Ẹgbẹ́ PDP yarí pè kò yẹ kí ìjọba yan Etekamba tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC sípò kọmíṣọ́nnà àjọ INEC ní Akwa Ibom

“Ẹgbẹ PDP nipinlẹ Akwa Ibom wi pe awọn ti lọ ile-ẹjọ nitori ọgbẹni Etekamba Umoren to figba kan jẹ olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio, to tun jẹ agba ọjẹ lẹgbẹ oṣelu APC bii kọmiṣọna ajọ INEC nipinlẹ naa”
Egbẹ PDP ni iwa yii ko dara rara.
Ati pe PDP tako igbeṣe ijọba naa

Oríṣun àwòrán, Channels TV
Ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana, lo ti ni iṣoro ti ajọ eleto idibo lorilẹ-ede Naijiria (INEC) n doju kọ yoo tunbọ peleke sii pẹlu yiyan awọn to jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu gẹgẹ bii kọmiṣọna ajọ naa.
Falana to jẹ agbẹjọro agba lo sọ ọrọ yii lakoko to jẹ aléjo lori ẹrọ amohunmaworan Channels nibi to ti bu ẹnu atẹ lu awọn ti ile aṣofin agba buwọ lu lati di kọmiṣọna INEC ni Ọjọru ati Ọjọbọ ọsẹ yii.
Falana wi pe “ẹni to ni iwe idanimọ ẹgbẹ oṣelu kankan ko gbọdọ ni nkan ṣe pẹlu ajọ INEC nitori yoo tunbọ jẹ kawọn araalu o kuna igbagbọ ninu ajọ naa sii”.
Yíyan ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú bíi kọmíṣọ́na àjọ INEC yóò dojú ètò ìdìbò rú pátápátá - Falana
Agbẹjọro naa wi pe mẹta ninu awọn tile aṣofin agba naa fọwọ si lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti ọkan ninu wọn si jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP.
“Ẹgbẹ PDP nipinlẹ Akwa Ibom wi pe awọn ti lọ ile-ẹjọ nitori ọgbẹni Etekamba Umoren to figba kan jẹ olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio, to tun jẹ agba ọjẹ lẹgbẹ oṣelu APC bii kọmiṣọna ajọ INEC nipinlẹ naa”
Agbẹjọro naa fi kun pe awọn mẹta to ku lo yẹ ki wọn tun gbe lọ ile-ẹjọ nitori iyansipo wọn ko boju mu.
A kò gba ìwé àtakò látọ̀dọ ará ìlú - ilé aṣòfin
Ẹwẹ, sẹnetọ Yemi adaramodu to jẹ agbẹnusọ ile aṣofin agba ti fesi lori awuyewuye pe ile aṣofin naa ko ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ.
Adaramodu wi pe awọn ko tẹwọ gba iwe atako kankan lati ọdọ ẹnikẹni lori eyikeyi ninu awọn orukọ ti aarẹ Bola Tinubu fi ṣọwọ si wọn lati di kọmiṣọna lajọ INEC.
Sẹnetọ naa fi kun pe bẹẹni ko si iwe kankan lati ọdọ awọn ẹṣọ alaabo to fihan pe awọn kọmiṣọna naa ko kunju iwọn.












