ sínú 'Tea' tó o fẹ́ mu

Aworan tea ti eeyan kan n po papọ

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

Awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi a maa kan sara si arawọn pe awọn jẹ onimọ nipa pipo ohun mimu nii taa mọ si tea.

Lojumọ kan o kere tan, wọn a maa mu ọgọrun miliọnu ife tea.

Amọ onimọ sayẹnsi kan to wa ni America ti da si ọrọ tea pipo to si ni oun ti ri aṣiri eroja kan ti yoo jẹ ki awọn eeyan maa gbadun tea mimu ju ti atẹyinwa lọ.

Aba to mu wa ni pe ki wọn maa fi iyọ sinu tea ki wọn to da sọna ọfun.

Ọjọgbọn Michelle Francl lo ṣe iwadii lori ọrọ yi to si ti n da awuyewuye silẹ eyi to mu ki ileeṣẹ okere ilẹ Amẹrica ni ilẹ Gẹẹsi da si ọrọ naa.

Anfaani to wa ninu ki o fi iyọ̀ sinu Tea rẹ

Iwadii fi han pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ọrọ iyọ ti rapala wọn inu tea tawọn eeyan n po mu.

Ọjọgbọn Francl salape pe awọn eeyan ilẹ China ti ṣaaju sọrọ nipa fifi iyọ sinu tea ti akọsilẹ rẹ si wa.

Eyi ni Ọjọgbọn Francl ṣamulo lati peelo eroja rẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Ohun to yatọ ni imọ ti a ni nipa rẹ gẹgẹ bi onimọ apopọ kẹmika, Chemistry.''

O ṣalaye pe iyọ a maa ṣe idiwọ fun ẹya ara to maa n jẹ ki tea koro lori ahọn ni paapa ti eeyan ba po o gbona daada.

O ni ti eeyan ba fi iyọ kinkini si, yoo pa eyikeyi ikoro to ba wa ninu adun ohun mimu naa rẹ.

Ko dabi ki eeyan fi sugar si tea. Ẹru kan n ba awọn eeyan pe wọn yoo gbọ adun iyọ ninu tea ti wọn ba fi si''

O rọ awọn to nifẹ si tea mimu ni ilẹ Gẹẹsi lati fi ọkan mimọ tẹle iwadii toun ṣe.

Iwadii yi wa ninu iwe kan to pe orukọ rẹ ni '' The Chemistry of Tea'' ti Royal Society of Chemistry ṣe agbejade rẹ.

''Ko si aburu nibi ka maa ṣe agbeyẹwo lorisi. Emi gaan ṣe ayẹwo lorisi ki n to gbe jade ''

Ọjọgbọn Francl bẹrẹ si ni nifẹ si tea lati igba ti mama rẹ po fun nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa.

Ọtọọtọ ni bi onikaluku ṣe nifẹ si tea rẹ ni pipo.

Amọ Ọjọgbọn Francl mu amọran wa wi pe ki awọn eeyan maa fi ewe tea po tea wọn dipo baagi olokun ki wọn si po pọ daada ki miliki ati omi baa le dapọ mọ arawọn ninu rẹ.

O tun mu aba wa pe ki awọn eeyan maa kan omi oronbo sinu tea wọn.

Bakan naa lo ni ki wọn gbe miliki ra ina diẹ ki wọn to o da sinu tea.

Amọ amọra pataki to mu wa ni pe ki awọn eeyan ma ṣe fi microwave mu tea wọn gbona.

''Kii fun ara lokun bẹẹ si ni adun rẹẹ kii jade daada''

Ileeṣẹ aṣoju America ti bọ si oju opo Twitter lati sọ pe ''A fẹ sọ di mimọ pe kii ṣe ilana America ni pe ki wọn maa fi iyọ si ohun mimu ti ọpọ nifẹ si ni ilẹ Gẹẹsi. A ko si ni faramọ ilana yi lailai''

Igba akọkọ kọ ni yi ti ọrọ Tea yoo da họwuhọwu silẹ laarin awọn orilẹ-ede mejeeji.

Ni 1773 awọn oluwọde nilu Bosto Massachusetts fi ibinu da apoti ọọdunrun ti tea kun inu rẹ sinu odo ni ifẹhonuhan ati atako owo ori ti ilẹ Gẹẹsi n gbe le wọn lori.

Iṣẹlẹ yi jẹ eleyi to lamilaaka to si jẹ atọna ija ominira America lọwọ ilẹ Gẹẹsi nigba naa lọhun.

''Mi o si wa gbero lati da wahala silẹ laarin orileede mejeeji''

Bẹẹ ni ọjọgbọn Bryan Francl ti ilẹ ẹkọ Bryn Mawr to wa ni Pennsylvania ṣe sọ fun BBC.

''Awọn eeyan ko jẹ ki n rimu mi ninu imeeli mi .Mi o lero pe mo maa ji lowuro lati ri wi pe awọn eeyan n sọrọ nipa fifi iyọ sinu tea wọn'