Edgar Lungu- Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Zambia réè tí ijọba wọ́gilé gbogbo mùdùnmúdùn ifẹ̀yìntì tó n jẹ́ anfáànì rẹ̀

Aworan aarẹ tẹlẹ ni Zambia

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijọba orileede Zambia ti wọgile gbogbo ajẹmọnu ifẹyinti ti aarẹ tẹlẹ Edgar Lungu n jẹ anfaani rẹ lẹyin to loun fẹ pada sidi oṣelu.

Ọgbẹni Lungu fidirẹmi ninu idibo aarẹ lọwọ Hakinde Hichilema lọdun 2021 to si kede pe oun ti fẹyinti nidi oṣelu.

Lẹyin ọdun mẹfa to lolori aleefa, o fi orileede naa pẹlu awọn ipenija ọrọ aje to sọ Zambia di ilẹ to jẹ gbese julọ ni Afrika.

Pipada si agbo oṣelu ti mu ki araalu maa reti ifigagbaga ti yoo lamilaka ninu idibo aarẹ ọdun 2026.

Wọn ti fi to aarẹ tẹlẹ yi leti pe ko ni jẹ awọn anfaani to n jẹ tẹlẹ mọ bayii gẹgẹ bi agbẹnusọ ijọba Cornelius Mweetwa ti ṣe sọ.

O ni gbagada lo wa ninu ofin ilẹ naa pe aarẹ tẹlẹ to ba pada si agbo oṣelu ko ni jẹ awọn anfaani yi mọ.

Ninu anfaani taa n sọ yi ni pe awọn ẹṣọ alaabo mẹta yo maa tẹle ka,yoo niiwe irina pasipọọti ti wọn ko ni ṣe ayẹwo rẹ,yoo gba ọkọ mẹta , ile ti wọn ṣe lọjọ, etoadojutofo ẹmi ilera bẹẹ si ni ijọba yoo gbe gbogbo bukata eto isinku rẹ to ba jade laye.

Yoo si tun ni idaabobo labẹ ofin ti wọn o fi ni pe lẹjọ kankan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lasiko ti o n ba awọn akọroyin sọrọ, Ọgbẹni Mweetwa sọ pe bayii aarẹ tẹlẹ yi koni yatọ si awọn to ti de ipo agba lorileede naa labẹ ofin ilẹ ọhun.

Ọgbẹni Lungu n gbero lati wọle si awọn oludibo lara pẹlu bi eto ọrọ aje ṣe dẹnu kọlẹ labẹ akoso ẹni to wa lori oye nisinyi.

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan naa ti fẹdun ọkan wọn han lori bi ko ṣe si ibọwọ fẹtọmọniyan lorileede naa.

Lasiko to n kede ipadabọ rẹ sagbo oṣelu,ọgbẹni Lungu s pe oun pada wa l;ati ja fun ijọba awarawa lorileede naa.

Bẹẹ naa lo ṣe ileri lati yọ ẹgbẹ oṣelu rẹ to wa lori aleefa tẹlẹ kuro ninu ọọfin to wa bayii.

Ijọba to wa lori oye ti halẹ laimọye igba pe oun yoo gba orukọ ẹgbẹ naa kuro ninu orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ilẹ naa nitori ede aiyede to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.

Agbẹnusọ ijọba tako ọrọ ọgbẹni Lungu to s laipẹ pe awọn alatilẹyin ẹgbẹ

United Party for National Development (UPND) to wa lori oye n dẹyẹ si oun.

O ṣapejuwe ọrọ Ọgbẹni Lungu gẹgẹ bi asẹ to si ni aabo to peye wa fun aarẹ tẹlẹ ri yi bi o ṣe wa fun eyikeyi ọmọ orileede naa kankan.

Amọ ṣa o kilọ fun Lungu l;ati yago fun eyikeyi igbesẹ oṣeluto n gbena woju ijọba aarẹ Hichilema.

Loṣu to kọja ni wọn kilọ fun Ọgbẹni Lungu lati yago fun ṣiṣe ere idaraya ni ita gbangba ti awọn ọlọpaa si ṣapejuwe igbesẹ yi gẹgẹ bi ipolongo oṣelu.

Ko yi ti daju boya ijọba yoo wọgile anfaani rẹ to ni nipa pe wọn ko le ni ko wa kawọ pọnyin rojọ.

Ṣaaju asiko yi, ile aṣofin Zambia ti wọgile irufẹ anfaani yi fawọn aarẹ meji tẹlẹ ri iyẹn aarẹ tẹlẹ Frederick Chiluba lọdun 2002 ati Rupiah Banda lọdun 2013.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu UPND to wa lori oye kan ti n pe fun yiyọ anfaani ma kawọ pọnyin rojọ yi lara aarẹ tẹlẹ Ọgbẹni Lungu tori ajẹbanu to waye lasiko ijọba rẹ.

Lungu si ti sọ pe gbogbo ipeati idẹyẹsi yi lọwọ oṣelu ninu.