Bí EFCC ṣe pa ohun tí wọ́n gbé sójú òpó ayélujára rẹ́ náà ni kí wọ́n tọrọ àforíjìn- Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ OAU

Aworan Asia ajọ EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC

Awọn akẹkọọ Fáṣítì Obafemi Awolowo, Ile Ife ti ni ki ajọ to n gbe ogun ti wa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC tọrọ aforijin lẹyin ti wọn mu akẹkọọ mọkandinlaadọrin lọ si ahamọ lọjọ lọjọru ọsẹ yii.

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti ni awọn ti EFCC ko ni ile ẹkọ lo jẹ akẹkọọ Fasiti, ti wọn si gbe wọn lọ si ọfisi wọn niluu Ibadan.

Lẹyin ìfẹhonuhan awọn akẹkọọ ni ọfisi EFCC niluu Ibadan, ajọ naa tu akẹkọọ mejinlaadọta silẹ pe wọn ko lẹjọ lati jẹ.

Akẹkọọ mọkanla si wa ni ahamọ ti wọn salaye pe wọn ní ẹjọ lati jẹ.

Bakan naa ni EFCC tí pa gbogbo ohun tí wọn gbe sori ayelujara nípa àwọn akẹkọọ OAU rẹ, ti a ko si nnkan to jẹ mọ bẹ lori opo ayelujara wọn.

Ṣugbọn ninu atẹjade ti ẹgbẹ akẹkọọ ni OAU fi lede fun awọn akọroyin ni o se koko ki ajọ EFCC tọrọ aforijin fun orukọ awọn akẹkọọ ti wọn bajẹ, ti wọn si gbinyanju lati gba awọn yooku to wa lọgba ẹwọn jade.

"A n bere pe ki wọn tu awọn akẹkọọ mọkanla to wa ni ahamọ wọn silẹ, ki wọn dẹ tun tọrọ aforijin fun bi wọn ṣe ba orukọ akẹkọọ je.

Aarẹ ẹgbẹ naa Abbas Ojo, Akọwe ẹgbẹ, Akinboni Opeyemi ati Agbẹnusọ ẹgbẹ, Omisore Elijah tí wọn buwọlu atẹjade naa fun awọn akọroyin.

"A fẹ ki EFCC tọrọ aforijin, ki wọn fọ orukọ awọn akẹkọọ wa ti wọn bajẹ mọ."

58 gba ìtúsílẹ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ OAU tí EFCC mú

Aworan awọn akẹkọọ OAU nibi ifẹhonuhan

Awọn mejidinlọgọta ninu awọn akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ti ilu Ile-ife ti ajọ EFCC mu ni wọn ti gba itusilẹ.

Awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC lo yabo ibugbe kan ti awọn akẹkọọ fasiti OAU wa ni ita ọgba ileẹkọ naa mọjumọ Ọjọru ti wọn si ko awọn akẹkọọ mọkandinlaadọrin lọ silu Ibadan.

Awọn aṣoju awọn akẹkọọ naa ni wọn ko ara wọn lọ iwaju ọfiisi EFCC nilu Ibadan lati lọ fi ẹhonu han ti wọn si n beere fun itusilẹ awọn akẹgbẹ wọn.

Aarẹ awọn akẹkọọ ni fasiti naa, Abbas Akinyemi, ṣe alaye fun BBC News Yoruba pe ohun mẹta lawọn beere lọdọ ajọ EFCC nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu ajọ naa.

“A ni ki wọn yọ gbogbo ohun ti wọn fi sori ẹrọ ayelujara nipa awọn akẹkọọ naa, ki wọn yọnda wọn ati awọn dukia wọn, ki wọn si tun tọrọ aforiji lowọ gbogbo akẹkọọ rilẹ-ede yii fun iwa ibajẹ ti wọn hu.”

Akinyemi wi pe ki awọn too kuro nilu ibadan ni alẹ ana ni wọn ti tu awọn mejidinlọgọta silẹ.

O fi kun pe awọn mọkanla to ku ni ko lee tẹle awọn lọọle nitori pe ko si akoko mọ lati ṣe ifokusilẹ ati iwadi nipa wọn.

Gómìnà Adeleke ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí EFCC mú

Akinyemi dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, fun atilẹyin rẹ lati le gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa.

Aarẹ awọn akẹkọọ naa wi pe gomina Adeleke yọnda kọmiṣọna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Wole Jimi-Bada, lati tẹle awọn lọ Ibadan lati gba itusilẹ awọn mọkanla to ku.

“Eyi jọwa loju gidi, o si jẹ ohun iwuri fun wa.”

Akinyemi wi pe oun nigbagbọ pe awọn mọkanla to ku yoo gba ominira lo

Alága àjọ EFCC ti dá sí ọ̀rọ̀ náà

Igbakeji aarẹ apapọ fawọn akẹkọọ lorilẹ-ede yii, Akinteye Babatunde wi pe awọn ti gbe ọrọ naa de iwaju alaga ajọ EFCC ti eyi si ti n so eso rere.

Babatunde wi fun BBC Yoruba pe lẹyin ti awọn kan si alaga EFCC naa lo paa laṣẹ pe oṣiṣẹ ajọ naa kankan ko gbọdọ mu ẹnikẹni loru mọ.

Babatunde ni amọran oun fun EFCC ni ki wọn maa kọwe si awọn adari ile-ẹkọ lati beere fun akẹkọọ ti wọn ba fura si gẹgẹ bi ajọ ọlọpaa ṣe maa n ṣe dipo ki wọn maa fiya jẹ alaiṣẹ ninu igbiyanju wọn lati mu afurasi ọdaran.