Mọ nípa àwọn ànfàní tó sára lóore tó wà nínú jíjẹ iṣu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣu jẹ ọkan lara awọn ounjẹ to gbajumọ nilẹ Adulawọ ti ko si ile ti ẹ ko ti ni ba.
Koda onkowe Naijiria kan, Chinua Achebe sapajuwe gẹgẹ bi “ọba awọn nnkan ọgbin”.
Gẹgẹ bi ẹgẹ ati anamọ, Iṣu jẹ ohun ọgbin to jẹ ilumọka ounjẹ ti ọpọlọpọ n jẹ ni awọn orilẹede Afirika.
Isu jẹ ounjẹ to ni ọpọlọlọ eroja asara loore bi vitamin ati awọn eroja miii. Isu le funfun, ofeefee tabi ko ni Pink, ti wọn si ma ṣe jinna bi wọn ṣe n ṣe Anamọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko si labẹ ohun ọgbin kan naa.
Ẹya isu to wa le ni ọgọrun-un lorisirisi ṣugbọn diẹ ninu wọn ni o wa fun jijẹ.
Isu dun lẹnu to si jẹ pe nigba mii o ma tu si ẹnu. Isu pẹlu okiki rẹ ni ọpọ mọ fun awọn eroja to sara loore ati didun lẹnu rẹ.
Awọn eroja asara loore to wa lara Isu
Awọn eroja asara loore to wa ninu iṣu jẹ ki o jẹ ounjẹ to ṣe koko fun ilera ati wiwa ni alaafia wa.
Isu kun fun awọn eroja pataki to maa n pọkun awọn eroja to maa n ṣe alekun awọn ohun ilera ti ara nilo ni kikun.
O jẹ orisun eroja "carbohydrates" eyi ti o maa n pese agbara pataki ti a nilo fun ago ara wa fun iṣẹ ṣiṣe.
Onimọ nipa ounjẹ, Marion Ezzedine to n ṣe idari ileese kan to n ri si mọ nipa ounjẹ niluu Abidjan, olu ilu eto ọrọ aje ti Ivory Coast sọrọ nipa awọn anfani to wa ninu iṣu.
O ṣafihan ọpọlọpọ awọn iwulo ati eroja to wa lara jijẹ Isu:
“Iṣu jẹ orisun Fiber (ida mẹrin lo wa ninu isu dipo ida meji to wa ninu anamọ ati ida kan to wa ninu irẹsi), awọn eroja vitamin (paapaa B1, B6, C), awọn ohun eroja miniral bi copper, manganese, potasiomu ati awọn egboogi-oxidants.
O tun jẹ orisun agbara ti o nifẹ nitori akoonu carbohydrate rẹ jẹ ida mẹrinlelogun (24).
Iṣu jẹ ounjẹ asara loore to gbajumọ ni ilẹ Afirika. Orisirisi ọna ni awọn eeyan lati orilẹede Benin, Togo, Cameroon, Nigeria ati Ivory Coast ni pataki fi n ṣe Isu jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sise, sisun tabi gigun pẹlu ọbẹ to dun, onikaluku lo ni bi o ṣe fẹran lati ma jẹ isu rẹ niulu Abidjan.
“Mo fẹran iṣu, Mo ma jẹ gan ni abule mi. Iṣu ni itọwo to jẹ pataki. Si awọn kan, o dun, lọdọ awọn ẹlo mii ni kikoro diẹ.
“Nitori naa onikaluku ni o ni itọwo ti rẹ to da le lori bi o ba ṣe ṣe idu rẹ. Mo feran iṣu sise tabi sisun. Bakan naa, n ko ki ṣe ololufẹ iyan, eyi ti mo nifẹ pupọ ni sisun ati sise,” Maxime, ololufę iṣu.
“Mo fẹ́ràn iṣu, paapa iṣu kponan, mo fẹran rẹ gan. Mo ma jẹ ni ẹkan tabi ẹmeji lọsẹ kan, paapaa ti n ba ri pẹlu obe gouagouassou,o dara gan. Ṣiṣe iṣu ati kiki kaabọ pẹlu obe gouagouassou, Mo ro pe o jẹ aami to ma jẹ ki eeyan dagba soke si, ”René sọ,
“Bẹẹni, Mo fẹran iṣu daradara, o jẹ ounjẹ ti wa kati ibi ti mo n gbe, lati aṣa mi nitori akọkọ, Baoulé ni mi.
“Lọdọ ti wa, o dun, o si tun ma tu si mi lẹnu. Nitori naa mo fẹran iṣu, o baa mi lara mu. Mo ma jẹ ni gbogbo igba
O da bi pe mo n pada si igba ewe mi nitori mo ma n jẹ pẹlu awọn obi mi. Nitori naa o mọ mi lara.
O wa di aṣa dipo ounjẹ”Jean Marc sọ.
Iṣu dun ju Anamọ lọ, orisiris ọna ni a le fi ṣe iṣu ti yoo si dun.
Pẹlu o ṣe kun pẹlu eroja Fiber, Iṣu le jẹ ki ounjẹ tete da ninu . Bakan naa iṣu ma ṣe anojuto ara sisan.
Eroja bi carbohydrates ati awọn ohun alumọni to wa ninu isu, ti jẹ ko rọpo Anamọ ati Irẹsi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sise itọju ẹjẹ lọwọ ṣuga.
Iṣu ni eroja glycemic to kekere ju awọn orisun carbohydrate yooku lọ, eyi to tumọ si pe jijẹ iṣu loorekore le ni ipa ninu suga ẹjẹ.
Pẹlu eroja sitasi ida adọrin i, iṣu ṣe iranlọwọ lati mu adinku ba glycemic, atọgbẹ ati itọ suga ati ki ounjẹ ma tete da ni inu. Eyi tumọ si pe lilọ ounjẹ sew koko fun awọn eniyanto ni itọ suga, awọn ọmọde ati awọn aboyun, gẹgẹ bi onimọ ounjẹ, Marion Ezzedine se salaye.
“Ẹru glycemic ti iṣu jẹ iwọntunwọnsi, nitori naa o se jẹ ni lẹkọkan fun awọn eniyan ti o ni àtọgbẹ.
Ko si itọkasi fun awọn aboyun tabi awọn ọmọde. Awọn eniyan ti o ni ikuna kidinrin yẹ ki o ṣe iwọn si jijẹ iṣu wọn niwọntunwọnsi nitori eroja miniral to wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, AFRIDOCTOR.COM
Ṣiṣe atunṣe si agọ ara
Vitamin C ti o wa ninu iṣu ni ohun ti oyinbo n pe ni antioxidant ti o ṣe iranlọwọ fun agọ ara to si n dena de aisan ati aarun kan.
Iṣu tun ni awọn ohun egbogi ti o ṣe iranlọwọ lati ṣe adinku ipalara ninu ara ati to si n din irora ku lago ara bii arthritis.
Lakoko ti o ṣe iranlọwọ lati dena de aisan ẹdọ ati aarun kidinrin, o ni awọn eroja asara loore to n gbe ogun ti sisọ oye nu atọgbẹ ati ifunpa to ga.
Pẹlu eroja potaṣiomu, iṣu tun wulo fun ilera to peye to fi ni lọkanbalẹ ati awọn miiran.















